Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mó Bá Ń Ronú Àtipa Ara Mi?

Ṣé Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mó Bá Ń Ronú Àtipa Ara Mi?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bẹ́ẹ̀ ni! Bíbélì wá látọ̀dọ̀ “Ọlọ́run tó ń tu àwọn tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá nínú.” (2 Kọ́ríńtì 7:6) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé tó dá lórí ìlera ọpọlọ, ó ti ran ọ̀pọ̀ àwọn tó ronú àtipa ara wọn lọ́wọ́. Àwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì wúlò, wọ́n sì lè ran ìwọ náà lọ́wọ́.

 Àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò wo ló wà nínú Bíbélì?

  • Sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún ẹlòmíì.

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”​—Òwe 17:17.

     Ohun tó túmọ̀ sí: A nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn míì tá a bá ní ìdààmú ọkàn.

     Ńṣe ni ìdààmú ọkàn rẹ á máa pọ̀ sí i tí o kò bá sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún ẹlòmíì. Àmọ́ tí o bá sọ ọ́, ìyẹn lè mú kí ọ̀rọ̀ náà fúyẹ́, kó o sì lè fojú tó tọ́ wò ó.

     Ohun tó o lè ṣe: Bá mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ kan tó o fọkàn tán sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lónìí. a O tún lè kọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ sílẹ̀.

  • Lọ rí dókítà.

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, àmọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn nílò rẹ̀.”​—Mátíù 9:12.

     Ohun tó túmọ̀ sí: Tá a bá ń ṣàìsàn, ó yẹ ká lọ bá àwọn dókítà kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́.

     Ohun tó sábà máa ń mú kéèyàn máa ronú àtipara rẹ̀ ni ìsoríkọ́ tàbí àrùn ọpọlọ. Kì í ṣe ohun ìtìjú rárá, torí èèyàn kì í tijú tára rẹ̀ ò bá yá. Ìsoríkọ́ àti àrùn ọpọlọ sì ṣe é wò sàn.

     Ohun tó o lè ṣe: Lọ rí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ dókítà láìjáfara.

  • Rántí pé ọ̀rọ̀ rẹ jẹ Ọlọ́run lógún.

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Ẹyọ owó méjì tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́ márùn-ún, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀, Ọlọ́run ò gbàgbé ìkankan nínú wọn. . . . Ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.”​—Lúùkù 12:6, 7.

     Ohun tó túmọ̀ sí: O ṣeyebíye lójú Ọlọ́run.

     Ó lè ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ ohun tó ò ń bá yí. Kódà táyé bá sú ẹ, rántí pé ọ̀rọ̀ rẹ jẹ Ọlọ́run lógún. Sáàmù 51:17 sọ pé: “Ìwọ Ọlọ́run, o kò ní pa ọkàn tó gbọgbẹ́ tó sì ní ìdààmú tì.” Ọlọ́run fẹ́ràn ẹ, ó sì fẹ́ kó o wà láàyè.

     Ohun tó o lè ṣe: Gbé àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run fẹ́ràn ẹ yẹ̀ wò nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, wo orí 24 nínú ìwé Sún mọ́ Jèhófà.

  • Máa gbàdúrà sí Ọlọ́run.

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ [Ọlọ́run], torí ó ń bójú tó yín.”​—1 Pétérù 5:7.

     Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run fẹ́ kó o sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún òun láìfi ohunkóhun pa mọ́.

     Ọlọ́run lè fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀, kó sì fún ẹ lókun láti fara dà á. (Fílípì 4:6, 7, 13) Ọ̀nà yìí ni Ọlọ́run ń gbà ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ń ké pè é tọkàntọkàn.​—Sáàmù 55:22.

     Ohun tó o lè ṣe: Gbàdúrà sí Ọlọ́run lónìí. Dárúkọ rẹ̀, Jèhófà, nínú àdúrà rẹ, kó o sì sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún un. (Sáàmù 83:18) Bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara dà á.

  • Ronú lórí ohun tí Bíbélì sọ pé ká máa retí lọ́jọ́ ọ̀la.

     Ohun tí Bíbélì sọ: “A ní ìrètí yìí bí ìdákọ̀ró fún ẹ̀mí wa, ó dájú, ó fìdí múlẹ̀.”​—Hébérù 6:19, àlàyé ìsàlẹ̀.

     Ohun tó túmọ̀ sí: Bó ṣe ń ṣe ẹ́ lè má dúró sójú kan bí ìgbà tí ìgbì òkun bá ń bi ọkọ̀ sókè sódò, síbẹ̀ ìrètí tó wà nínú Bíbelì lè gbé ẹ ró.

     Ìrètí yìí kì í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ, àmọ́ ó dá lórí àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe láti fòpin sí gbogbo ohun tó ń fa ìrora.​—Ìfihàn 21:4.

     Ohun tó o lè ṣe: Kẹ́kòọ́ sí i nípa àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì ní ẹ̀kọ́ 5 nínú ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!

  • Máa ṣe ohun tó gbádùn mọ́ ẹ.

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Ọkàn tó ń yọ̀ jẹ́ oògùn tó dára fún ara.”​—Òwe 17:22.

     Ohun tó túmọ̀ sí: Ọkàn wa lè balẹ̀, kí ọpọlọ wa sì jí pépé tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan tó máa fún wa láyọ̀.

     Ohun tó o lè ṣe: Máa ṣe ohun tó máa ń gbádùn mọ́ ẹ. Bí àpẹẹrẹ, máa gbọ́ orin tó ń dáni lára yá, ka nǹkan tó ń fúnni níṣìírí tàbí kó o wá eré ọwọ́ dilẹ̀ kan ṣe. Tó o bá ń ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, ayọ̀ rẹ á máa pọ̀ sí i bó ti wù kóhun tó o ṣe kéré tó.​—Ìṣe 20:35.

