Kí Là Ń Pè Ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ọ̀rọ̀ náà, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” sábà máa ń túmọ̀ sí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ tàbí àkójọ irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. (Lúùkù 11:28) Láwọn ibì kan nínú Bíbélì, orúkọ oyè ẹnì kan ni “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” tàbí “Ọ̀rọ̀ náà” jẹ́.—Ìṣípayá 19:13; Jòhánù 1:14.
Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ. Àwọn wòlíì sábà máa ń sọ pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni iṣẹ́ táwọn wá jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jeremáyà fẹ́ jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an, ohun tó fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ọ̀rọ̀ Jèhófà . . . bẹ̀rẹ̀ sí tọ̀ mí wá.” (Jeremáyà 1:4, 11, 13; 2:1) Bákan náà, kí wòlíì Sámúẹ́lì tó sọ fún Sọ́ọ̀lù pé Ọlọ́run ti yàn án ṣe ọba, ohun tí wòlíì náà kọ́kọ́ sọ ni pé: “Dúró jẹ́ẹ́ nísinsìnyí, kí n lè jẹ́ kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”—1 Sámúẹ́lì 9:27.
Orúkọ oyè. Bíbélì tún pe Jésù Kristi ní “Ọ̀rọ̀ náà” nígbà tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí lọ́run àti nígbà tó wá sáyé bí èèyàn. Wo àwọn ohun kan tó mú ká gbà bẹ́ẹ̀:
Ọ̀rọ̀ náà ti wà ṣáájú gbogbo ìṣẹ̀dá yòókù. “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni Ọ̀rọ̀ náà wà . . . Ẹni yìí ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ wà pẹ̀lú Ọlọ́run.” (Jòhánù 1:1, 2) Jésù ni “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá . . . Ó wà ṣáájú gbogbo ohun mìíràn.”—Kólósè 1:13-15, 17.
Ọ̀rọ̀ náà di èèyàn, ó sì wá sáyé. “Ọ̀rọ̀ náà di ẹlẹ́ran ara, ó sì gbé láàárín wa.” (Jòhánù 1:14) Kristi Jésù “sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀, ó sì wá wà ní ìrí ènìyàn.”—Fílípì 2:5-7.
Ọmọ Ọlọ́run ni Ọ̀rọ̀ náà. Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Jòhánù ti sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí, pé “Ọ̀rọ̀ náà di ẹlẹ́ran ara,” ó wá sọ pé: “A sì rí ògo rẹ̀, ògo kan irú èyí tí ó jẹ́ ti ọmọ bíbí kan ṣoṣo láti ọ̀dọ̀ baba kan.” (Jòhánù 1:14) Jòhánù tún sọ pé: “Jésù Kristi ni Ọmọ Ọlọ́run.”—1 Jòhánù 4:15.
Ọ̀rọ̀ náà dà bí Ọlọ́run. “Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ ọlọ́run kan,” tàbí “wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Jòhánù 1:1; Bíbélì An American Translation) Jésù ni “àgbéyọ ògo [Ọlọ́run] àti àwòrán náà gẹ́lẹ́ ti wíwà rẹ̀ gan-an.”—Hébérù 1:2, 3.
Ọba ni Ọ̀rọ̀ náà. Bíbélì sọ pé “adé dáyádémà púpọ̀” wà lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ìṣípayá 19:12, 13) Ó tún pe Ọ̀rọ̀ náà ní “Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa.” (Ìṣípayá 19:16) Jésù ni “Ọba àwọn tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti Olúwa àwọn tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí olúwa.”—1 Tímótì 6:14, 15.
Ọ̀rọ̀ náà máa ń gbẹnu sọ fún Ọlọ́run. Ó ṣe kedere pé orúkọ oyè yìí, ìyẹn “Ọ̀rọ̀ náà” ń fi hàn pé Ọlọ́run máa ń fi ìsọfúnni àti ìtọ́ni rán ẹni tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀. Jésù sọ pé Ọlọ́run ló rán òun ní ohun tóun ń sọ, ó ní: “Baba fúnra rẹ̀ tí ó rán mi ti fún mi ní àṣẹ kan ní ti ohun tí èmi yóò wí àti ohun tí èmi yóò sọ. . . . Nítorí náà, àwọn ohun tí mo ń sọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti sọ wọ́n fún mi, bẹ́ẹ̀ ni mo ń sọ wọ́n.”—Jòhánù 12:49, 50.