Kí Ni Mo Lè Gbàdúrà Fún?
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Kò sóhun tó ò lè gbàdúrà fún tó bá ṣáà ti bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, bó ṣe wà nínú Bíbélì. “Ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.” (1 Jòhánù 5:14) Ṣó o lè sọ ohun tó ń dùn ẹ́ lọ́kàn fún Ọlọ́run? Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì ṣáà sọ pé: “Ẹ tú ọkàn-àyà yín jáde níwájú [Ọlọ́run].”—Psalm 62:8.
Àpẹẹrẹ ohun tó o lè gbàdúrà fún
Ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.—Lúùkù 17:5.
Kí ẹ̀mí mímọ́, tàbí agbára Ọlọ́run, ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́.—Lúùkù 11:13.
Okun láti kojú ìṣòro, kó o sì dènà inúnibíni.—Fílípì 4:13.
Ìbalẹ̀ Ọkàn àti àlàáfíà.—Fílípì 4:6, 7.
Ọgbọ́n láti ṣe ìpinnu tó tọ́.—Jákọ́bù 1:5.
Oúnjẹ́ Òòjọ́.—Mátíù 6:11.
Ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.—Mátíù 6:12.