Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ Mímọ́?
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Kí nǹkan jẹ́ mímọ́ túmọ̀ sí pé kó má ní àbàwọ́n kankan. Ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “mímọ́” wá látinú ọ̀rọ̀ náà “yà sọ́tọ̀.” Torí náà, wọn kì í lo nǹkan tó bá jẹ́ mímọ́ nílòkulò, ọwọ́ pàtàkì ni wọ́n máa fi ń mú un, pàápàá jù lọ torí pé kò dọ̀tí, ó sì rí nigín-nigín.
Ọlọ́run lẹni mímọ́ jù lọ, kò sì sẹ́ni tó mọ́ tó o. Bíbélì sọ pé: “Kò sí ẹnì kankan tí ó jẹ́ mímọ́ bí Jèhófà.” a (1 Sámúẹ́lì 2:2) Fún ìdí yìí, Ọlọ́run nìkan ló lè jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè di mímọ́.
A lè pe ohunkóhun tó bá tan mọ́ Ọlọ́run ní “mímọ́,” pàápàá jù lọ àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa:
Àwọn ibi mímọ́: Nígbà tí Mósè wà ní ẹ̀gbẹ́ igbó tó ń jó, Ọlọ́run sọ fún un pé: “Ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí ìwọ dúró sí.”—Ẹ́kísódù 3:2-5.
Àpéjọpọ̀ mímọ́: Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì máa ń lọ sáwọn “àpéjọpọ̀ mímọ́” láti jọ́sìn Jèhófà.—Léfítíkù 23:37.
Ohun èlò mímọ́: Àwọn nǹkan tó wà nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù tí wọ́n ń lò fún ìjọsìn Ọlọ́run nígbà yẹn ni wọ́n ń pè ní, “nǹkan èlò mímọ́.” (1 Àwọn Ọba 8:4) Àwọn èèyàn kì í fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn nǹkan yẹn, síbẹ̀ kì í ṣe pé wọ́n ń jọ́sìn wọn. b
Ṣé èèyàn aláìpé lè jẹ́ mímọ́?
Bẹ́ẹ̀ ni. Ọlọ́run sọ fáwọn Kristẹni pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi jẹ́ mímọ́.” (1 Pétérù 1:16) Lóòótọ́, kò sí bí àwa èèyàn aláìpé ṣe lè jẹ́ mímọ́ pátápátá bí Ọlọ́run. Àmọ́ ẹni tó bá ń tẹ̀lé àwọn òfin Ọlọ́run máa jẹ́ ẹni “mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà” lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Róòmù 12:1) Ó máa hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe ẹni tó bá fẹ́ jẹ́ mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, irú eni yẹn á máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Kí ẹ ta kété sí àgbèrè,” àtèyí tó sọ pé: “Kí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín.”—1 Tẹsalóníkà 4:3; 1 Pétérù 1:15.
Ṣé ẹni tó jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run lè di aláìmọ́?
Bẹ́ẹ̀ ni. Tẹ́nì kan ò bá tẹ̀lé àwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́, Ọlọ́run ò ní ka ẹni yẹn sí mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn “ará mímọ́” ni Pọ́ọ̀lù kọ ìwé Hébérù sí, síbẹ̀ ó tún kìlọ̀ fún wọn pé “ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́” tó ń yani “kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè” lè dìde nínú ẹnikẹ́ni nínú wọn.—Hébérù 3:1, 12.
Àwọn èrò tí kò tọ́ nípa jíjẹ́ mímọ́
Èrò tí kò tọ́: Téèyàn bá máa jẹ́ mímọ́, ó gbọ́dọ̀ máa fìyà jẹ ara rẹ̀.
Òtítọ́: Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kéèyàn máa fi ìyà jẹ ara rẹ̀ tàbí kó máa fi nǹkan du ara rẹ̀ lọ́nà tó burú, kò ní ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run. (Kólósè 2:23) Dípò ìyẹn, Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbádùn ohun rere. “Kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.”—Oníwàásù 3:13.
Èrò tí kò tọ́: Tẹ́nì kan ò bá ṣègbéyàwó, ó máa túbọ̀ jẹ́ mímọ́.
Òtítọ́: Kò burú tí Kristẹni kan bá pinnu pé òun ò ní ṣègbéyàwó, àmọ́ ìyẹn kọ́ ló máa sọ ọ́ di ẹni mímọ́ lójú Ọlọ́run. Lóòótọ́ ó lè ṣeé ṣe fún ẹni tó kò ṣègbéyàwó láti sin Ọlọ́run láìsí ìpínyà ọkàn. (1 Kọ́ríńtì 7:32-34) Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, àwọn tó ṣègbéyàwó náà lè jẹ́ Mímọ́. Ó kéré tán, ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì Jésù ṣe ìgbéyàwó, ìyẹn Pétérù.—Mátíù 8:14; 1 Kọ́ríńtì 9:5.
a Jèhófà ni orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́. Ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ló máa ń sọ̀rọ̀ nípa “mímọ́” àti “ìjẹ́mímọ́” nígbà tó bá mẹ́nu ba orúkọ yẹn.
b Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kò yẹ ká máa jọ́sìn àwọn nǹkan èlò tí wọ́n lò nínú ìjọsìn Ọlọ́run láyé àtijọ́.—1 Kọ́ríńtì 10:14.