Ibo Là Ń Pè Ní Ọ̀run?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ọ̀nà pàtàkì mẹ́ta ni Bíbélì gbà lo ọ̀rọ̀ náà, “ọ̀run”: (1) ọ̀run tí a lè fójú rí; (2) ibi táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ń gbé; àti (3) ohun tó ṣàpẹẹrẹ ipò àṣẹ gíga. Àyíká ọ̀rọ̀ la fi máa ń mọ èyí tó jẹ́ nínú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. a
Ọ̀run tí a lè fojú rí. “Ọ̀run” yìí ń tọ́ka sí ojú ọ̀run tá a máa ń rí láti ayé, níbi tí atẹ́gùn ti ń fẹ́, tí àwọn ẹyẹ ti ń fò, tí òfuurufú ti ń rọ̀jò àti yìnyín àti ibi tí ààrá ti máa ń sán. (Sáàmù 78:26; Òwe 25:3; Aísáyà 55:10; Lúùkù 17:24) Ó tún lè túmọ̀ sí ibi gbalasa tó yí òbíríkítí ayé ká, níbi tí “oòrùn àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀” wà.—Diutarónómì 4:19; Jẹ́nẹ́sísì 1:1.
Ibi táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ń gbé. Ọ̀rọ̀ náà, “ọ̀run” tún lè túmọ̀ sí ọ̀run tí a kò lè fojú rí tàbí ibi táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ń gbé. Ó kọjá àgbáálá ayé tá a lè fojú rí. (1 Àwọn Ọba 8:27; Jòhánù 6:38) Ọ̀run yìí ni Jèhófà Ọlọ́run, tó jẹ́ “Ẹ̀mí” àtàwọn áńgẹ́lì tó dá wà. Ẹ̀dá ẹ̀mí náà láwọn áńgẹ́lì yìí. (Jòhánù 4:24; Mátíù 24:36) Láwọn ìgbà míì, “ọ̀run” máa ń dúró fún àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́, ìyẹn “ìjọ àwọn ẹni mímọ́.”—Sáàmù 89:5-7.
Bíbélì tún máa ń lo “ọ̀run” láti tọ́ka sí “ibi . . . tí [Jèhófà] ń gbé” gan-an láàárín àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yòókù. (1 Àwọn Ọba 8:43, 49; Hébérù 9:24; Ìṣípayá 13:6) Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n á lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run, wọn ò sì ní lè dé iwájú Jèhófà mọ́. Àmọ́, wọ́n ṣì máa jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí.—Ìṣípayá 12:7-9, 12.
Ohun tó ṣàpẹẹrẹ ipò àṣẹ gíga. Ìwé Mímọ́ tún máa ń fi “ọ̀run” ṣàpẹẹrẹ ipò tó gá, pàápàá ipò àwọn aláṣẹ. Àwọn tó máa ń wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀ ni:
Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀, tó jẹ́ Olódùmarè Ọba Aláṣẹ—2 Kíróníkà 32:20; Lúùkù 15:21.
Ìjọba Ọlọ́run, tó máa rọ́pò ìjọba àwọn èèyàn. Bíbélì pe Ìjọba yìí ní “ọ̀run tuntun”—Aísáyà 65:17; 66:22; 2 Pétérù 3:13. b
Àwọn Kristẹni tó wà láyé àmọ́ tí wọ́n ń retí àtilọ sọ́run.—Éfésù 2:6.
Àwọn ìjọba èèyàn tó ń ṣàkóso lé àwọn tó kù lórí.—Aísáyà 14:12-14; Dáníẹ́lì 4:20-22; 2 Pétérù 3:7.
Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú tó ń ṣàkóso ayé báyìí.—Éfésù 6:12; 1 Jòhánù 5:19
Báwo ni ọ̀run ṣe rí?
Ọwọ́ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó wà lọ́run dí gan an. Àìmọye mílíọ̀nù àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ló ń gbé lọ́run, tí wọ́n ń “pa ọ̀rọ̀ [Jèhófà] mọ́.”—Sáàmù 103:20, 21; Dáníẹ́lì 7:10.
Bíbélì sọ pé ọ̀run mọ́lẹ̀ yòò. (1 Tímótì 6:15, 16) Wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí ọ̀run tó ní “ìrísí ìtànyòò” nínú ìran, “ìṣàn iná” sì ni Dáníẹ́lì rí nínú ìran ọ̀run tó rí. (Ìsíkíẹ́lì 1:26-28; Dáníẹ́lì 7:9, 10) Ọ̀run jẹ́ mímọ́, tàbí ká sọ pé ó mọ́ tónítóní, ó sì rẹwà.—Sáàmù 96:6; Aísáyà 63:15; Ìṣípayá 4:2, 3.
Gbogbo àlàyé tí Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ́ pé ibi ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ni ọ̀run jẹ́. (Ìsíkíẹ́lì 43:2, 3) Àmọ́, kò sí bí àwa èèyàn ṣe lè lóye bí ọ̀run ṣe rí gan an, torí òye wa ò lè gbé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́run torí pé a kì í ṣe ẹ̀dá ẹ̀mí.
a Ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run” wá látinú èdè Hébérù tó túmọ̀ sí “gíga” tàbí “gíga jù lọ.” (Òwe 25:3) Wo ìwé The New Brown, Driver, and Briggs Hebrew and English Lexicon of the Old Testament, ojú ìwé 1029.
b Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tó ń jẹ́ McClintock and Strong’s Cyclopedia sọ pé ọ̀run tuntun tí Aísáyà 65:17 ń tọ́ka sí ni “ìṣàkóso tuntun, ìjọba tuntun”—Ìdìpọ̀ Kẹrin, ojú ìwé 122.