Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìṣẹ́yún?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò lo ọ̀rọ̀ náà “ìṣẹ́yún” nígbà tó mẹ́nu bà á pé oyún yọ lára èèyàn. Ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì ló sọ èrò Ọlọ́run nípa ẹ̀mí èèyàn, títí kan ti ọmọ tí a ò tíì bí.
Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìwàláàyè. (Jẹ́nẹ́sísì 9:6; Sáàmù 36:9) Gbogbo ohun ẹlẹ́mìí ló sì ṣeyebíye lójú Ọlọ́run, títí kan ẹ̀mí ọmọ tí a ò tíì bí tó wà nínú ikùn ìyá rẹ̀. Torí náà, tí ẹnì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ́yún, ńṣe ló pààyàn.
Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé: “Tí àwọn èèyàn bá ń jà, tí wọ́n sì ṣe obìnrin tó lóyún léṣe, tó wá bímọ nígbà tí àsìkò rẹ̀ kò tíì tó, àmọ́ tí kò la ẹ̀mí lọ, ẹni tó ṣe obìnrin náà léṣe gbọ́dọ̀ san owó ìtanràn tí ọkọ rẹ̀ bá bù lé e; kí ó san án nípasẹ̀ àwọn adájọ́. Àmọ́ tó bá la ẹ̀mí lọ, kí o fi ẹ̀mí dípò ẹ̀mí.”—Ẹ́kísódù 21:22, 23. a
Ìgbà wo ni ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn bẹ̀rẹ̀?
Ọlọ́run sọ pé gbàrà tí ọlẹ̀ bá ti sọ nínú obìnrin ni ìwàláàyè ti bẹ̀rẹ̀. Gbogbo ibi tí Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ nípa ọmọ inú tí a kò tíì bí nínú Bíbélì ló ti hàn kedere pé ó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn. Jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé ojú kan náà ni Ọlọ́run fi wo ọmọ inú tí a kò tíì bí àti ọmọ tá a ti bí.
Lábẹ́ ìmísí, Ọba Dáfídì sọ fún Ọlọ́run pé: “Kódà, ojú rẹ rí mi nígbà tí mo ṣì wà nínú ikùn.” (Sáàmù 139:16) Ọlọ́run ka Dáfídì sí ẹ̀dá èèyàn bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò tíì bí i.
Bákan náà, kí wọ́n tó bí wòlíì Jeremáyà ni Ọlọ́run ti ní in lọ́kàn pé òun máa fún un ní iṣẹ́ pàtàkì kan. Ọlọ́run sọ fún un pé: “Kí n tó dá ọ nínú ìyá rẹ ni mo ti mọ̀ ọ́, Kí wọ́n sì tó bí ọ ni mo ti sọ ọ́ di mímọ́. Mo fi ọ́ ṣe wòlíì àwọn orílẹ̀-èdè.”—Jeremáyà 1:5.
Lúùkù, oníṣègùn tó wà lára àwọn tó kọ Bíbélì, lo ọ̀rọ̀ Gírí ìkì kan náà láti fi ṣàpèjúwe ọmọ inú tí a kò tíì bí àti ọmọ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí.—Lúùkù 1:41; 2:12, 16.
Ṣé Ọlọ́run máa dárí ji ẹni tó bá ṣẹ́yún?
Ọlọ́run lè dárí ji àwọn tó ti ṣẹ́yún rí. Tí wọ́n bá fara mọ́ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìwàláàyè, kò sídìí fún wọn láti máa dá ara wọn lẹ́bi. “Aláàánú ni Jèhófà, ó sì ń gba tẹni rò . . . Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.” b (Sáàmù 103:8-12) Jèhófà máa dárí ji gbogbo àwọn tó ti dẹ́ṣẹ̀ kọjá títí kan àwọn tó ti ṣẹ́yún, tí wọ́n bá ronú pìwà dà tinútinú.—Sáàmù 86:5.
Ṣé oyún ṣíṣẹ́ burú tí ẹ̀mí ìyá tàbí ti ọmọ bá wà nínú ewu?
Ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀mí ọmọ tí a ò tíì bí fi hàn pé kò tọ̀nà tẹ́nì kan bá ṣẹ́yún torí pé ẹ̀mí ìyá àbí ti ọmọ wà nínú ewu.
Ohun míì tún wà tí kì í sábà sẹlẹ̀, ìyẹn ni ìgbà tó máa gba pé kí wọ́n yan ẹni tí wọ́n á dá ẹ̀mí rẹ̀ sí nínú ìyá àti ọmọ nígbà tí aboyún kan bá fẹ́ bímọ. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, kí ni ṣíṣe? Àwọn tọ́ràn náà kàn ló máa fúnra wọn pinnu ẹni tí wọ́n máa dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.
a Àwọn kan túmọ̀ rẹ̀ pé obìnrin tó lóyún tí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀ sí ni òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, kò kan ọmọ inú oyún. Àmọ́, obìnrin tó lóyún tàbí ọmọ inú tí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀ sí ni ọ̀rọ̀ Hébérù náà ń tọ́ka sí.
b Bíbélì fi hàn pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.