Ṣé Kristẹni Lè Gba Ìtọ́jú Lọ́dọ̀ Àwọn Dókítà?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bẹ́ẹ̀ ni o! Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé, “àwọn ẹni tí ó ní ìlera kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀” fi hàn pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun lè gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn dókítà. (Mátíù 9:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé ìṣègùn, ó fún àwọn tó fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní àwọn ìlànà tí wọ́n lè tẹ̀ lé.
Àwọn ìbéèrè tó o lè bi ara rẹ
1. Ṣé mo lóye ìtọ́jú tí mo fẹ́ gbà yìí dáadáa? Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé ká wá ojúlówó ìsọfúnni dípò ká máa “ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀” táwọn èèyàn sọ.—Òwe 14:15.
2. Ṣé ó yẹ kí n wádìí lọ́dọ̀ dókítà méjì tàbí mẹ́ta nípa ìtọ́jú yìí? Tí àìsàn tó ń ṣe ọ́ bá le gan-an, ó máa dáa kó o ní “ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.”—Òwe 15:22.
3. Ṣé mi ò ní rú òfin Ọlọ́run tó ní kí n “ta kété sí . . . ẹ̀jẹ̀” tí mo bá gba ìtọ́jú yìí?—Ìṣe 15:20.
4. Ṣé ìtọ́jú yìí kò ní agbára òkùnkùn nínú? Bíbélì dẹ́bi fún àṣà “bíbá ẹ̀mí lò.” (Gálátíà 5:19-21) Gbé àwọn ìbéèrè yìí yẹ̀wò tó o bá fẹ́ pinnu bóyá ìtọ́jú náà ní agbára òkùnkùn nínú:
Ǹjẹ́ oníṣègùn náà máa ń lo agbára òkùnkùn?
Ǹjẹ́ ọ̀nà tí oníṣègùn náà gbà ń tọ́jú aláìsàn fi hàn pé ó gbà gbọ́ pé àwọn òrìṣà tó ń bínú tàbí àwọn ọ̀tá tó ń lo agbára òkùnkùn ló ń fa àìsàn náà?
Ṣé oníṣègùn náà máa ń rú ẹbọ, àbí ó máa ń pọfọ̀ tàbí ó máa ń lọ́wọ́ nínú àwọn ààtò ìbẹ́mìílò míì tó bá fẹ́ ṣe oògùn tàbí tó fẹ́ sọ bí wọ́n ṣe máa lò ó?
5. Ṣé ọ̀rọ̀ ìlera mi ni mò ń rò ṣáá nígbà gbogbo? Bíbélì sọ pé: ‘Jẹ́ kí ìfòyebánilò rẹ di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.’ (Fílípì 4:5) Tó o bá jẹ́ afòyebánilò, “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù” ni wàá gbájú mọ́, irú bíi kó o máa fi àkókò rẹ sin Ọlọ́run.—Fílípì 1:10; Mátíù 5:3.