Kí Nìdí Tí A Fi Pe Jésù Ní Ọmọ Ọlọrun?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì máa ń pe Jésù ní “Ọmọ Ọlọ́run” (Jòhánù 1:49) Ọ̀rọ̀ náà, “Ọmọ Ọlọ́run” fi hàn pé Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo tàbí Orísun gbogbo ẹ̀mí, títí kan ti Jésù. (Sáàmù 36:9; Ìfihàn 4:11) Bíbélì kò kọ́ni pé Ọlọ́run ní bàbá Jésù bí ìgbà téèyàn bímọ.
Bíbélì tún pe àwọn áńgẹ́lì ní “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́”. (Jóòbù 1:6) Bíbélì tún sọ pé èèyàn àkọ́kọ́, Ádámù jẹ́ “Ọmọ Ọlọ́run.” (Lúùkù 3:38) Àmọ́, torí pé Jésù jẹ́ àkọ́bí nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá àti pé òun nìkan ni Ọlọ́run dá ní tààràtà, Bíbélì pe Jésù ní àkọ́kọ́ Ọmọ Ọlọ́run.
Ǹjẹ́ Jésù ti gbé ọ̀run kí wọ́n tó bí i sáyé?
Bẹ́ẹ̀ ni. Jésù jẹ́ ẹ̀mí ní ọ̀run kí wọ́n tó bí i sáyé ní èèyàn. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé òun “sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run.”—Jòhánù 6:38; 8:23.
Ọlọ́run dá Jésù kó tó dá ohunkóhun míì. Bíbélì sọ nípa Jésù pé:
“Òun ni . . . àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá.”—Kólósè 1:15.
Òun ni “ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ohun tí Ọlọ́run dá.”—Ìfihàn 3:14.
Àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ nípa “ẹni tó ti wà láti ìgbà àtijọ́, láti àwọn ọjọ́ tó ti pẹ́” ṣẹ sí Jésù lára—Míkà 5:2; Mátíù 2:4-6.
Kí ni Jésù ń ṣe kó tó wá sáyé?
Ó wà ní ipò gíga ní ọ̀run. Jésù sọ nípa ipò yìí nígbà tó ń gbàdúrà, ó ní: “Bàbá ṣe mí lógo . . . pẹ̀lú ògo tí mo ti ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kí ayé tó wà”—Jòhánù 17:5.
Ó ran bàbá rẹ̀ lọ́wọ́ láti dá ohun gbogbo yòókù. Jésù ṣiṣẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọ́run “gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́.” (Òwe 8:30) Bíbélì sọ nípa Jésù pé: “Ipasẹ̀ rẹ ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé.”—Kólósè 1:16.
Ọlọ́run lo Jésù láti dá ohun gbogbo yòókù. Ara àwọn ohun náà ni gbogbo àwọn áńgẹ́lì yòókù títí kan ayé àti ọ̀run. (Ìfihàn 5:11) Láwọn ọ̀nà kan, irú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó wà láàárín Ọlọ́run àti Jésù dà bí ti ayàwòrán ilé àti kọ́lékọ́lé. Ayàwòrán ilé yóò yàwòrán bí ilé kan ṣe máa rí, kọ́lékọ́lé á kọ́ ilé tó rí nínú àwòrán náà.
Jésù ni Ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tí a sọ nípa ìgbésí ayé Jésù kó tó wá sáyé, Bíbélì pe Jésù ní “Ọ̀rọ̀ náà.” (Jòhánù 1:1) Dájúdájú, èyí túmọ̀ sí pé Ọlọ́run lo Ọmọ rẹ̀ láti sọ àwọn nǹkan àti ẹ̀kọ́ fún àwọn ẹ̀dá yòókù tí wọ́n jẹ́ ẹ̀mí.
Ó jọ pé Jésù tún ṣe Agbọ̀rọ̀sọ Ọlọ́run láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ láyé. Ó ṣeéṣe kí Ọlọ́run lo Jésù tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ nígbà tó ń sọ àwọn nǹkan fún Ádámù àti Éfà nínú ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Ó lè jẹ́ Jésù ni áńgẹ́lì tó darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ nínú aginjù, ó sì lè jẹ́ ohùn rẹ̀ ni wọ́n ṣègbọràn sí nígbà náà—Ẹ́kísódù 23:20-23. a
a Kìí ṣe “Ọ̀rọ̀ náà” nìkan ni áńgẹ́lì tí Ọlọ́run gba ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó lo àwọn ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ áńgẹ́lì tí wọn kì í ṣe àkọ́bí rẹ̀ láti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ ní Òfin rẹ̀ —Ìṣe 7:53; Gálátíà 3:19; Hébérù 2:2, 3.