ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ
Bó O Ṣe Lè Máa Ní Sùúrù
“Ọkọ àti ìyàwó nílò sùúrù gan-an lójoojúmọ́. Ó lè má ṣòro fún ẹ láti máa ní sùúrù kó o tó ṣègbéyàwó, àmọ́, ó ṣe pàtàkì kí ìdílé kan tó lè ṣàṣeyọrí.”—John.
Kí nìdí tó o fi nílò sùúrù?
Ìgbéyàwó lè mú kó o túbọ̀ rí àwọn àṣìṣe ọkọ tàbí aya ẹ.
“Tó bá ti ṣe díẹ̀ tẹ́nì kan ti ṣègbéyàwó, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ranjú mọ́ àwọn kùdìẹ̀kudiẹ ọkọ tàbí aya rẹ̀. Tí èrò òdì yìí bá ń wá sí i lọ́kàn, ó lè tán an ní sùúrù.”—Jessena
Àìnísùúrù lè mú kó o sọ̀rọ̀ kó o tó ronú.
“Mo máa ń tètè sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára mi, ó sì máa ń mú kí n sọ ohun tí kò yẹ nígbà míì. Àmọ́ ká ní mo ní sùúrù ni, mi ò bá fara balẹ̀ rò ó dáadáa, kí n sì máa bá tèmi lọ láì tiẹ̀ sọ nǹkan kan.”—Carmen.
Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́ máa ń ní sùúrù àti inú rere.” (1 Kọ́ríńtì 13:4) Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé, kí ẹni méjì tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́mìí sùúrù. Àmọ́, kì í fìgbà gbogbo rí bẹ́ẹ̀. John tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Bíi tàwọn ànímọ́ dáadáa míì, àtiní sùúrù ò rọrùn tó pé kó bọ́ mọ́ọ̀yàn lọ́wọ́.” Ó gba ìsapá kéèyàn tó lè máa ní sùúrù nìṣó.”
Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o ní sùúrù?
Nígbà tí ohun kan tó ṣàdédé ṣẹlẹ̀ fẹ́ tán ẹ ní sùúrù.
Bí àpẹẹrẹ: Ká sọ pé ọkọ tàbí ìyàwó ẹ sọ ohun tí kò dáa sí ẹ. Ó lè ṣe ẹ́ bíi pé kó o dá a pa dà fún un.
Ìlànà Bíbélì: “Má ṣe máa kánjú láti bínú, torí pé àyà àwọn òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.”—Oníwàásù 7:9, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
Bó o ṣe lè fi hàn pé o ní sùúrù: Kọ́kọ́ dúró. Kó o tó fèsì, gbìyànjú láti gbà pé ohun kan ló fà á tí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ fi sọ ohun tó sọ sí ẹ, kì í ṣe pé ó mọ̀ọ́mọ̀. Ìwé Fighting for Your Marriage sọ pé: Ohun tá a rò ni ọ̀pọ̀ lára wa sábà máa ń fi hùwà pa dà sí ọkọ tàbí ìyàwó wa dípò ohun tó ní lọ́kàn tàbí ohun tó sọ gangan.
Ká tiẹ̀ sọ pé ọkọ tàbí ìyàwó ẹ múnú bí ẹ, sùúrù tó o ní lè paná ọ̀rọ̀ náà kàkà kó sọ ọ́ di ńlá. Bíbélì sọ pé “Níbi tí kò bá sí igi, iná á kú.”—Òwe 26:20.
“Tó bá ń wá sí ẹ lọ́kàn pé alátakò ni ìyàwó ẹ, kọ́kọ́ dúró, ronú nípa ìdí tó o fi fẹ́ràn ẹ̀, kó o sì ṣe nǹkan kan tó máa múnú ẹ̀ dùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”—Ethan.
Rò ó wò ná:
Kí lo máa ń ṣe tí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ bá sọ̀rọ̀ kan tàbí tó ṣe ohun kan tí kò bára dé sí ẹ?
Tírú ẹ̀ bá tún ṣẹlẹ̀, báwo lo ṣe lè túbọ̀ mú sùúrù?
Nígbà tí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ bá ń ṣe ohun kan léraléra, tó sì fẹ́ tán ẹ ní sùúrù.
Àpẹẹrẹ: Ọkọ tàbí ìyàwó ẹ máa ń pẹ́ lẹ́yìn, inú sì máa ń bí ẹ gan-an bó ṣe ń dá ẹ dúró.
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa fara dà á fún ara yín kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà.”—Kólósè 3:13.
Bó o ṣe lè fi hàn pé o ní sùúrù: Bí àjọṣe ẹ̀yin méjèèjì ṣe máa dáa sí i ló yẹ kó gbawájú kì í ṣe ire tara ẹ nìkan. Bi ara ẹ pé, ‘Tí mo bá fa ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí, ṣé ó máa ràn wá lọ́wọ́ àbí ó máa pa wá lára?’ Rántí pé, “gbogbo wa ni a maá ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” (Jémíìsì 3:2) Èyí fi hàn pé ìwọ náà ní àwọn ibi tó o kù sí.
“Nígbà míì, ó rọrùn fún mi láti mú sùúrù fáwọn ọ̀rẹ́ mi ju ọkọ mi lọ. Ó jọ pé ohun tó fà á ni pé mo sábà máa ń wà pẹ̀lú ọkọ mi, mo sì máa ń rí àwọn àṣìṣe ẹ̀. Àmọ́ ọ̀kan lára àwọn ìwà tí ìfẹ́ máa ń mú kéèyàn ní ni sùúrù, ó máa ń fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fúnni, ó sì ṣe pàtàkì gan-an nínú ìdílé.”—Nia
Rò ó wò ná:
Ṣé o máa ń ní sùúrù fún ọkọ tàbí ìyàwó ẹ tó bá ṣàṣìṣe?
Báwo lo ṣe lè túbọ̀ ní sùúrù nígbà míì?