Kí Ni Bíbélì Kọ́ni Nípa Fífi Èdè Fọ̀?
Ohun tí Bíbélì sọ
Àwọn Kristẹni kan nígbà àtijọ́ lè ‘fi èdè fọ̀’. Ohun ìyanu ni torí pé wọ́n lè sọ èdè kan láìjẹ́ pé wọ́n ti kọ́kọ́ kọ́ bí wọ́n ṣe ń sọ ọ́. (Ìṣe 10:46, Bíbélì New International Version) Ohun tí wọ́n bá sì ń sọ máa ń tètè yé ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́ èdè náà. (Ìṣe 2:4-8) Fífi èdè fọ̀, tàbí sísọ̀rọ̀ ní ahọ́n àjèjì wà lára ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ tí Ọlọ́run fún àwọn Kristẹni kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní.—Hébérù 2:4; 1 Kọ́ríńtì 12:4, 30.
Ibo ni àwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí í fèdè fọ̀, ìgbà wo ló sì bẹ̀rẹ̀?
Jerúsálẹ́mù ni iṣẹ́ ìyanu yìí ti kọ́kọ́ wáyé, láàárọ̀ ọjọ́ táwọn Júù ń ṣe Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì lọ́dún 33 S.K. Nǹkan bí ọgọ́fà (120) nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù pàdé pọ̀ lọ́jọ́ yẹn, ó sì ṣẹlẹ̀ pé “gbogbo wọ́n . . . wá kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi onírúurú ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀.” (Ìṣe 1:15; 2:1-4) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn “láti gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run” ló kóra jọ, “ẹnì kọ̀ọ̀kan [sì] gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní èdè tòun.”—Ìṣe 2:5, 6.
Kí ni ète fífi èdè fọ̀?
Láti fi hàn pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn àwọn Kristẹni. Nígbà àtijọ́, Ọlọ́run ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu kan láti fẹ̀rí hàn pé òun wà lẹ́yìn àwọn olóòótọ́ èèyàn bíi Mósè. (Ẹ́kísódù 4:1-9, 29-31; Númérì 17:10) Iṣẹ́ kan náà ni fífi èdè fọ̀ ṣe, ṣe ló fi hàn pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn ìjọ Kristẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwọn ahọ́n àjèjì wà fún iṣẹ́ àmì, kì í ṣe fún àwọn onígbàgbọ́, bí kò ṣe fún àwọn aláìgbàgbọ́.”—1 Kọ́ríńtì 14:22.
Láti jẹ́ kí àwọn Kristẹni lè jẹ́rìí kúnnákúnná. Àwọn tó gbọ́ táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì sọ pé: “Àwa gbọ́ wọn tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní ahọ́n wa nípa àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run.” (Ìṣe 2:11) Ó fi hàn pé ohun pàtàkì míì tí iṣẹ́ ìyanu yìí wà fún ni láti jẹ́ kí àwọn Kristẹni lè “jẹ́rìí kúnnákúnná”, kí wọ́n sì lè “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,” bí Jésù ṣe pa á láṣẹ fún wọn. (Ìṣe 10:42; Mátíù 28:19) Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn tí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu náà, tí wọ́n sì gbọ́ báwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe jẹ́rìí ló di ọmọ ẹ̀yìn lọ́jọ́ yẹn.—Ìṣe 2:41.
Ṣé ẹ̀bùn fífi èdè fọ̀ máa wà pẹ́ títí ni?
Rárá. Ìgbà díẹ̀ ni àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́, títí kan fífi èdè fọ̀, fi máa wà. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Yálà àwọn ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ wà, a óò mú wọn wá sí òpin; yálà àwọn ahọ́n àjèjì wà, wọn yóò ṣíwọ́.”—1 Kọ́ríńtì 13:8.
Ìgbà wo ni fífi èdè fọ̀ dópin?
Àwọn àpọ́sítélì máa ń wà níbẹ̀ tí àwọn Kristẹni míì bá fẹ́ gba àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́. Bó ṣe sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn àpọ́sítélì máa ń gbé ọwọ́ wọn lé àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn láti fún wọn láwọn ẹ̀bùn náà. (Ìṣe 8:18; 10:44-46) Ó jọ pé àwọn tó gba àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ yìí ò fún àwọn míì. (Ìṣe 8:5-7, 14-17) Bí àpẹẹrẹ, aláṣẹ ìjọba kan lè fún ẹnì kan ní ìwé ìwakọ̀, àmọ́ ẹni yẹn ò láṣẹ láti fún ẹlòmíì ní ìwé ìwakọ̀. Torí náà, ó jọ pé ìgbà táwọn àpọ́sítélì àtàwọn tó gba ẹ̀bùn yìí látọ̀dọ̀ wọn kú ni fífi èdè fọ̀ dópin.
Ṣé ẹ̀bùn fífi èdè fọ̀ ṣì wà dòní?
Ẹ̀rí fi hàn pé nǹkan bí ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni ẹ̀bùn fífi èdè fọ̀ lọ́nà ìyanu dópin. Kò sẹ́nì kankan lónìí tó lè fọwọ́ ẹ̀ sọ̀yà pé Ọlọ́run ló fún òun lágbára láti máa fèdè fọ̀. a
Kí la lè fi dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀?
Jésù sọ pé ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ la fi máa dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun mọ̀. (Jòhánù 13:34, 35) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ́ wa pé ìfẹ́ ló máa jẹ́ àmì ìdánimọ̀ tó máa wà títí lọ tá a fi máa dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀. (1 Kọ́ríńtì 13:1, 8) Ó sọ pé ẹ̀mí Ọlọ́run máa mú kí àwọn Kristẹni ní àwọn ànímọ́ tá à ń pè ní “èso ti ẹ̀mí,” ìfẹ́ sì ni àkọ́kọ́ nínú àwọn ànímọ́ yìí.—Gálátíà 5:22, 23.
a Wo àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Fífi Èdè Fọ̀ Ti Wá?”