ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́
Bí Àwọn Òbí Ṣe Lè Tọ́ Àwọn Ọmọ Sọ́nà
Ohun tó yẹ kó o mọ̀
Nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan lóde òní, àwọn ọmọdé máa ń ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn òbí wọn, wọ́n sì máa ń fẹ́ káwọn òbí wọn tọ́ wọn sọ́nà. Àmọ́ láwọn ilẹ̀ míì, àwọn ọmọdé sábà máa ń gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn ojúgbà wọn.
Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ ojúgbà wọn làwọn ọmọdé ti ń gbàmọ̀ràn, wọ́n ò ní fi bẹ́ẹ̀ ka ìmọ̀ràn àwọn òbí sí. Nígbà táwọn ọmọ náà bá fi máa di ọ̀dọ́, á wá máa ṣe àwọn òbí wọn bíi pé ẹnu wọn ò ká wọn mọ́. Ìyẹn ò sì jẹ́ tuntun mọ́! Táwọn ọmọ bá ti ń lo àkókò púpọ̀ jù lọ́dọ̀ àwọn ọmọdé bíi tiwọn, ṣe ló máa ń dà bíi pé àwọn ọmọ náà ló tọ́ ara wọn dàgbà dípò àwọn òbí wọn.
Kí nìdí tó fi sábà máa ń rọrùn fáwọn ọmọdé láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ojúgbà wọn dípò àwọn òbí wọn? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.
Ilé Ìwé. Táwọn ọmọdé bá ti ń lo àkókò tó pọ̀ jù lọ́dọ̀ àwọn ọmọdé bíi tiwọn, wọ́n á di kòríkòsùn wọn, wọ́n á sì máa fara mọ́ ohun táwọn ojúgbà wọn bá sọ fún wọn ju ohun táwọn òbí wọn sọ fún wọn lọ. Ìṣòro náà tiẹ̀ lè wá burú sí i táwọn ọmọ náà bá di ọ̀dọ́.
Kò fi bẹ́ẹ̀ sáyè láti wà papọ̀. Ní ọ̀pọ̀ ìdílé, táwọn ọmọdé bá ti dé láti ilé ìwé, wọn ò kì í bá ẹnikẹ́ni nílé, bóyá tórí pé àwọn òbí wọn wà níbi iṣẹ́.
Ohun táwọn ọ̀dọ́ nífẹ̀ẹ́ sí. Gbàrà táwọn ọmọdé bá ti di ọ̀dọ́, ohun tó sábà máa ń gbà wọ́n lọ́kàn jù lọ ni bí wọ́n ṣe máa múra, bí wọ́n á ṣe máa sọ̀rọ̀, tí wọ́n á sì máa hùwà bíi tàwọn ọ̀dọ́ míì. Wọ́n máa ń ka ohun táwọn ojúgbà bá sọ fún wọn sí ju tàwọn òbí wọn.
Ìpolówó ọjà. Àwọn nǹkan táwọn oníṣòwò máa ń ṣe àtàwọn eré ìnàjú tí wọ́n máa ń gbé jáde sábà máa ń wà fáwọn ọ̀dọ́ nìkan. Ìdí nìyẹn tó fi túbọ̀ ṣòro fáwọn òbí àtàwọn ọ̀dọ́ láti lóye ara wọn. Dr. Robert Epstein kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ ńlá ló máa kógbá wọlé táwọn oníṣòwò ò bá ṣe àwọn nǹkan tó wà fáwọn ọ̀dọ́ nìkan mọ́.” a
Ohun tó o lè ṣe
Jẹ́ kí àjọṣe ìwọ àti ọmọ rẹ lágbára.
Bíbélì sọ pé: “Rí i pé o fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sọ́kàn, kí o máa fi kọ́ àwọn ọmọ rẹ léraléra, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ, nígbà tí o bá ń rìn lójú ọ̀nà, nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.”—Diutarónómì 6:6, 7.
