Ta Ni Jòhánù Arinibọmi?
Ohun tí Bíbélì sọ
Wòlíì Ọlọ́run ni Jòhánù Arinibọmi. (Lúùkù 1:76) Ó kù díẹ̀ kí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Ṣáájú Sànmánì Kristẹni parí ni wọ́n bíi, ó sì wà láàyè títí di ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni. Ọlọ́run fa iṣẹ́ lé e lọ́wọ́ láti múra àwọn èèyàn sílẹ̀ de Mèsáyà tàbí Kristi. Jòhánù ṣe iṣẹ́ náà nípa wíwàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn Júù bíi tiẹ̀ kó lè yí wọn lọ́kàn pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run.—Máàkù 1:1-4; Lúùkù 1:13, 16, 17.
Ìwàásù Jòhánù mú káwọn tó lọ́kàn rere mọ̀ pé Jésù ará Násárẹ́tì ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Mátíù 11:10) Jòhánù rọ àwọn tó gbọ́rọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí wọ́n sì ṣèrìbọmi láti fi hàn pé wọ́n ti ronú pìwà dà. (Lúùkù 3:3-6) Torí pé Jòhánù ri ọ̀pọ̀ èèyàn bọmi ni wọ́n ṣe ń pè é ní Arinibọmi tàbí Onírìbọmi. Ìrìbọmi tí Jòhánù ṣe fún Jésù ló ṣe pàtàkì jù lọ. a—Máàkù 1:9.
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa Jòhánù Arinibọmi?
Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ iṣẹ́ tó máa ṣe: Iṣẹ́ ìwàásù tí Jòhánù ṣe fi hàn pé òun ni ìránṣẹ́ Jèhófà tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀. (Málákì 3:1; Mátíù 3:1-3) Òun ni ẹni tí Bíbélì sọ pé ó máa “ṣètò àwọn èèyàn tí a ti múra sílẹ̀ fún Jèhofà,” ìyẹn ni pé ó máa múra àwọn Júù bíi tiẹ̀ sílẹ̀ kí wọ́n lè gba ọ̀rọ̀ Jésù Kristi, aṣojú pàtàkì tí Jèhófà Ọlọ́run rán.—Lúùkù 1:17.
Èrè tó máa rí gbà: Jésù sọ pé “kò tíì sí ẹni tó tóbi ju Jòhánù Arinibọmi lọ, àmọ́ ẹni kékeré nínú Ìjọba ọ̀run tóbi jù ú lọ.” (Mátíù 11:11) Yàtọ̀ sí pé Jòhánù jẹ́ wòlíì, òun tún ni “ìránṣẹ́” tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀, torí náà kò sí ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó gbé láyé ṣáájú rẹ̀ tá a lè sọ pé ó tóbi jù ú lọ. Jésù tún fi hàn nínú ọ̀rọ̀ tó sọ pé Jòhánù ò ní sí lára àwọn tó máa jogún Ìjọba Ọlọ́run lókè ọ̀run. b Wòlíì olóòótọ́ yìí ti kú kí Kristi tó ṣí àǹfààní àtilọ sọ́run sílẹ̀. (Hébérù 10:19, 20) Ṣùgbọ́n, Jòhánù á wà lára àwọn tó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé nínú Ìjọba Ọlọ́run, á sì gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè.—Sáàmù 37:29; Lúùkù 23:43.
Àwọn wo ni òbí Jòhánù Arinibọmi?
Àwọn tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Sekaráyà àti Èlísábẹ́tì ni òbí Jòhánù. Àlùfáà Júù ni Sekaráyà. Ọ̀nà ìyanu ni wọ́n gbà bí Jòhánù, torí pé ìyá rẹ̀ yàgàn, kò sì lè bímọ. Bákan náà, òun àti Sekaráyà ti “lọ́jọ́ lórí gan-an.”—Lúùkù 1:5-7, 13.
Ta ló fa ikú Jòhánù Arinibọmi?
Ọba Hẹ́rọ́dù Áńtípà ló ní kí wọ́n bẹ́ orí Jòhánù. Torí Hẹrodíà ìyàwó rẹ̀ ló ṣe ní kí wọ́n pa á. Hẹrodíà kórìíra Jòhánù torí pé ó sọ fún Hẹ́rọ́dù tó pera ẹ̀ ní Júù pé kò dáa bó ṣe fẹ́ Hẹrodíà torí pé ó lòdì sófin àwọn Júù.—Mátíù 14:1-12; Máàkù 6:16-19.
Ṣé orogún ni Jòhánù Arinibọmi àti Jésù?
Bíbélì ò sọ pé orogún ni Jésù àti Jòhánù. (Jòhánù 3:25-30) Kódà, Jòhánù sọ ní gbangba pé ojúṣe òun ni pé kóun múra àwọn èèyàn sílẹ̀ de Mèsáyà, kì í ṣe láti bá a díje. Jòhánù sọ pé: ‘Èmi wá, mò ń fi omi batisí ká lè fi í hàn kedere fún Ísírẹ́lì.’ Lẹ́yìn náà ló tún sọ pé: “Ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run.” (Jòhánù 1:26-34) Torí náà inú Jòhánù dùn gan-an láti gbọ́ bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ṣe yọrí sí rere.
a Jésù “kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.” (1 Pétérù 2:21, 22) Torí náà, kì í ṣe torí pé ó nílò ìrònúpìwàdà ló fi ṣèrìbọmi, bí kò ṣe kó bàa lè yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ara ẹ̀ náà sì ní bó ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ torí wa.—Hébérù 10:7-10.
b Wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Wo Ló Ń Lọ sí Ọ̀run?”