Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Pèrò Dà?

Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Pèrò Dà?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bẹ́ẹ̀ ni, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀, ní ti pé ó máa ń yí ohun tó ní lọ́kàn pa dà nígbà tí àwọn èèyàn bá yíwà pa dà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọlọ́run rán wòlíì kan sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ pé kó lọ jíṣẹ́ fún wọn pé òun máa dá wọn lẹ́jọ́, ó sọ pé: “Bóyá wọn yóò fetí sílẹ̀ kí olúkúlùkù wọn sì padà ní ọ̀nà búburú rẹ̀, dájúdájú, èmi yóò sì pèrò dà ní ti ìyọnu àjálù tí mo ń rò láti mú ṣẹ ní kíkún sórí wọn nítorí búburú ìbálò wọn.”​—Jeremáyà 26:3.

 Ọ̀pọ̀ ìtúmọ̀ Bíbélì ló túmọ̀ ẹsẹ yìí bíi pé Ọlọ́run máa “ronú pìwà dà” nípa ìyà tó fẹ́ fi jẹ wọ́n, èyí tó lè túmọ̀ sí pé àṣìṣe ló ṣe tẹ́lẹ̀. Àmọ́, ọ̀rọ̀ èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ tó wà nínú ẹsẹ yìí lè túmọ̀ sí “pa èrò dà tàbí yí ohun tó o ní lọ́kàn pa dà.” Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé: “Ọlọ́run máa ń yí ìdájọ́ rẹ̀ pa dà téèyàn bá ti yíwà pa dà.”

 Ọlọ́run yí èrò rẹ̀ pa dà lóòótọ́, àmọ́ ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé ó gbọ́dọ̀ yí i pa dà. Ṣàyẹ̀wò àwọn ohun kan tó ṣẹlẹ̀, àmọ́ tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run pèrò dà nípa rẹ̀:

  •   Ọlọ́run ò jẹ́ kí Bálákì yí Òun lọ́kàn pa dà kó sì gégùn-ún fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì.​—Númérì 23:18-​20.

  •   Gbàrà tí Ọba Sọ́ọ̀lù ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì ti di aláìgbọràn, Ọlọ́run pinnu pé òun máa gba ìjọba lọ́wọ́ rẹ̀, kò sì pèrò dà nípa ohun tó fẹ́ ṣe yẹn.​—1 Sámúẹ́lì 15:28, 29.

  •   Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa sọ Ọmọ òun di àlùfáà títí láé, yóò sì mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ọlọ́run ò ní pèrò dà.​—Sáàmù 110:4.

Ṣebí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run kì í yí pa dà?

 Bẹ́ẹ̀ ni, nínú Bíbélì, Ọlọ́run sọ pé: “Èmi ni Jèhófà; èmi kò yí padà.” (Málákì 3:6) Bákan náà, Bíbélì sọ pé ‘kò sí àyídà ìyípo òjìji’ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Jákọ́bù 1:17) Àmọ́ èyí ò ta ko ohun tí Bíbélì sọ nígbà tó ní Ọlọ́run máa ń pèrò dà. Ọlọ́run kì í yí pa dà ní ti pé kì í yí irú ẹni tó jẹ́ pa dà, ìlànà ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo rẹ̀ kì í sì í yí pa dà. (Diutarónómì 32:4; 1 Jòhánù 4:8) Síbẹ̀, ó máa ń yí ìtọ́ni tó fún àwọn èèyàn pa dà nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run fún Ọba Dáfídì ní ìtọ́ni nígbà tó fẹ́ ja ogun kan, àmọ́ ìtọ́ni tó yàtọ̀ ló fún un nígbà tó fẹ́ ja ogun míì lẹ́yìn ìyẹn, méjèèjì ló sì ṣàṣeyọrí.​—2 Sámúẹ́lì 5:18-​25.

Ǹjẹ́ Ọlọ́run kábàámọ̀ pé òun dá èèyàn?

 Rárá o, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dùn ún pé ọ̀pọ̀ èèyàn kọ òun, tí wọ́n sì pa òun ti. Bíbélì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú Ìkún Omi ìgbà ayé Nóà, ó ní: “Jèhófà sì kẹ́dùn pé òun dá àwọn ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé, ó sì dùn ún ní ọkàn-àyà rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:6) Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, ọ̀rọ̀ náà “kẹ́dùn” wá látinú ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tó lè túmọ̀ sí “yí èrò pa dà.” Ọlọ́run yí ohun tó ní lọ́kàn pa dà nípa ọ̀pọ̀ èèyàn tó gbé ayé ṣáájú Ìkún Omi torí pé wọ́n ti di èèyàn burúkú. (Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 11) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dùn ún pé wọ́n yàn láti ṣe ohun tí ò dáa, kò yíwà pa dà sí gbogbo aráyé. Kódà, kò jẹ́ kí Ìkún Omi pa ìran èèyàn run torí ó dá Nóà àti ìdílé rẹ̀ sí.​—Jẹ́nẹ́sísì 8:21; 2 Pétérù 2:5, 9.