Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Àǹfààní Tó Wà Nínú Eré Táá Mú Kí Ọmọdé Ronú

Àǹfààní Tó Wà Nínú Eré Táá Mú Kí Ọmọdé Ronú

 Àwọn eré tó ń mú kí ọmọdé ronú máa ń jẹ́ káwọn ọmọdé lo ọpọlọ wọn, ìyẹn máa ń jẹ́ kí wọ́n gbọ́n, kí wọ́n mọ béèyàn ṣe ń ronú, kára wọn sì jí pépé.

 Lára irú àwọn eré bẹ́ẹ̀ ni:

  •   Yíyà àwòrán

  •   Dínáná pẹ̀lú òbí

  •   Eré bojúbojú

  •   Orin kíkọ

  •   Títo ohun ìṣeré pọ̀

  •   Fífi àwọn nǹkan kéékèèké ṣeré (kódà ó gba ìrònú kó tó lè fi páálí ṣe àpótí)

 Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, dípò káwọn ọmọdé máa ṣeré táá mú kí wọ́n ronú, tẹlifíṣọ̀n ni wọ́n máa ń wò, wọ́n sì lè máa tẹ fóònù tàbí kí wọ́n máa ṣe eré táwọn míì bá ṣètò fún wọn.

 Ṣó yẹ kó o máa da ara ẹ láàmù nípa irú eré tọ́mọ ẹ ń ṣe?

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀

  •   Bí ọmọdé bá ń ṣeré táá mú kó ronú, ìyẹn á mú kó gbọ́n. Irú eré bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ kí ọmọ já fáfá, kí orí rẹ̀ pé, kó mọ nǹkan ṣe, kó sì máa bá àwọn èèyàn ṣeré. Ó tún lè kọ́ ọmọdé ní sùúrù, kó túbọ̀ mọ bó ṣe lè ṣe ìpinnu tó dáa, bá ṣe máa kó ara rẹ̀ níjàánu àti bá ṣe máa gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn tó ń bá ṣeré. Lọ́rọ̀ kan, eré tó ń mú kí ọmọdé ronú á jẹ́ kó mọ bá ṣe máa hùwà tó bá dàgbà.

  •   Ó léwu kéèyàn máa lo ẹ̀rọ ìgbàlódé ní àlòjù. Tí ọmọdé bá ń pẹ́ jù nídìí tẹlifíṣọ̀n tàbí ẹ̀rọ ìgbàlódé míì, ó lè di bárakú fún un. Bákan náà, àwọn ọmọ tó bá ń pẹ́ jù nídìí wọn lè sanra jọ̀kọ̀tọ̀ tàbí kí wọ́n di oníjàgídíjàgan. Ìkìlọ̀ lèyí jẹ́ fún àwọn òbí tó jẹ́ pé tẹlifíṣọ̀n tàbí ẹ̀rọ ìgbàlódé míì ni wọ́n máa ń tan fáwọn ọmọ wọn nígbà gbogbo.

  •   Ó ṣe pàtàkì káwọn ọmọ máa ṣeré láyè ara wọn. Tí ohun táwọn òbí ṣètò fún ọmọ bá ti pọ̀jù, àwọn ọmọ náà ò ní ráyè ṣe àwọn eré táá mú kí wọ́n máa ronú, kí ọpọlọ wọn sì jí pépé.

 Ohun tó o lè ṣe

  •   Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ ráyè ṣeré táá mú kí wọ́n ronú. Bí ààyè bá ṣe wà sí, jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ ṣeré ní ìta kí wọ́n lè rí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá. Jẹ́ kí wọ́n ṣeré tó wù wọ́n, kí wọ́n sì lo àwọn ohun ìṣeré tí wọ́n lè fi ṣe onírúurú nǹkan. a

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Tí ọmọ mi bá ń ṣeré táá mú kó ronú, àwọn ànímọ́ wo ló máa ní, kí ló máa mọ̀ ọ́n ṣe, àǹfààní wo nìyẹn sì máa ṣe é lọ́jọ́ iwájú?

     Ìlànà Bíbélì: ‘Àǹfààní wà nínú eré ìmárale.’—1 Tímótì 4:8.

  •   Dín àkókò táwọn ọmọ fi ń wo tẹlifíṣọ̀n kù. Rò ó dáadáa kó o tó jẹ́ kí ọmọ rẹ máa lo gbogbo àkókò rẹ̀ nídìí fóònù, ẹ̀rọ ìgbàlódé, tàbí tẹlifíṣọ̀n. Àwọn dókítà tó ń tọ́jú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ sọ pé kò yẹ káwọn ọmọ tí ò tíì pé ọmọ ọdún méjì máa wo tẹlifíṣọ̀n tàbí kí wọ́n máa lo ẹ̀rọ ìgbàlódé, kò sì yẹ káwọn ọmọ ọdún méjì sí márùn-ún máa wò ó ju wákàtí kan lọ lóòjọ́. b

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ìgbà wo ló yẹ kí n jẹ́ kọ́mọ mi wo tẹlifíṣọ̀n dà? Ṣé kí èmi àti ẹ̀ jọ máa wò ó? Kí ni mo lè fi rọ́pò ẹ̀rọ ìgbàlódé fún ọmọ mi?

     Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe bí aláìlọ́gbọ́n àmọ́ bí ọlọ́gbọ́n, kí ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.”—Éfésù 5:15, 16.

  •   Ronú nípa àkóbá tí ọ̀pọ̀ nǹkan tó o ṣètò lè ṣe fún ọmọ rẹ. Ó dájú pé wọ́n lè mú kí ọmọ rẹ já fáfá tàbí kó túbọ̀ mọ àwọn eré kan ṣe dáadáa. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ ìgbà ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú kó rẹ ọmọ náà àti òbí tó ń ṣe gbogbo ètò yẹn. Ká má gbàgbé ìlànà tó wà nínú Éfésù 5:15, 16 tó sọ pé ká máa fọgbọ́n lo àkókò wa.

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé ètò tí mo ṣe fún ọmọ mi ò ti pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àtúnṣe wo la lè ṣe?

     Ìlànà Bíbélì: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:10.

a Ọ̀pọ̀ àwọn ohun ìṣeré tí wọ́n ń ṣe lónìí kì í fi bẹ́ẹ̀ kọ́ àwọn ọmọ ní nǹkan kan. Ṣùgbọ́n tí ọmọdé bá ń lo àwọn ohun ìṣeré tó ṣeé tò pọ̀ tàbí àpótí tí wọ́n fi páálí ṣe, á jẹ́ kó lè lo ọpọlọ rẹ̀ dáadáa.

b Àkókò tọ́mọ fi ń wo tẹlifíṣọ̀n tó sì fi ń wo eré lórí fóònù là ń sọ níbi, kì í ṣe àkókò tẹ́ ẹ fi ń lo fídíò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì láti kàn sáwọn ọ̀rẹ́ tàbí èyí tẹ́ ẹ fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.