Kò burú tàwọn ọmọ rẹ bá láwọn ọ̀rẹ́ tó jẹ́ ojúgbà wọn, àmọ́ má ṣe jẹ́ káwọn ojúgbà wọn gba iṣẹ́ rẹ̀ ṣe gẹ́gẹ́ bí òbí. Àmọ́ má sọ̀rètí nù: Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé, ọ̀pọ̀ ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́ ló máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn, wọ́n sì máa ń fẹ́ láti múnú wọn dùn. Tó o bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ, wàá lè máa darí wọn ju báwọn ojúgbà wọn ti ń ṣe lọ.
“Ó yẹ kó o máa wáyè fáwọn ọmọ rẹ, ẹ jọ máa ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe lójoojúmọ́, bíi kẹ́ ẹ jọ se oúnjẹ, kẹ́ ẹ jọ tún ilé ṣe, kẹ́ ẹ sì jọ ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá. Ẹ máa ṣeré papọ̀, bíi kẹ́ ẹ máa gbá géèmù, kẹ́ ẹ máa wo fíìmù tàbí tẹlifíṣọ̀n papọ̀. Má ṣe rò pé, tó o bá ṣáà ti lo àkókò díẹ̀ tó nítumọ̀ pẹ̀lú wọn, ìyẹn náà ti tó. Tó o bá ń lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ, wàá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú wọn!”—Lorraine.
Má ṣe jẹ́ kí wọ́n yan ojúgbà wọn nìkan lọ́rẹ̀ẹ́.
Bíbélì sọ pé: “Ọkàn ọmọdé ni ìwà òmùgọ̀ dì sí.”—Òwe 22:15.
Àwọn òbí kan máa ń fẹ́ káwọn ọmọ wọn lọ́rẹ̀ẹ́ tó pọ̀. Àmọ́, ó yẹ kí wọ́n ṣọ́ra, torí pé ọmọ kan lè láwọn ọ̀rẹ́ tó pọ̀, síbẹ̀ kó má láwọn ọ̀rẹ́ tọ́jọ́ orí wọn yàtọ̀ síra, tó lè ràn án lọ́wọ́ bó ṣe ń dàgbà. Àwọn ọ̀dọ́ ò lè rí ìtọ́sọ́nà tó wúlò lọ́dọ̀ ojúgbà wọn, àwọn òbí wọn nìkan ló lè pèsè ìtọ́sọ́nà tó dára jùlọ.
“Ojúgbà ọmọ kan lè ní òye nípa àwọn ohun kan, àmọ́ wọn ò ní ìrírí, wọn ò sì ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́ pàtàkì tí wọ́n lè fi ran ọ̀dọ́ bíi tiwọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn ìpinnu tó dára jùlọ nígbèésí ayé. Tàwọn ọ̀dọ́ bá tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà àwọn òbí wọn, wọ́n á dẹni tó gbọ́n dáadáa níbi tọ́jọ́ orí wọn mọ.”—Nadia.
Pèsè ìtọ́sọ́nà tó mọ́gbọ́n dání.
Bíbélì sọ pé: “Ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.”—Òwe 13:20.
Bí àwọn ọmọ rẹ ṣe ń dàgbà, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni wọ́n máa kọ́ lára ẹ tó o bá ń lo àkókò pẹ̀lú wọn. Àpẹẹrẹ rere ló yẹ kó o jẹ́ fún wọn.
“Àpẹẹrẹ àwọn òbí ló ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ káwọn ọmọ tẹ̀ lé. Tí wọn bá kọ́ àwọn ọmọ pé ó yẹ kí wọn nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí wọn, kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún wọn, ohun tàwọn ọmọ náà máa ṣe nìyẹn tí wọ́n bá dàgbà.”—Katherine.
a Látinú ìwé Teen 2.0—Saving Our Children and Families From the Torment of Adolescence.