  • Tọ́jú ara rẹ.

     Ohun tí Bíbélì sọ: ‘Àǹfààní wà nínú eré ìmárale.’​—1 Tímótì 4:8.

     Ohun tó túmọ̀ sí: Tá a bá ń ṣeré ìmárale, tá à ń sùn dáadáa, tá a sì ń jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore, á ṣe wá láǹfààní.

     Ohun tó o lè ṣe: O lè rìn kánmọ́kánmọ́ fún bí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún.

  • Rántí pé bónìí ṣe rí ọ̀la lè má rí bẹ́ẹ̀.

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Ẹ ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí yín lọ́la.”​—Jémíìsì 4:14.

     Ohun tó túmọ̀ sí: Ìṣòro tó o rò pé kò sí ọ̀nà àbáyọ rẹ̀ lè jẹ́ fún ìgbà díẹ̀.

     Bónìí tiẹ̀ korò, ọ̀la ń bọ̀ wá dára. Torí náà, máa fara dà á. (2 Kọ́ríńtì 4:8) Ìdààmú ọkàn rẹ lè lọ tó bá yá, àmọ́ ẹ̀pa ò ní bóró mọ́ tó o bá pa ara ẹ.

     Ohun tó o lè ṣe: Kà nípa àwọn tí Bíbélì sọ pé wọ́n ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn débi tí wọ́n fi rò ó pé ó sàn káwọn kú, àmọ́ tí ayé wọn wá dáa ju bí wọ́n ṣe rò lọ. Wo àpẹẹrẹ díẹ̀.

 Ṣé Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ní ayé ti sú àwọn?

 Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó sọ pé, “Ó sàn kí n kú.” Dípò kí Ọlọ́run bá wọn wí, ṣe ló ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó lè ran ìwọ náà lọ́wọ́.

Èlíjà

  •  Tá ni Èlíjà? Wòlíì tó nígboyà ni Èlíjà. Àmọ́ òun náà rẹ̀wẹ̀sì láwọn ìgbà kan. Jémíìsì 5:17 sọ pé “Ẹni tó máa ń mọ nǹkan lára bíi tiwa ni Èlíjà.”

  •  Kí nìdí tó fi fẹ́ kú? Ìgbà kan wà tí Èlíjà rò pé òun dá nìkan wà, tí ẹ̀rù bà á, tó sì rò pé òun ò já mọ́ nǹkan kan. Ó bẹ̀bẹ̀ pé: “Jèhófà, gba ẹ̀mí mi.”​—1 Àwọn Ọba 19:4.

  •  Kí ló ràn án lọ́wọ́? Èlíjà sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ fún Ọlọ́run. “Báwo ni Ọlọ́run ṣe fún un níṣìírí? Ọlọ́run fi hàn án pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ òun lọ́kàn, ó sì jẹ́ kó mọ bí òun ṣe lágbára tó. Ó fi dá Èlíjà lójú pé ó ṣì wúlò, ó sì fún un ní olùrànlọ́wọ́ tó dáńgájíá.

  •  Kà nípa Èlíjà: 1 Àwọn Ọba 19:2-18.

Jóòbù

  •  Ta ni Jóòbù? Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tó ní ìdílé ńlá tó sì tún fòótọ́ ọkàn sin Ọlọ́run ni Jóòbù.

  •  Kí nìdí tó fi fẹ́ kú? Nǹkan dojú rú fún Jóòbù láìròtẹ́lẹ́. Ó pàdánù gbogbo ohun tó ní. Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan pa gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀. Àìsàn tó ń roni lára ṣe é. Paríparí ẹ̀, wọ́n fẹ̀sùn èké kàn án pé àfọwọ́fà rẹ̀ ni àwọn ìṣòro tó dé bá a. Ni Jóòbù bá sọ pé: “Mo kórìíra ayé mi gidigidi; mi ò fẹ́ wà láàyè mọ́.”​—Jóòbù 7:16.

  •  Kí ló ràn án lọ́wọ́? Jóòbù gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó sì bá àwọn míì sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro tó ní. (Jóòbù 10:1-3) Ọ̀rẹ́ tòótọ́ kan tó ń jẹ́ Élíhù fún un níṣìírí, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti fojú tó tọ́ wo ìṣòro rẹ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Jóòbù gba ìmọ̀ràn àti ìrànlọ́wọ́ tí Ọlórun fún un.

  •  Kà nípa Jóòbù: Jóòbù 1:1-3, 13-22; 2:7; 3:1-13; 36:1-7; 38:1-3; 42:1, 2, 10-13.

Mósè

  •  Ta ni Mósè? Mósè jẹ́ aṣáájú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́, ó sì jẹ́ wòlíì olóòótọ́.

  •  Kí nìdí tó fi fẹ́ kú? Iṣẹ́ tó wọ Mósè lọ́rùn àti bí wọ́n ṣe ń ṣàríwísí rẹ̀ léraléra mú káyé sú u. Ló bá sọ fún Ọlórun pé: “Jọ̀ọ́ kúkú pa mí báyìí.”​—Nọ́ńbà 11:11, 15.

  •  Kí ló ràn án lọ́wọ́? Mósè sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ fún Ọlọ́run. Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́, ó mú kí nǹkan rọrùn fún un.

  •  Kà nípa Mósè: Nọ́ńbà 11:4-6, 10-17.

a Tó bá ń ṣe ẹ́ ní gbogbo ìgbà bíi pé kó o pá ara rẹ tí àwọn tó o fọkàn tán kò sì sí nítòsí, pe fóònù àwọn tó ń rí sí ọ̀rọ̀ pàjáwìrì.