Ṣé Wọ́n Ti Yí Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì Pa Dà?
Rárá o. Tá a bá fi àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ wéra, ó jẹ́ ká rí i pé àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì ò yí pa dà bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti ń ṣe àdàkọ rẹ̀ sórí àwọn nǹkan ìkọ̀wé tó lè bà jẹ́.
Ṣó túmọ̀ sí pé àwọn tó da Bíbélì kọ ò ṣàṣìṣe rárá ni?
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì làwọn èèyàn ti wá rí. Ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ wà nínú àwọn kan, tó fi hàn pé àwọn tó dà á kọ ṣàṣìṣe nígbà tí wọ́n ń kọ ọ́. Ìyàtọ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ló pọ̀ jù, àwọn ìyàtọ̀ yìí ò sì yí ìtumọ̀ ohun tí Bíbélì sọ pa dà. Àmọ́, a ti rí àwọn ibi mélòó kan tó yàtọ̀ gan-an, ó sì jọ pé ṣe làwọn tó dà á kọ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn yẹn fẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ yí ohun tí Bíbélì sọ pa dà láwọn ibì kan. Wo àpẹẹrẹ méjì yìí:
Ní 1 Jòhánù 5:7, ohun tó wà nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan tó ti pẹ́ ni pé: “ní ọ̀run, Baba, Ọ̀rọ̀ náà àti Ẹ̀mí Mímọ́: àwọn mẹ́ta yìí sì jẹ́ ọ̀kan.” Àmọ́ àwọn ìwé àfọwọ́kọ tó ṣeé fọkàn tán jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn ọ̀rọ̀ yìí ò sí nínú Bíbélì tí wọ́n kọ níbẹ̀rẹ̀. Àwọn èèyàn ló fìyẹn kún un. a Torí ẹ̀ ló ṣe jẹ́ pé a ò lè rí àwọn ọ̀rọ̀ yẹn nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì òde òní tó ṣeé fọkàn tán.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà ni orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gangan fara hàn nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì àtijọ́. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìtúmọ̀ Bíbélì ló ti fi àwọn orúkọ oyè bí “Olúwa” tàbí “Ọlọ́run” rọ́pò orúkọ Ọlọ́run.
Ṣe kì í ṣe pé ọ̀pọ̀ àṣìṣe míì ló ṣì wà táwọn èèyàn ò tíì rí?
Lásìkò wa yìí, ìwé àfọwọ́kọ táwọn èèyàn ti wá rí ti pọ̀ gan-an, ìyẹn sì ti mú kó rọrùn ju tàtẹ̀yìnwá lọ láti rí àṣìṣe tó bá wà. b Nígbà tá a fi àwọn ìwé yìí wéra, kí ló jẹ́ ká mọ̀ nípa bí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ṣe péye tó lónìí?
Ọ̀mọ̀wé William H. Green sọ̀rọ̀ lórí ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù (táwọn èèyàn ń pè ní “Májẹ̀mú Láéláé”), ó ní: “A lè fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ pé kò sí iṣẹ́ kankan tí wọ́n ṣe láyé àtijọ́ tó ṣì péye títí dòní bí èyí.”
Ọ̀mọ̀wé F. F. Bruce kọ̀wé nípa Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, tí wọ́n tún ń pè ní “Májẹ̀mú Tuntun,” ó ní: “Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló wà tó fi hàn pé àwọn ìwé inú Májẹ̀mú Tuntun lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ dáadáa ju ìwé tí ọ̀pọ̀ àwọn òǹkọ̀wé pàtàkì-pàtàkì kọ, bẹ́ẹ̀ sì rèé, kò sẹ́ni tó jẹ́ yẹ àwọn òǹkọ̀wé yìí lọ́wọ́ wò láti mọ̀ bóyá òótọ́ ni wọ́n kọ àbí bẹ́ẹ̀ kọ́.”
Sir Frederic Kenyon, tó jẹ́ aláṣẹ pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì sọ pé èèyàn “lè mú Bíbélì lódindi dání, kó sì sọ láìbẹ̀rù, láìkọ́ ọ lẹ́nu, pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jóòótọ́ lòun mú dání, ìwé tí ohun tó wa nínú ẹ̀ ò yí pa dà ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún tó ti wà láti ìrandíran.”
Àwọn ohun míì wo ló jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé ohun tó wà nínú Bíbélì ò yí pa dà?
Àwọn Júù àtàwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ adàwékọ ò ṣe àyípadà sí ìtàn àwọn àṣìṣe ńlá táwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì. c (Númérì 20:12; 2 Sámúẹ́lì 11:2-4; Gálátíà 2:11-14) Ohun kan náà ni wọ́n ṣe sí àwọn ìtàn tó dá lórí bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn Júù lẹ́bi torí wọ́n jẹ́ aláìgbọràn àti bí a ṣe túdìí àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́. (Hóséà 4:2; Málákì 2:8, 9; Mátíù 23:8, 9; 1 Jòhánù 5:21) Bí àwọn adàwékọ yìí ò ṣe yí àwọn àkọsílẹ̀ yìí pa dà fi hàn pé wọ́n ṣeé fọkàn tán, wọ́n sì ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ mímọ́ sí pàtàkì gan-an.
Ṣé kò bọ́gbọ́n mu lóòótọ́ pé, Ọlọ́run tó mí sí Bíbélì náà tún máa rí sí i pé ohun tó wà nínú ẹ̀ ò yí pa dà? d (Aísáyà 40:8; 1 Pétérù 1:24, 25) Ó ṣe tán, kì í ṣe àwọn èèyàn ìgbà àtijọ́ nìkan ni Ọlọ́run fẹ́ kí ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ṣe láǹfààní, ó tún fẹ́ kí àwa èèyàn lóde òní náà jàǹfààní látinú ẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 10:11) Kódà, “gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.”—Róòmù 15:4.
Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù táwọn èèyàn fọwọ́ dà kọ láì máa rò ó bóyá àwọn ọ̀rọ̀ àtijọ́ yẹn jóòótọ́ àbí kò jóòótọ́.—Lúùkù 4:16-21; Ìṣe 17:1-3.
a A ò lè rí àwọn ọ̀rọ̀ yìí nínú ìwé Codex Sinaiticus, Codex Alexandrinus, Vatican Manuscript 1209, Bíbélì Vulgate tí wọ́n kọ ní èdè Latin ìbẹ̀rẹ̀, Bíbélì Philoxenian-Harclean Syriac Version, àbí nínú Bíbélì Syriac Peshitta.
b Bí àpẹẹrẹ, ó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] ìwé àfọwọ́kọ lédè Gíríìkì, tí wọ́n ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun tàbí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, táwọn èèyàn ti wá rí.
c Bíbélì ò sọ pé àwọn èèyàn tó ń ṣojú fún Ọlọ́run ò lè ṣàṣìṣe. Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ ló sọ ọ́, ó ní: “Kò sí ènìyàn tí kì í dẹ́ṣẹ̀.”—1 Àwọn Ọba 8:46.
d Bíbélì sọ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ò pe gbogbo ohun tó fẹ́ kí wọ́n kọ sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, ó darí èrò àwọn èèyàn tó kọ ọ́.—2 Tímótì 3:16, 17; 2 Pétérù 1:21.