Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Dáníẹ́lì?
Ohun tí Bíbélì sọ
Wòlíì Júù kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni Dáníẹ́lì, ó gbé ayé láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún keje àti ìkẹfà Ṣ.S.K. Ọlọ́run fún un lágbára láti túmọ̀ àwọn àlá àti láti mọ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ó tún mí sí i láti kọ ìwé Bíbélì tá a fi orúkọ ẹ̀ pè.—Dáníẹ́lì 1:17; 2:19.
Ta ni Dáníẹ́lì?
Ilẹ̀ Júdà ni Dáníẹ́lì ti ṣe kékeré, ibẹ̀ sì ni ìlú Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì àwọn Júù wà. Lọ́dún 617 Ṣ.S.K., Nebukadinésárì tó jẹ́ ọba Bábílónì ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù, ó mú “àwọn aṣáájú ilẹ̀ náà,” ó sì kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí Bábílónì. (2 Àwọn Ọba 24:15; Dáníẹ́lì 1:1) Wọ́n mú Dáníẹ́lì tó ṣeé ṣe kó ṣì jẹ́ ọmọdé nígbà yẹn lọ pẹ̀lú wọn.
Wọ́n mú àwọn ọ̀dọ́kùnrin míì pẹ̀lú Dáníẹ́lì (lára wọn ni Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò). Wọ́n mú gbogbo wọn lọ sí ààfin ọba Bábílónì láti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run wọn, láìka ti pé àwọn òṣìṣẹ́ ààfin ń fúngun mọ́ wọn pé kí wọ́n ṣe ohun tí kò bá ẹ̀rí ọkàn wọn mu. (Dáníẹ́lì 1:3-8) Lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mẹ́ta, Ọba Nebukadinésárì gbóríyìn fún wọn torí pé wọ́n kún fún ọgbọ́n àti òye, ó tiẹ̀ sọ pé wọ́n fi “ìlọ́po mẹ́wàá dáa ju gbogbo àwọn àlùfáà onídán àti àwọn pidánpidán tó wà ní gbogbo ibi tó jọba lé lórí.” Ó wá ní kí Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ máa ṣiṣẹ́ láàfin ọba.—Dáníẹ́lì 1:18-20.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ọba kan tó ń jẹ́ Bẹliṣásárì pàṣẹ pé kí wọ́n mú Dáníẹ́lì wá sí ààfin òun, ó ṣeé ṣe kí Dáníẹ́lì ti pé ẹni àádọ́rin (90) ọdún nígbà yẹn. Ọba Bẹliṣásárì ní kí Dáníẹ́lì túmọ̀ ohun tí ọwọ́ kan tó ṣàdédé fara hàn kọ sára ògiri. Jèhófà ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́ láti mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí ọwọ́ náà kọ. Dáníẹ́lì wá jẹ́ kí ọba mọ̀ pé àwọn ará Mídíà àti Páṣíà máa ṣẹ́gun Bábílónì. Alẹ́ ọjọ́ yẹn ni wọ́n sì ṣẹ́gun Bábílónì lóòótọ́.—Dáníẹ́lì 5:1, 13-31.
Lẹ́yìn táwọn ará Mídíà àti Páṣíà ṣẹ́gun Bábílónì, Ọba Dáríúsì yan Dáníẹ́lì pé kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè òun, ó sì tún ń gbèrò láti gbé e ga. (Dáníẹ́lì 6:1-3) Àmọ́ àwọn ìjòyè àtàwọn baálẹ̀ tó kù ń jowú Dáníẹ́lì, wọ́n sì ń wá ẹ̀sùn sí i lẹ́sẹ̀ kí wọ́n lè pa á. Wọ́n ṣe é débi pé wọ́n ju Dáníẹ́lì sínú ihò kìnnìún, àmọ́ Jèhófà dáàbò bò ó. (Dáníẹ́lì 6:4-23) Nígbà tó kù díẹ̀ kí Dáníẹ́lì kú, áńgẹ́lì kan fara hàn án, ó sì fi dá a lójú lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pé ó jẹ́ “ọkùnrin tó ṣeyebíye gan-an.”—Dáníẹ́lì 10:11, 19.
Wo bá a ṣe ṣàfihàn ìtàn yìí nínú fídíò alápá méjì náà Dáníẹ́lì Nígbàgbọ́ Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Rẹ̀.