Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Di Àtúnbí?

Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Di Àtúnbí?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ọ̀rọ̀ náà “àtúnbí” túmọ̀ sí àjọṣe tuntun kan tó bẹ̀rẹ̀ láàárín Ọlọ́run àti ẹni tó di àtúnbí. (Jòhánù 3:3, 7) Ọlọ́run sọ àwọn tó di àtúnbí yìí di ọmọ rẹ̀. (Róòmù 8:15, 16; Gálátíà 4:5; 1 Jòhánù 3:1) Bíi tẹnì kan tí òfin fọwọ́ sí pé kí wọ́n gbà ṣọmọ lọ̀rọ̀ wọ́n rí, ṣe lonítọ̀hún máa di ọmọ ẹni tó gbà á ṣọmọ. Àwọn tó di àtúnbí náà máa ń di ara ìdílé Ọlọ́run.​—2 Kọ́ríńtì 6:18.

Kí ló máa ń mú kí ẹnì kan di àtúnbí?

 Jésù sọ pé: “Láìjẹ́ pé a tún ẹnikẹ́ni bí, kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.” (Jòhánù 3:3) Torí náà, kí ẹnì kan tó lè bá Kristi nínú Ìjọba Ọlọ́run, ó máa kọ́kọ́ di àtúnbí. Àtọ̀run ni Ìjọba Ọlọ́run á ti máa ṣàkóso, ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé àwọn tó ní “ìbí tuntun” ni ohun ìní tí wọ́n ‘fi pa mọ́ dè wọ́n ní ọ̀run.’ (1 Pétérù 1:3, 4) Ó dá àwọn tó di àtúnbí yìí lójú pé àwọn máa ‘ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba’ pẹ̀lú Kristi.​—2 Tímótì 2:12; 2 Kọ́ríńtì 1:21, 22.

Báwo ni ẹnì kan ṣe ń di àtúnbí?

 Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí, ó sọ pé wọ́n máa “fi omi àti ẹ̀mí bí” ẹni tó bá máa di àtúnbí. (Jòhánù 3:5, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n máa kọ́kọ́ ri ẹni náà bọmi, wọ́n á wá fi ẹ̀mí mímọ́ batisí rẹ̀.​—Ìṣe 1:5; 2:1-4.

 Jésù ló kọ́kọ́ di àtúnbí. Inú Odò Jọ́dánì ló ti ṣe ìrìbọmi, Ọlọ́run wá fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án, tàbí ká sọ pé Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ batisí rẹ̀. Ìyẹn sọ Jésù di àtúnbí ọmọ Ọlọ́run, ó sì wá nírètí pé òun máa pa dà sọ́run. (Máàkù 1:9-​11) Nígbà tó yá, Ọlọ́run jí Jésù dìde lẹ́yìn tó kú, ó wá di ẹ̀dá ẹ̀mí, ó sì pa dà sọ́run.​—Ìṣe 13:33.

 Àwọn míì tó di àtúnbí náà kọ́kọ́ ṣèrìbọmi kí Ọlọ́run tó fẹ̀mí yàn wọ́n. a (Ìṣe 2:38, 41) Ìgbà yẹn ló tó dá wọn lójú pé àwọn máa lọ sọ́run, Ọlọ́run á sì jẹ́ kó ṣeé ṣe tó bá dìgbà àjíǹde.​—1 Kọ́ríńtì 15:42-​49.

Èrò tí kò tọ́ táwọn èèyàn ní nípa dídi àtúnbí

 Èrò tí kò tọ́: Kí ẹnì kan tó lè rígbàlà tàbí kó tó lè di Kristẹni, ó gbọ́dọ̀ di àtúnbí.

 Òótọ́: Kì í ṣe àwọn tó di àtúnbí, tí wọ́n máa bá Kristi jọba lọ́run nìkan ni ẹbọ ìràpadà Jésù máa jẹ́ kí wọ́n rígbàlà, àwọn tó máa wà láyé tí Ìjọba Ọlọ́run bá ti ń ṣàkóso náà máa rígbàlà. (1 Jòhánù 2:1, 2; Ìṣípayá 5:9, 10) Àwọn Kristẹni tá a dárúkọ ṣìkejì yẹn máa láǹfààní láti máa gbé láyé nínú Párádísè títí láé.​—Sáàmù 37:29; Mátíù 6:9, 10; Ìṣípayá 21:1-5.

 Èrò tí kò tọ́: Ẹnì kan lè yàn láti di àtúnbí.

 Òótọ́: Gbogbo wa la láǹfààní láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, ká sì rígbàlà. (1 Tímótì 2:3, 4; Jákọ́bù 4:8) Àmọ́ Ọlọ́run ló máa ń yan àwọn tó máa jẹ́ àtúnbí, tàbí lédè míì, ló máa ń pinnu àwọn tóun máa fẹ̀mí yàn. Bíbélì sọ pé àti di àtúnbí “kò sinmi lé ẹni tí ń fẹ́ tàbí lé ẹni tí ń sáré, bí kò ṣe lé Ọlọ́run.” (Róòmù 9:16) A tún lè pe ẹni tó jẹ́ “àtúnbí” ní ẹni tá a “tún bí láti ọ̀run,” ìyẹn jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run ló máa ń yan àwọn tó jẹ́ àtúnbí tàbí ká sọ pé yíyàn wọn jẹ́ “láti ọ̀run.”​—Jòhánù 3:3, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀.

a Ti Kọ̀nílíù àtàwọn èèyàn rẹ̀ nìkan ló yàtọ̀.​—Ìṣe 10:44-48.