Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Sún Mọ́ Ọlọ́run? Ṣé Mo Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run Bí Mi Ò Bá Ṣe Ẹ̀sìn Kankan?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ohun tí Bíbélì sọ ni pé ẹni tó bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run máa ń fi gbogbo ọkàn ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ó sì máa ń wá bí á ṣe mú ìrònú rẹ̀ bá ti Ọlọ́run mu. Ẹni tó bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run máa ń ṣe ohun tó bá ìlànà Ọlọ́run mu, ó sì máa ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run darí òun. a—Róòmù 8:5; Éfésù 5:1.
Tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run, ó sábà máa ń sọ ohun tí àwọn tí kò sún mọ́ Ọlọ́run máa ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, “ẹni ti ara kì í tẹ́wọ́ gba àwọn nǹkan ti ẹ̀mí Ọlọ́run,” tàbí àwọn ẹ̀kọ́ Ọlọ́run bí ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run ṣe máa ń ṣe. (1 Kọ́ríńtì 2:14-16) Àwọn tó jẹ́ ẹni ti ara máa ń dá “owú àti wàhálà” sílẹ̀ dípò kí wọ́n lawọ́, kí wọ́n sì jẹ́ ẹni àlàáfíà, ṣùgbọ́n ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run kì í ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 3:1-3) Bíbélì sọ pé àwọn abanijẹ́ máa ń tú àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ká, ó sì sọ pé “wọ́n ń hùwà bí ẹranko, wọn ò ní ẹ̀mí Ọlọ́run.”—Júùdù 19; Òwe 16:28. b
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Báwo lèèyàn ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run?
A lè sún mọ́ Ọlọ́run torí pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Torí náà, kò yani lẹ́nu pé àwọn nǹkan tá ò lè rí tàbí tá ò lè fọwọ́ kàn máa ń wu ọ̀pọ̀ èèyàn, wọ́n sì máa ń fẹ́ mọ̀ sí i nípa wọn.
Bí Ọlọ́run ṣe dá wa máa ń mú ká fẹ́ láti fìwà jọ ọ́. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń fẹ́ kí àlàáfíà wà, a máa ń ṣàánú, a ò sì nífẹ̀ẹ́ ojúsàájú. (Jémíìsì 3:17) Jèhófà c Ọlọ́run tún máa ń fún àwọn tó bá ń sapá láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ ní ẹ̀mí mímọ́.—Ìṣe 5:32.
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn sún mọ́ Ọlọ́run?
Ẹni tó bá sún mọ́ Ọlọ́run máa ní “ìyè àti àlàáfíà.” (Róòmù 8:6) Ìyè àti àlàáfíà jẹ́ ẹ̀bùn tí kò lẹ́gbẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Ìyè: Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa fún àwọn tó bá sún mọ́ òun ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 17:3; Gálátíà 6:8.
Àlàáfíà: Èyí ni àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run. Ọ̀tá Ọlọ́run làwọn tó jẹ́ pé ohun tí wọ́n nílò nípa tara nìkan ni wọ́n gbájú mọ́. (Róòmù 8:7) Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run máa ń fún àwọn tó bá sún mọ́ ọn ní “àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye.” (Fílípì 4:6, 7) Irú àlàáfíà tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ bẹ́ẹ̀ ń fún wọn láyọ̀.—Mátíù 5:3.
Báwo ni mo ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run?
Mọ òfin Ọlọ́run, kó o sì máa pa á mọ́. Bó o ṣe lè ṣe èyí ni pé kó o máa ka Bíbélì, ìyẹn ìwé tí Ọlọ́run lo àwọn èèyàn láti kọ èrò rẹ̀ sí “bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí wọn.” (2 Pétérù 1:21) Ohun tí wàá rí kọ́ nínú Bíbélì á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè sin Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́,” kí ẹ̀mí Ọlọ́run sì máa darí ẹ lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.—Jòhánù 4:24.
Gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Lúùkù 11:13) Ọlọ́run á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa hùwà lọ́nà tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (Gálátíà 5:22, 23) Ó tún lè fún ẹ ni ọgbọ́n tí wàá fi máa yanjú àwọn ìṣòro tó o bá ń kojú.—Jémíìsì 1:5.
Àwọn tó ní ẹ̀mí Ọlọ́run ni kó o máa bá kẹ́gbẹ́. Wọ́n á mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. (Róòmù 1:11, 12) Àmọ́ tó o bá ń bá àwọn tí èrò wọn ò jọ ti Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́, wọ́n lè mú kí nǹkan tara gbà ẹ́ lọ́kàn.—Jémíìsì 4:4.
Ṣé mo gbọ́dọ̀ ní ẹ̀sìn kí n tó lè sún mọ́ Ọlọ́run?
