Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Wa?
Ohun tí Bíbélì sọ
Onírúurú ọ̀nà ni a lè gbà béèrè ìbéèrè yìí. Bí àpẹẹrẹ, a lè béèrè pé Kí nìdí tí a fi wà láyé? tàbí Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá mi sáyé? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìdí tí Ọlọ́run fi dá wa ni pé ká lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú rẹ̀. Wo díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Bíbélì kọ́ wa.
Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá wa. Bíbélì sọ pé: “[Ọlọ́run] ni ó ṣẹ̀dá wa, kì í sì í ṣe àwa fúnra wa.”—Sáàmù 100:3; Ìṣípayá 4:11.
Ó ní ìdí tí Ọlọ́run fi dá ohun gbogbo, tó fi mọ́ àwa èèyàn.—Aísáyà 45:18.
Ọlọ́run dá ‘àìní ti ẹ̀mí’ mọ́ wa, ìyẹn ni pé kó máa wù wá láti mọ ìdí tó fi dá wa. (Mátíù 5:3) Ọlọ́run fẹ́ ká máa tẹ́ àìní yìí lọ́rùn.—Sáàmù 145:16.
Ọ̀nà tí a lè gbà tẹ́ àìní ti ẹ̀mí tí Ọlọ́run dá mọ́ wa yìí lọ́rùn ni pé ká jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lè máa rò pé kò ṣeé ṣe láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8; 2:23.
Tí a bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tí Ọlọ́run torí rẹ̀ dá wa. Bíbélì sọ ohun náà nínú Oníwàásù 12:13. Ó ní: “Bẹ̀rù Ọlọ́run kí o sì pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́: nítorí èyí ni ojúṣe gbogbo ènìyàn.”—Bíbélì Mímọ́.
Lọ́jọ́ iwájú, a ó máa ṣe ohun tí Ọlọ́run torí rẹ̀ dá wa ní kíkún nígbà tó bá fi òpin sí ìpọ́njú, tó sì fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó ń jọ́sìn rẹ̀ ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Sáàmù 37:10, 11.