Ṣé Jésù Ṣègbéyàwó? Ṣé Jésù Ní Àwọn Àbúrò?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì jẹ́ kó yé wa pé Jésù kò fẹ́ ìyàwó, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sọ ní pàtó pé ó ṣègbéyàwó tàbí kò ṣe. a Gbé àwọn ẹ̀rí yìí yẹ̀wò:
Bíbélì sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìdílé tí Jésù dàgbà sí àti àwọn obìnrin tó tẹ̀ lé Jésù nígbà tó ń wàásù àti àwọn tó dúró tì í nígbà tí wọ́n dájọ́ ikú fún un, síbẹ̀ Bíbélì kò sọ pé ó fẹ ìyàwó. (Mátíù 12:46, 47; Máàkù 3:31, 32; 15:40; Lúùkù 8:2, 3, 19, 20; Jòhánù 19:25) Ìdí pàtàkì tí Bíbélì kò fi sọ̀rọ̀ nípa ìyàwó Jésù ni pé kò fẹ́yàwó rárá.
Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó yàn láti má ṣe ní ọkọ tàbí aya torí kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Ọlọ́run, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kí ẹni tí ó bá lè wá àyè fún [wíwà láì ní ọkọ tàbí aya] wá àyè fún un.” (Mátíù 19:10-12) Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn tó yàn láti má ṣe lọ́kọ tàbí láya torí kí wọ́n lè fi gbogbo ìgbésí ayé wọn sin Ọlọ́run ní kíkún.—Jòhánù 13:15; 1 Kọ́ríńtì 7:32-38.
Kí Jésù tó kú, ó ṣètò ẹnì kan tí yóò máa tọ́jú ìyá rẹ̀. (Jòhánù 19:25-27) Ká sọ pé Jésù fẹ́ ìyàwó ni tàbí tó bá jẹ́ pé ó ní àwọn ọmọ, ó máa ṣètò bí àwọn tó jẹ́ ara ìdílé rẹ̀ ṣe máa rí àbójútó bákan náà.
Bíbélì fi Jésù ṣe àpẹẹrẹ tó yẹ kí àwọn ọkọ máa tẹ̀ lé, àmọ́ kò sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe bá ìyàwó tó fẹ́ sílé lò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Éfésù 5:25) Tó bá jẹ́ pé Jésù fẹ́yàwó lóòótọ́ nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ǹjẹ́ ẹsẹ Bíbélì yẹn kò ní sọ̀rọ̀ nípa àpẹẹrẹ pípé ti Jésù fi lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkọ tó níyàwó lọ́ọ̀dẹ̀?
Ǹjẹ́ Jésù ní àwọn àbúrò?
Bẹ́ẹ̀ ni, ó kéré tan Jésù ní àwọn àbúrò mẹ́fà, àwọn ni Jákọ́bù, Jósẹ́fù, Símónì àti Júdásì àti àwọn obìnrin méjì, ó kéré tan. (Mátíù 13:54-56; Máàkù 6:3) Màríà, ìyá Jésù ló bí àwọn àbúrò Jésù tá a dárúkọ wọn yìí, Jósẹ́fù, ọkọ rẹ̀ ló sì bí wọn fún. (Mátíù 1:25) Bíbélì pe Jésù ní “àkọ́bí” Màríà, tó fi hàn pé ó bí àwọn ọmọ míì lẹ́yìn náà.—Lúùkù 2:7.
Èrò tí kò tọ̀nà tí àwọn kan ní nípa àwọn àbúrò Jésù
Àwọn ìtumọ̀ tó yàtọ̀ síra ni àwọn èèyàn kan ti fún ọ̀rọ̀ náà “arákùnrin” torí kí wọ́n lè fi ti èrò wọn lẹ́yìn pé wúńdíá ni Màríà títí tó fi kú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn kan gbà pé àwọn ọmọ tí Jósẹ́fù ti bí nígbà kan ni àwọn àbúrò Jésù ti ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ. Ṣùgbọ́n, Bíbélì fi hàn pé Jésù ló lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti jogún ipò ọba tí Ọlọ́run ṣèlérí fún Dáfídì. (2 Sámúẹ́lì 7:12, 13; Lúùkù 1:32) Tó bá jẹ́ pé Jósẹ́fù bí àwọn ọmọ tó dàgbà ju Jésù lọ, ẹni tó dàgbà jù nínú wọn ló máa lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti jogún ipò ọba tó tọ́ sí Jósẹ́fù.
Ṣe àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tàbí àwọn arákùnrin Jésù nípa tẹ̀mí ni ọ̀rọ̀ náà ń tọ́ka sí? Èrò yìí ta ko ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, torí Bíbélì sọ pé ìgbà kan wa tí ‘àwọn arákùnrin rẹ̀ kò lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.’ (Jòhánù 7:5) Bíbélì máa ń fi ìyàtọ̀ hàn láàárín àwọn arákùnrin Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.—Jòhánù 2:12.
Àwọn kan tún sọ pé ìbátan làwọn ọkùnrin wọ̀nyí jẹ́ sí Jésù. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún “arákùnrin,” “ìbátan” àti “mọ̀lẹ́bí” nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì yàtọ̀ síra. (Lúùkù 21:16; Kólósè 4:10) Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì gbà pé ọmọ ìyá kan náà ni àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn yìí. Bí àpẹẹrẹ, ìwé The Expositor’s Bible Commentary ṣàlàyé pé: “Ọ̀nà tó nítumọ̀ jù lọ téèyàn lè gbà lóye ọ̀rọ̀ náà ‘àwọn arákùnrin’ . . . ni pé àwọn ọmọkùnrin tí Màríà bí fún Jósẹ́fù ni wọ́n pè bẹ́ẹ̀, tọ́ràn bá sì rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé àwọn àbúrò Jésù tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ ìyá kan náà là ń sọ̀rọ̀ nípa wọn.” b
a Bíbélì pe Kristi ni ọkọ ìyàwó, àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ ṣáájú àti lẹ́yìn àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí fi hàn pé ńṣe ló ń ṣàpẹẹrẹ ohun kan.—Jòhánù 3:28, 29; 2 Kọ́ríńtì 11:2.
b Tún wo ìwé náà, The Gospel According to St. Mark, Àtúnṣe Kejì, láti ọwọ́ Vincent Taylor, ojú ìwé 249 àti ìwé náà, A Marginal Jew—Rethinking the Historical Jesus, láti ọwọ́ John P. Meier, Apá Kìíní, ojú ìwé 331 àti 332.