Pé èèyàn ní ẹ̀sìn tirẹ̀ kò túmọ̀ sí pé ó sún mọ́ Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun gba Ọlọ́run gbọ́, àmọ́ tí kò ṣọ́ ahọ́n rẹ̀ gidigidi, ṣe ló ń tan ọkàn ara rẹ̀ jẹ, asán sì ni ìjọsìn rẹ̀.”—Jémíìsì 1:26, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
Síbẹ̀, Bíbélì fi hàn pé àwọn tó sún mọ́ Ọlọ́run máa ń sin Ọlọ́run lọ́nà tó fẹ́. Wọ́n gbà pé “ẹ̀mí kan,” ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, ló wà. Ẹ̀mí yẹn ń mú kí wọ́n máa sin Ọlọ́run pa pọ̀ bí “ara kan,” tàbí àwùjọ kan tó wà létòlétò tó ń “pa ìṣọ̀kan ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà.”—Éfésù 4:1-4.
Èrò tí kò tọ́ nípa béèyàn ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run
Èrò tí kò tọ́: Lára ohun tó túmọ̀ sí láti sún mọ́ Ọlọ́run ni pé kí nǹkan yọrí sí béèyàn ṣe fẹ́ tàbí kí ọwọ́ èèyàn tẹ gbogbo ohun tó ń wá.
Òótọ́: Ohun tí Bíbélì sọ pé ó túmọ̀ sí láti sún mọ́ Ọlọ́run ni pé kéèyàn jẹ́ kí Ọlọ́run máa darí ìgbésí ayé ẹni. Kò sọ pé kéèyàn máa wá bí ohun tí òun ń fẹ́ á ṣe yọrí sí rere láìwá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Àwọn tó sún mọ́ Ọlọ́run gbà pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wọn, wọ́n sì ń fi ayé wọn ṣe ohun tó wù ú, èyí ń mú kí ohun tí wọ́n ń ṣe máa yọrí sí rere.—Sáàmù 100:3.
Èrò tí kò tọ́: Èèyàn lè sún mọ́ Ọlọ́run tó bá ń fi ìyà jẹ ara rẹ̀ tàbí tó bá ń fa ìrora fún ara rẹ̀.
Òótọ́: Ṣe ni àwọn tó bá ń fìyà jẹ ara wọn ń “yan ọ̀nà ìjọsìn tiwọn fúnra wọn” tí wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ronú lọ́nà ti ara. (Kólósè 2:18, 23) Ayọ̀ ni Bíbélì sọ pé ẹni tó bá sún mọ́ Ọlọ́run máa ń ní, kì í ṣe ìrora.—Òwe 10:22.
Èrò tí kò tọ́: Téèyàn bá ń ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù tàbí àwọn tó ń bá òkú sọ̀rọ̀, ó máa jẹ́ kó túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.
Òótọ́: Àwọn tó ń bá òkú sọ̀rọ̀ gbà gbọ́ pé ẹ̀mí àwọn tó ti kú lè bá àwọn alààyè sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n, Bíbélì kọ́ wa pé àwọn òkú kò mọ nǹkan kan. (Oníwàásù 9:5) Bíbá ẹ̀mí lò ni kéèyàn máa bá àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Bíbá ẹ̀mí lò máa ń múnú bí Ọlọ́run, kì í sì í jẹ́ kéèyàn lè sún mọ́ Ọlọ́run.—Léfítíkù 20:6; Diutarónómì 18:11, 12.
Èrò tí kò tọ́: Gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá ló ní ẹ̀mí Ọlọ́run.
Òótọ́: Gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá ló ń fi ìyìn fún Ọlọ́run. (Sáàmù 145:10; Róòmù 1:20) Ṣùgbọ́n, àwọn ẹ̀dá olóye tí Ọlọ́run dá nìkan ni wọ́n lè ní ẹ̀mí Ọlọ́run. Àwọn ẹranko ò dà bí àwa èèyàn, ọgbọ́n tí Ọlọ́run dá mọ́ wọn ni wọ́n ń lò, irú ọgbọ́n yìí ò sì lè mú kí wọ́n di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ohun tí wọ́n bá fẹ́ ló ń pinnu irú ìwà tí wọ́n ń hù. (2 Pétérù 2:12) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé níní ẹ̀mí Ọlọ́run yàtọ̀ sí èrò tàbí ìwà tó jẹ́ ti ẹranko.—Jémíìsì 3:15; Júùdù 19.
a Nínú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì, àwọn ọ̀rọ̀ tá a tú sí “ọkàn” tún lè túmọ̀ ní tààràtà sí “èémí.” Ó tún túmọ̀ sí ohun tí kò ṣeé fojú rí ṣùgbọ́n tó ní agbára. Bíbélì pe Ọlọ́run ní Ẹni Ẹ̀mí Gíga Jù Lọ. Ẹni tó bá sún mọ́ Ọlọ́run máa ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run darí òun, ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ló sì máa ń ṣe.
b Àwọn tó jẹ́ pé ohun tí ara wọn ń fẹ́ tàbí ohun tí wọ́n nílò nípa ti ara ló ń gbà wọ́n lọ́kàn, tó sì jẹ́ pé ohun ló ń pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe láìka ìlànà Ọlọ́run sí ni Bíbélì pè ní ẹni “ti ara.”
c Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.