Kí Ni Ìpadàbọ̀ Kristi?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí Kristi máa wá ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn lórí ilẹ̀ ayé. a Bí àpẹẹrẹ, Mátíù 25:31-33 sọ pé:
“Nígbà tí Ọmọ ènìyàn [Jésù Kristi] bá dé nínú ògo rẹ̀, àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó sì kó jọ níwájú rẹ̀, yóò sì ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn kan tí ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́. Yóò sì fi àwọn àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ewúrẹ́ sí òsì rẹ̀.”
Àkókò ìdájọ́ tí Bíbélì mẹ́nu kàn yìí jẹ́ ara “ìpọ́njú ńlá,” irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí láyé. Ìpọ́njú ńlá yẹn máa dópin nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. (Mátíù 24:21; Ìṣípayá 16:16) Àwọn ọ̀tá Kristi tí wọ́n dúró fún ewúrẹ́ nínú àpèjúwe tí Kristi ṣe “yóò fara gba ìyà ìdájọ́ ìparun àìnípẹ̀kun.” (2 Tẹsalóníkà 1:9; Ìṣípayá 19:11, 15) Àmọ́, àwọn ìránṣẹ́ Kristi tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, ìyẹn àwọn àgùntàn, máa ní ìrètí “ìyè àìnípẹ̀kun.”—Mátíù 25:46.
Ìgbà wo ni Kristi máa dé?
Jésù sọ pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n.” (Mátíù 24:36, 42; 25:13) Àmọ́, ó sọ “àmì” alápá púpọ̀ kan tó ṣeé fojú rí táá jẹ́ ká mọ ìgbà tí Kristi ń bọ̀.—Mátíù 24:3, 7-14; Lúùkù 21:10, 11.
Ṣé Kristi wá gégẹ́ bí ẹlẹ́ran ara tàbí ẹ̀dá ẹ̀mí?
Ọlọ́run jí Jésù dìde nínú ẹ̀mí, torí náà ó wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí, kì í ṣe bí ẹlẹ́ran ara. (1 Kọ́ríńtì 15:45; 1 Pétérù 3:18) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ́jọ́ tó ku ọ̀la tó máa kú pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ayé kì yóò sì rí mi mọ́.”—Jòhánù 14:19.
Èrò tí kò tọ́ táwọn èèyàn ní nípa ìpadàbọ̀ Kristi
Èrò tí kò tọ́: Nígbà tí Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn máa rí Jésù “tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà,” ohun tó túmọ̀ sí ni pé àwọn èèyàn máa rí Jésù nígbà tó bá ń bọ̀.—Mátíù 24:30.
Òótọ́: Lọ́pọ̀ ìgbà, Bíbélì máa ń lo àwọsánmà fún ohun téèyàn kò lè fojú rí. (Léfítíkù 16:2; Númérì 11:25; Diutarónómì 33:26) Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “Èmi yóò wá sọ́dọ̀ rẹ nínú àwọsánmà ṣíṣú.” (Ẹ́kísódù 19:9) Mósè kò rí Ọlọ́run sójú. Bákan náà, Kristi ‘wá lórí àwọsánmà’ ni ti pé àwọn èèyàn fòye mọ ìpadàbọ̀ rẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lè rí i kòrókòró.
Èrò tí kò tọ́: Nígbà tí Ìṣípayá 1:7 ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí Jésù ń bọ̀, gbólóhùn náà “gbogbo ojú ni yóò sì rí i,” tó wà nínú ẹsẹ yìí túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn máa rí i kòrókòró.
Òótọ́: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Bíbélì lò fún “ojú” àti “rí i” nígbà míì máa ń túmọ̀ sí kéèyàn fòye mọ nǹkan tàbí kíyè sí i, kì í ṣe ojú téèyàn fi ń ríran ló ń tọ́ka sí. b (Mátíù 13:15; Lúùkù 19:42; Róòmù 15:21; Éfésù 1:18) Bíbélì sọ pé Jésù tó jíǹde ni “ẹni . . . tí ń gbé nínú ìmọ́lẹ̀ tí kò ṣeé sún mọ́, ẹni tí kò sí . . . ènìyàn . . . tí ó lè rí i.” (1 Tímótì 6:16) Torí náà, ọ̀rọ̀ náà “gbogbo ojú ni yóò sì rí i” túmọ̀ sí pé gbogbo èèyàn yóò kíyè sí i pé Jésù ni ẹni tí yóò mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ.—Mátíù 24:30.
Èrò tí kò tọ́: Ọ̀rọ̀ tó wà ní 2 Jòhánù 7 fi hàn pé Jésù máa wá gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran ara.
Òótọ́: Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé: “Nítorí ọ̀pọ̀ ẹlẹ́tàn ti jáde lọ sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ Jésù Kristi pé ó wá nínú ẹran ara.”
Nígbà ayé àpọ́sítélì Jòhánù, àwọn kan kọ̀ jálẹ̀ pé Jésù wá sí ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ran ara. Àwọn yẹn ni wọ́n ń pè ní Gnostics, ìyẹn àwọn onímọ̀-awo. Ọ̀rọ̀ tó wà ní 2 Jòhánù 7 ló já irọ́ wọn.