ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ
Bó O Ṣe Lè Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kí Máàkì Rẹ̀ Lè Gbé Pẹ́ẹ́lí
Ó jọ pé ọ̀rọ̀ iléèwé ò ká ọmọ rẹ lára, kì í fẹ́ ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n bá fún un, kì í sì í fẹ́ kàwé. Ibo ló wá já sí? Ó bẹ̀rẹ̀ sí í gba òdo wálé, kì í sì í ṣe dáadáa mọ́ nínú ilé. Báwo lo ṣe lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí máàkì rẹ̀ lè gbé pẹ́ẹ́lí sí i níléèwé?
Ohun tó yẹ kó o mọ̀
Tó o bá ń fúngun mọ́ ọn, nǹkan á máa burú sí i. Tó o bá ń fúngun mọ́ ọmọ rẹ, ọkàn ẹ̀ ò ní balẹ̀ níléèwé, kò sì tún ní balẹ̀ nílé! Torí pé ó máa fẹ́ kó o fi òun lọ́rùn sílẹ̀, á di pé kó bẹ̀rẹ̀ sí í parọ́, kó máa fi àwọn iṣẹ́ iléèwé tó ti gbòdo pa mọ́, kó máa yíwèé lórí káàdì rẹ̀ tàbí kó máa sá níléèwé. Ṣe ni nǹkan á kàn máa burú sí i.
Tó o bá ń fún un lẹ́bùn, ẹ̀bùn náà lè má ṣiṣẹ́ tó o fẹ́ kó ṣe. Bàbá kan tó ń jẹ́ Andrew sọ pé, “Ká lè ṣe kóríyá fún ọmọ wa obìnrin, a sọ pé àá máa fún un lẹ́bùn tó bá ti gba máàkì tó dáa, àmọ́ ó wá di pé ẹ̀bùn yẹn ló ń fọkàn sí ṣáá. Ọjọ́ tí máàkì ẹ̀ ò bá ti dáa, ẹ̀bùn tí kò ní rí gbà yẹn máa ń dùn ún ju máàkì ẹ̀ tí ò dáa lọ.”
Tó o bá ń di ẹ̀bi ru àwọn olùkọ́, ọmọ rẹ̀ kò ní tẹ̀síwájú. Ọmọ rẹ lè parí èrò sí pé kò nílò kéèyàn sapá kó tó lè rí èsì tó dáa gbà nínú ìdánwò. Ó tún lè máa di ẹ̀bi tiẹ̀ ru àwọn míì, kó máa retí pé àwọn míì ló máa yanjú ìṣòro tóun ní. Lẹ́nu kan, ọmọ rẹ lè wá di ẹni tí kì í gba ẹ̀bi rẹ̀ lẹ́bi, kò sì ní dáa kírú ìwà yìí bá a dàgbà.
Ohun tó o lè ṣe
Kọ́ bí wàá ṣe máa pa nǹkan mọ́ra. Tínú bá ń bí ẹ, á dáa kó má jẹ́ àkókò yẹn ni wàá bá ọmọ ẹ sọ̀rọ̀ nípa máàkì tó ń gbà níléèwé. Bàbá kan tó ń jẹ́ Brett sọ pé, “Ìgbà tí ara èmi àtìyàwó mi bá balẹ̀, tá ò sì kanra la máa ń ṣàṣeyọrí jù.”
Ìlànà Bíbélì: “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.”—Jákọ́bù 1:19.
Mọ ibi tí ìṣòro wà gan-an. Àwọn ohun tó sábà máa ń fà á tí máàkì àwọn ọmọ kì í fi í dáa ni tí àwọn míì bá ń halẹ̀ mọ́ wọn, tí wọ́n bá ń pààrọ̀ iléèwé, tẹ́rù bá ń bà wọ́n lákòókò ìdánwò, tí ìdílé wọn bá níṣòro, tí wọn ò bá sùn dáadáa, tí wọn ò níṣètò tàbí tí wọn ò pọkàn pọ̀. Má kàn parí èrò sí pé ọ̀lẹ ni ọmọ rẹ.
Ìlànà Bíbélì: “Ẹni tí ń fi ìjìnlẹ̀ òye hàn nínú ọ̀ràn yóò rí ire.”—Òwe 16:20.
Ṣe ètò tó máa jẹ́ kó rọrùn fún ọmọ rẹ láti kẹ́kọ̀ọ́. Ṣètò ìgbà tó máa ṣiṣẹ́ àṣetiléwá àti ìgbà táá máa kàwé. Ṣètò ibì kan tí ọmọ rẹ á ti lè máa ṣiṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀ láìsí ohun tó máa dí i lọ́wọ́ (bíi tẹlifíṣọ̀n àti fóònù alágbèéká). Pín àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀ sí kéékèèké kó lè pọkàn pọ̀. Bàbá kan tó ń jẹ́ Hector lórílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé, “Tí àkókò ìdánwò ọmọ mi bá ti ń sún mọ́lé, ojoojúmọ́ la máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó ti kọ́ sẹ́yìn díẹ̀díẹ̀ dípò ká dúró dìgbà tó máa ti bọ́ sórí.”
Ìlànà Bíbélì: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún.”—Oníwàásù 3:1.
Jẹ́ kó wu ọmọ rẹ láti máa kẹ́kọ̀ọ́. Tó bá jẹ́ láti ìsinsìnyí ni ọmọ rẹ ti ń rí bí ohun tó ń kọ́ níléèwé ṣe ń ṣe é láǹfààní, á túbọ̀ máa wù ú láti kẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, ìṣirò tí wọ́n ń kọ́ ọ máa jẹ́ kó mọ bí á ṣe máa ná owó ọwọ́ ẹ̀.
Àbá: Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ tó bá ń ṣiṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀, àmọ́ má bá a ṣe é. Andrew gbà pé bó ṣe yẹ kó rí nìyẹn, ó ní, “Ọmọbìnrin wa ò tiẹ̀ wá fẹ́kan ṣe mọ́, àwa ló fẹ́ ká máa sọ gbogbo ìdáhùn iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀ fún un.” Kọ́ ọmọ rẹ bí á ṣe máa dá ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀.