Kí Làwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìṣípayá Túmọ̀ Sí?
Ohun tí Bíbélì sọ
Orúkọ tí wọ́n ń pe ìwé Ìṣípayá lédè Gíríìkì ni A·po·kaʹly·psis (ìyẹn àpókálíìsì), èyí tó túmọ̀ sí “Ṣíṣí ìbòjú” tàbí “Fífi hàn.” Orúkọ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ṣe ni ìwé Ìṣípayá ṣí ìbòjú lójú àwọn ohun kan tá ò mọ̀ tẹ́lẹ̀, tó sì fi àwọn ohun kan hàn wá tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí wọ́n kọ ọ́. Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú rẹ̀ kò sì tíì ṣẹ.
Ohun tó wà nínú ìwé Ìṣípayá
Ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀.—Ìṣípayá 1:1-9.
Ọ̀rọ̀ tí Jésù fi ránṣẹ́ sí ìjọ méje.—Ìṣípayá 1:10–3:22.
Ìran tó dá lórí Ọlọ́run bó ṣe wà lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run.— Ìṣípayá 4:1-11.
Onírúurú ìran, ọ̀kan tẹ̀ lé òmíràn:
Èdìdì méje.—Ìṣípayá 5:1–8:6.
Kàkàkí méje, tí mẹ́ta tí wọ́n fun kẹ́yìn sì fa ègbé mẹ́ta.—Ìṣípayá 8:7–14:20.
Àwokòtò méje tó ní ìyọnu àjàkálẹ̀ kọ̀ọ̀kan nínú, èyí tó dúró fún ìdájọ́ Ọlọ́run tí wọ́n máa dà jáde sórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 15:1–16:21.
Àwọn ìran tó dá lórí bí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run yóò ṣe pa run.—Ìṣípayá 17:1–20:10.
Àwọn ìran tó dá lórí bí ìbùkún Ọlọ́run ṣe máa wà ní ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 20:11–22:5.
Ìparí.—Ìṣípayá 22:6-21.
Ohun tó máa jẹ́ ká lóye ìwé Ìṣípayá
Ìtumọ̀ rere ló ní fáwọn tó ń sin Ọlọ́run, kì í ṣe èyí tá á máa dẹ́rù bà wọ́n tàbí dáyà já wọn. Ọ̀pọ̀ máa ń sọ pé àjálù ńlá ni “àpókálíìsì” túmọ̀ sí, àmọ́ ìwé Ìṣípayá sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí rẹ̀ pé aláyọ̀ ni ẹni tó bá ń ka ọ̀rọ̀ inú rẹ̀, tó lóye rẹ̀, tó sì ń pa á mọ́.—Ìṣípayá 1:3; 22:7.
Ìwé Ìṣípayá lo ọ̀pọ̀ “àmì,” ó sì mẹ́nu ba àwọn ohun kan lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.—Ìṣípayá 1:1.
Àwọn ìwé míì nínú Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹni pàtàkì àtàwọn ohun míì tí ìwé Ìṣípayá mẹ́nu bà lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, irú bíi:
Jèhófà—“Ọlọ́run tòótọ́ nínú ọ̀run” àti Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo.—Diutarónómì 4:39; Sáàmù 103:19; Ìṣípayá 4:11; 15:3.
Jésù Kristi—“Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run.”—Jòhánù 1:29; Ìṣípayá 5:6; 14:1.
Sátánì Èṣù—ọ̀tá Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 3:14, 15; Jòhánù 8:44; Ìṣípayá 12:9.
Bábílónì Ńlá—bíi ti Bábílónì ìgbàanì (ìyẹn Bábélì), ó jẹ́ ọ̀tá Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn èèyàn rẹ̀, òun sì ni orísun ẹ̀kọ́ èké.—Jẹ́nẹ́sísì 11:2-9; Aísáyà 13:1, 11; Ìṣípayá 17:4-6; 18:4, 20.
“Òkun”—Aráyé oníwà búburú tó ta ko Ọlọ́run.—Aísáyà 57:20; Ìṣípayá 13:1; 21:1.
Àwọn ohun tí wọ́n ń lò nínú àgọ́ ìjọsìn Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì, irú bíi: àpótí májẹ̀mú, òkun tó dà bíi gíláàsì (ìyẹn bàsíà fún wíwẹ̀), fìtílà, ọrẹ ẹbọ tùràrí, àti pẹpẹ ìrúbọ.—Ẹ́kísódù 25:10, 17, 18; 40:24-32; Ìṣípayá 4:5, 6; 5:8; 8:3; 11:19.
Àwọn ẹranko ẹhànnà—tó dúró fún ìjọba èèyàn.—Dáníẹ́lì 7:1-8, 17-26; Ìṣípayá 13:2, 11; 17:3.
Nọ́ńbà tí wọ́n lò lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.—Ìṣípayá 1:20; 8:13; 13:18; 21:16.
Àwọn ìran náà máa nímùúṣẹ ní “ọjọ́ Olúwa,” èyí tó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ lọ́dún 1914 tí Jésù sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba. (Ìṣípayá 1:10) Torí náà, ó yẹ ká máa retí pé púpọ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìwé Ìṣípayá máa ṣẹ lákòókò wa yìí..
Ohun tó ràn wá lọ́wọ́ láti lóye àwọn ìwé tó kù nínú Bíbélì náà la nílò ká lè lóye ohun tó wà nínú ìwé Ìṣípayá, ìyẹn ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ìrànlọ́wọ́ àwọn tó ti lóye rẹ̀.—Ìṣe 8:26-39; Jákọ́bù 1:5.