Ohun Méjì Wo Ni Kì Í Jẹ́ Kí Ọlọ́run Dáhùn Àwọn Àdúrà Kàn?
Ohun tí Bíbélì sọ
Àwọn àdúrà kan wà tí Ọlọ́run kì í dáhùn. Wo ohun méjì tó lè mú kí ẹnì kan gbàdúrà kí Ọlọ́run má sì gbọ́.
1. Tí àdúrà yẹn bá ta ko ìfẹ́ Ọlọ́run
Ọlọ́run kì í gbọ́ àwọn àdúrà tó bá ta ko ìfẹ́ rẹ̀ tàbí àwọn ohun tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run fẹ́ ká máa ṣe. (1 Jòhánù 5:14) Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé ká má ṣe jẹ́ oníwọra. Ńṣe ni tẹ́tẹ́ títa máa ń sọni di oníwọra. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Torí náà, Ọlọ́run kò ní dá ọ lóhùn tó o bá ń gbàdúrà pé kó jẹ́ kó o jẹ tẹ́tẹ́. Ọlọ́run kì í ṣe àǹjọ̀nnú téèyàn kàn lè máa pè láti máa ṣe gbogbo ohun tó bá ṣáà ti wù ú. Ó sì yẹ kéyìí máa dùn mọ́ ẹ nínú. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ńṣe lò bá máa bẹ̀rù pé bóyá ẹnì kan máa rán Ọlọ́run kó wá bá ọ jà.—Jákọ́bù 4:3.
2. Tẹ́ni tó ń gbàdúrà bá jẹ́ aṣetinú-ẹni
Ọlọ́run kì í gbọ́ àdúrà àwọn tó bá ti pinnu láti máa ṣe ohun tó ń dun Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ fún àwọn kan tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́rùn àmọ́ tó jẹ́ pé ìfẹ́ inú ara wọn ni wọ́n ń ṣe pé: “Bí ẹ tilẹ̀ gba àdúrà púpọ̀, èmi kò ní fetí sílẹ̀; àní ọwọ́ yín kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.” (Aísáyà 1:15) Àmọ́ ká ní wọ́n ti yí pa dà ni tí wọ́n sì “mú àwọn ọ̀ràn [wọn] tọ́” lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ì bá gbọ́ wọn nígbà tí wọ́n gbàdúrà sí i.—Aísáyà 1:18.