Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Jọ́sìn Àwọn Ère?
Ohun tí Bíbélì sọ
Rárá, a kò gbọ́dọ̀ jọ́sìn àwọn ère. Nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia ń sọ̀rọ̀ nípa òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ó sọ pé: “Láti inú onírúurú àkọsílẹ̀ Bíbélì ni ó ti ṣe kedere pé ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ kò ní àwọn ère ninu.” Gbé àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí yẹ̀wò:
“Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ tàbí ìrísí tí ó dà bí ohunkóhun tí ó wà nínú ọ̀run lókè tàbí tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀ tàbí tí ó wà nínú omi lábẹ́ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn tàbí kí a sún ọ láti sìn wọ́n, nítorí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.” (Ẹ́kísódù 20:4, 5) Torí pé “ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe” ni Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa, kò ní tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa tí a bà ń jọ́sìn àwọn nǹkan bí ère, àwòrán, òòṣà tàbí àwọn àmì kan.
“Èmi kì yóò sì fi ògo mi fún . . . àwọn ère fífín.” (Aísáyà 42:8) Ọlọ́run kò fẹ́ ká jọ́sìn òun nípasẹ̀ àwọn ère. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan fi ère ọmọ màlúù jọ́sìn Ọlọ́run, Ọlọ́run sọ fún wọn pé wọ́n ti “gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun.”—Ẹ́kísódù 32:7-9.
“Kò yẹ kí a lérò pé Olù-Wà Ọ̀run rí bí wúrà tàbí fàdákà tàbí òkúta, bí ohun tí a gbẹ́ lére nípasẹ̀ ọnà àti ìdọ́gbọ́nhùmọ̀ ènìyàn.” (Ìṣe 17:29) Àwọn abọ̀rìṣà máa ń lo àwọn igi tí wọ́n “gbẹ́ lére nípasẹ̀ ọnà àti ìdọ́gbọ́nhùmọ̀ ènìyàn.” Àmọ́, àwọn Kristẹni yàtọ̀ sí wọn, Bíbélì sọ pé àwọn Kristẹni máa ‘rìn nípa ìgbàgbọ́ kì í ṣe nípa ohun tí wọ́n rí.’—2 Kọ́ríńtì 5:7.
“Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.” (1 Jòhánù 5:21) Ó hàn nínú àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti èyí tó pa fún àwọn Kristẹni pé léraléra ni Bíbélì ń tú àṣírí ẹ̀kọ́ irọ́ náà pé Ọlọ́run ló fọwọ́ sí lílo ère àti àwòrán nínú ìjọsìn.