Kí Ni Jerúsálẹ́mù Tuntun?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ẹ̀ẹ̀mejì ni ọ̀rọ̀ náà “Jerúsálẹ́mù Tuntun” fara hàn nínú Bíbélì. Ìlú ìṣàpẹẹrẹ ló jẹ́, ó dúró fún àwùjọ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó máa lọ sọ́run láti bá a ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run. (Ìfihàn 3:12; 21:2) Bíbélì jẹ́ ká rí i pé a tún lè pe àwùjọ yìí ní ìyàwó Kristi.
Àwọn ohun tá a lè fi dá Jerúsálẹ́mù Tuntun mọ̀
Ọ̀run ni Jerúsálẹ́mù Tuntun wà. Gbogbo ìgbà tí Bíbélì bá mẹ́nu ba Jerúsálẹ́mù Tuntun, ó máa ń sọ pé ó sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, àwọn áńgẹ́lì sì ń ṣọ́ àwọn ẹnubodè ìlú náà. (Ìfihàn 3:12; 21:2, 10, 12) Ohun míì tún ni pé, bí ìlú náà ṣe tóbi tó fẹ̀rí hàn pé kò lè jẹ́ orí ilẹ̀ ayé ló wà. Ìwọ̀n ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àti gíga rẹ̀ dọ́gba, ó jẹ́ “ẹgbẹ̀rún méjìlá ìwọ̀n fọ́lọ́ǹgì,” tàbí “sítédíọ̀mù,” yí ká. a (Ìfihàn 21:16; Bíbélì Mímọ́) A jẹ́ pé ìlú náà máa fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ọgọ́ta (560) kìlómítà, á ga dé ojú ọ̀run.
Àwùjọ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ló para pọ̀ di Jerúsálẹ́mù Tuntun, ìyẹn ìyàwó Kristi. Bíbélì pe Jerúsálẹ́mù Tuntun ní “ìyàwó . . . , aya Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìfihàn 21:9, 10) Nínú àpèjúwe yìí, Jésù Kristi ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ń tọ́ka sí. (Jòhánù 1:29; Ìfihàn 5:12) “Aya Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” ìyẹn ìyàwó Kristi, dúró fún àwọn Kristẹni tó máa wà pẹ̀lú Jésù lọ́run. Bíbélì fi àjọṣe tó wà láàárín Jésù àtàwọn Kristẹni yìí wé àjọṣe àárín ọkọ àti ìyàwó. (2 Kọ́ríńtì 11:2; Éfésù 5:23-25) Bákan náà, wọ́n gbẹ́ “orúkọ méjìlá àwọn àpọ́sítélì méjìlá ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” sára àwọn òkúta ìpìlẹ̀ Jerúsálẹ́mù Tuntun. (Ìfihàn 21:14) Ìsọfúnni yìí jẹ́ kí ohun tí Jerúsálẹ́mù Tuntun túmọ̀ sí túbọ̀ dá wa lójú, níwọ̀n ìgbà tó ti jẹ́ pé “[orí] ìpìlẹ̀ àwọn àpọ́sítélì àti àwọn wòlíì” la kọ́ àwọn Kristẹni tó ń lọ sọ́run sí.—Éfésù 2:20.
Jerúsálẹ́mù Tuntun wà lára ìjọba kan. Jerúsálẹ́mù ayé àtijọ́ ni olú ìlú Ísírẹ́lì, tí Ọba Dáfídì, Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ àti àtọmọdọ́mọ wọn ti jọba “[lórí] ìtẹ́ Jèhófà.” (1 Kíróníkà 29:23) Torí náà, ìlú Jerúsálẹ́mù tí Bíbélì pè ní “ìlú mímọ́,” dúró fún ìṣàkóso Ọlọ́run láti ìlà ìdílé Dáfídì. (Nehemáyà 11:1) Àwọn tó máa lọ bá Jésù lọ́run láti “ṣàkóso bí ọba lé ayé lórí” ló para pọ̀ di Jerúsálẹ́mù Tuntun tí Bíbélì tún pè ní “ìlú mímọ́.”—Ìfihàn 5:9, 10; 21:2.
Jerúsálẹ́mù Tuntun máa mú ìbùkún wá sórí àwọn èèyàn ní ayé. Bíbélì sọ pé Jerúsálẹ́mù Tuntun “ń ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run,” tó fi hàn pé Ọlọ́run ń lò ó láti bójú tó àwọn ohun tó jẹ mọ́ ilẹ̀ ayé. (Ìfihàn 21:2) Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká rí ìsopọ̀ tó wà láàárín Jerúsálẹ́mù Tuntun àti Ìjọba Ọlọ́run, tí Ọlọ́run máa lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ “ní ayé, bíi ti ọ̀run.” (Mátíù 6:10) Lára ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fáwọn èèyàn lórí ilẹ̀ ayé ni pé kó bù kún wọn láwọn ọ̀nà yìí:
Ó máa mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò. “Odò omi ìyè kan” ń ṣàn láti Jerúsálẹ́mù Tuntun, ó sì ń bomi rin “àwọn igi ìyè” tó “wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè lára dá.” (Ìfihàn 22:1, 2) Ìwòsàn nípa tara àti nípa tẹ̀mí yìí máa mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò, ó sì máa jẹ́ káwọn èèyàn lè ní ìyè àìnípẹ̀kun, kí wọ́n sì di ẹni pípé bí Ọlọ́run ṣe ní in lọ́kàn látìbẹ̀rẹ̀.—Róòmù 8:21.
Àjọṣe tó gún régé máa wà láàárín Ọlọ́run àti aráyé. Ẹ̀ṣẹ̀ ti mú kí ọmọ aráyé jìnnà sí Ọlọ́run. (Àìsáyà 59:2) Tí kò bá sí ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, àsọtẹ́lẹ̀ yìí máa wá ṣẹ ní kíkún, tó sọ pé: “Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, á máa bá wọn gbé, wọ́n á sì jẹ́ èèyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ máa wà pẹ̀lú wọn.”—Ìfihàn 21:3.
Ìyà àti ikú máa dópin. Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti “nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìfihàn 21:4.
a Àwọn ará Róòmù ló máa ń fi sítédíọ̀mù díwọ̀n, sítédíọ̀mù kan sì jẹ́ mítà márùnlélọ́gọ́sàn-án (185).