Kí Nìdí Tí Àwa Èèyàn Fi Ń Kú?
Ohun tí Bíbélì sọ
Kò burú rárá tí a bá béèrè pé kí nìdí tí àwa èèyàn fi ń kú, àgàgà tí ẹnì kan tá a fẹ́ràn gan-an bá kú. Bíbélì sọ pé: “Oró ikú ni ẹ̀ṣẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 15:56, Bíbélì Mímọ́.
Kí nìdí tí àwa èèyàn fi ń dẹ́sẹ̀ tí a sì ń kú?
Àwọn èèyàn tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, ìyẹn Ádámù àti Éfà kú torí pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19) Ohun kan ṣoṣo tó lè jẹ́ àbájáde ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọ́n hù sí Ọlọ́run ni ikú, torí pé Ọlọ́run “ni orísun ìyè.”—Sáàmù 36:9; Jẹ́nẹ́sísì 2:17.
Gbogbo àtọmọdọ́mọ Ádámù pátá ló jogún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Gbogbo èèyàn kú nítorí gbogbo wọn ń dẹ́ṣẹ̀.—Róòmù 3:23.
Bí ikú ṣe máa dópin
Ọlọ́run ṣèlérí pé ìgbà kan ń bọ̀ tí “òun yóò gbé ikú mì títí láé.” (Aísáyà 25:8) Kí Ọlọ́run tó lè mú ikú kúrò, ó gbọ́dọ̀ fòpin sí ẹ̀ṣẹ̀ tó ń fa ikú. Ọlọ́run yóò fòpin sí ikú nípasẹ̀ Jésù Kristi, ẹni “tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.”—Jòhánù 1:29; 1 Jòhánù 1:7.