Àwọn Wo Làwọn Néfílímù?
Ohun tí Bíbélì sọ
Fìrìgbọ̀n tó ga gògòrò làwọn Néfílímù, àkàndá ẹ̀dá ni wọ́n, wọ́n sì rorò bí ataare. Àwọn áńgẹ́lì burúkú tó lájọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin nígbà ayé Nóà ni wọ́n bí àwọn àràmàǹdà ọmọ yìí. a
Bíbélì sọ pé “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí àwọn ọmọbìnrin ènìyàn, pé wọ́n dára ní ìrísí.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:2) “Àwọn ọmọ Ọlọ́run” yìí làwọn áńgẹ́lì tó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run nígbà tí wọ́n “ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì” ní ọ̀run, tí wọ́n gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀, tí “wọ́n sì ń mú aya fún ara wọn, èyíinì ni, gbogbo ẹni tí wọ́n bá yàn.”—Júúdà 6; Jẹ́nẹ́sísì 6:2.
Àjọṣepọ̀ tí kò bójú mu yìí ló mú kí wọ́n bí àwọn ọmọ àràmàǹdà. (Jẹ́nẹ́sísì 6:4) Àwọn Néfílímù yìí ga gògòrò, wọ́n ya ìkà, wọ́n sì fojú àwọn èèyàn rí màbo. (Jẹ́nẹ́sísì 6:13) Bíbélì tiẹ̀ sọ nípa wọn pé “àwọn ni alágbára ńlá tí wọ́n wà ní ìgbà láéláé, àwọn ọkùnrin olókìkí.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:4) Kódà ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí wọ́n kú, àwọn èèyàn ṣì ń rántí ìwà ìkà ti wọ́n hù.—Jẹ́nẹ́sísì 6:5; Númérì 13:33. b
Èrò tí kò tọ́ nípa àwọn Néfílímù
Èrò tí kò tọ́: Àwọn Néfílímù ṣì ń gbélé ayé títí dòní.
Òótọ́: Jèhófà mú kí àkúnya omi pa àwọn èèyàn burúkú run láyé àtijọ́. Àwọn Néfílímù sì bá àkúnya omi náà lọ. Àmọ́ Nóà àti ìdílé rẹ̀ rí ojúure Jèhófà, àwọn nìkan ló sì la àkúnya omi náà já.—Jẹ́nẹ́sísì 6:9; 7:12, 13, 23; 2 Pétérù 2:5.
Èrò tí kò tọ́: Èèyàn bíi tiwa ni bàbá àwọn Néfílímù náà.
Òótọ́: Bíbélì pe bàbá wọn ní “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:2) Bíbélì sì máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì. (Jóòbù 1:6; 2:1; 38:7) Àwọn áńgẹ́lì lágbára láti gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 19:1-5; Jóṣúà 5:13-15) Àpọ́sítélì Pétérù náà sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ẹ̀mí nínú ẹ̀wọ̀n, àwọn tí wọ́n ti jẹ́ aláìgbọràn nígbà kan, nígbà tí sùúrù Ọlọ́run ń dúró ní àwọn ọjọ́ Nóà.” (1 Pétérù 3:19, 20) Nígbà tí ìwé Júúdà náà ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà, ó ṣàlàyé pé àwọn áńgẹ́lì kan kò ‘dúró ní ipò wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì.’—Júúdà 6.
Èrò tí kò tọ́: Àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n lé kúrò lọ́run làwọn Néfílímù.
Òótọ́: Ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 6:4 jẹ́ ka mọ̀ pé àwọn Néfílímù náà kì í ṣe áńgẹ́lì, kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn ni àràmàǹdà ọmọ táwọn obìnrin tó lájọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì tó gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀ bí. Lẹ́yìn táwọn áńgẹ́lì náà bẹ̀rẹ̀ sí í “mú aya fún ara wọn, èyíinì ni, gbogbo ẹni tí wọ́n bá yàn,” Jèhófà sọ pé ní ọgọ́fà ọdún sí i, òun máa pa àwọn èèyàn burúkú ìgbà yẹn run. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1-3) Bíbélì yẹn wá fi kún un pé “ní ọjọ́ wọnnì,” àwọn áńgẹ́lì tó gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀ ń bá a lọ láti “ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin ènìyàn” wọ́n sì bí àwọn “alágbára ńlá tí wọ́n wà ní ìgbà láéláé,” ìyẹn àwọn Néfílímù.—Jẹ́nẹ́sísì 6:4.
a Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “Néfílímù” ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Àwọn Abiniṣubú.” Ìwé Wilson’s Old Testament Word Studies sọ pé ọ̀rọ̀ yẹn ń tọ́ka sí àwọn “tó máa ń fipá kọlu àwọn míì, tó máa ń gba tọwọ́ wọn, tó sì máa ń bì wọ́n ṣubú.”
b Àwọn amí ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn nínú Númérì 13:33 rí àwọn èèyàn tó fìrìgbọ̀n. Èyí mú kí wọ́n rántí àwọn Néfílímù tó ti kú láìmọye ọdún sẹ́yìn.—Jẹ́nẹ́sísì 7:21-23.