Ṣé Ó Dáa Téèyàn Bá Nífẹ̀ẹ́ Ara Rẹ̀?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ kéèyàn nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ dé ìwọ̀n àyè kan. Èyí túmọ̀ sí pé kéèyàn mọyì ara rẹ̀, kó máa tọ́jú ara rẹ̀, kó sì pọ́n ara ẹ̀ lé. (Mátíù 10:31) Dípò téèyàn fi máa jẹ́ onímọ̀ tara ẹni nìkan, ohun tí Bíbélì sọ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa.
Ìfẹ́ ta ló yẹ kó gbawájú láyé wa?
Ìfẹ́ Ọlọ́run ló yẹ kó gbawájú lọ́kàn wa. Bíbélì jẹ́ ká mọ òfin tó ga jù lọ, ó ní: ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ.’—Máàkù 12:28-30; Diutarónómì 6:5.
Òfin kejì tó ga jùlọ ni pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”—Máàkù 12:31; Léfítíkù 19:18.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ibì kankan tí Bíbélì ti pàṣẹ pé kẹ́nì kan nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, síbẹ̀ òfin tó sọ pé: “Nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ” jẹ́ ká rí i pé déwọ̀n àyè kan, ó bọ́gbọ́n mu tá a bá nífẹ̀ẹ́ ara wa, tá a sì mọyì ara wa. Bó ṣe yẹ kó rí nìyẹn.
Ta ni Jésù kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́?
Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa bá a ṣe lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àwọn aládùúgbò wa àti ara wa láì jẹ́ pé à fi ìkan pa òmíì lára, ó sì sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ òun.—Jòhánù 13:34, 35.
Ìfẹ́ Jèhófà ló gbawájú láyé rẹ̀, iṣẹ́ Jèhófà ló sì fi gbogbo ayé rẹ̀ ṣe. Abájọ tó fi sọ pé: “Kí ayé lè mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ Baba, àní gẹ́gẹ́ bí Baba ti fi àṣẹ fún mi láti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni mo ń ṣe.”—Jòhánù 14:31.
Jésù fi hàn pé òun fẹ́ràn àwọn aládùúgbò òun nígbà tó bójú tó àìní wọn, kódà ó tiẹ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wọn.—Mátíù 20:28.
Ó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ nígbà tó wáyè sinmi, tó jẹun tó sì ní ìfararora pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ àtàwọn tó fẹ́ di ọmọlẹ́yìn rẹ̀.—Máàkù 6:31, 32; Lúùkù 5:29; Jòhánù 2:1, 2; 12:2.
Tó o bá fi ire àwọn míì ṣáájú tìẹ, ṣé ìyẹn túmọ̀ sí pé o ò ní láyọ̀ tàbí pé o ò mọyì ara ẹ?
Bẹ́ẹ̀ kọ́, torí pé Ọlọ́run dá wa láwòrán ara rẹ̀, ànímọ́ Ọlọ́run tó sì gbawájú jù lọ ni ìfẹ́ tí kò mọ̀ tara ẹ̀ nìkan. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27; 1 Jòhánù 4:8) Èyí túmọ̀ sí pé Ọlọ́run dá wa lọ́nà tá a lè fi máa fi ìfẹ́ hàn sáwọn míì. Òótọ́ ni pé a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wa, àmọ́ a máa láyọ̀ gan-an tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tá a sì ń ṣe dáadáa sáwọn míì. Bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ ló rí, ó ní: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àwọn máa láyọ̀ táwọn bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn ju àwọn míì. Lójú wọn, “nífẹ̀ẹ́ ara rẹ” ti rọ́pò “nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ.” Àmọ́, ìwádìí òde òní ti jẹ́ ká rí i pé èèyàn máa láyọ̀, ìlera rẹ̀ sì máa sunwọ̀n sí i tó bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì pé: “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.”—1 Kọ́ríńtì 10:24.