ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́
Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Máa Moore
Ìwádìí fi hàn pé àwọn èèyàn tó bá ń moore máa ń láyọ̀, wọ́n máa ń ní ìlera tó dáa, ó máa ń rọrùn fún wọn láti kojú ìṣòro, wọ́n sì máa ń ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn. Olùṣèwádìí kan tó ń jẹ́ Robert A. Emmons sọ pé ẹni tó bá moore “kì í ṣe ìlara, kì í ìbínú, kì í lójú kòkòrò àti kì í sì dììyàn sínú.” a
Bí àwọn ọmọ bá lẹ́mìí ìmoore, báwo lo ṣe máa ṣe wọ́n láǹfààní? Ìwádìí kan tí wọ́n fi ọdún mẹ́rin ṣe nípa àwọn ọ̀dọ́ tí iye wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje (700) fi hàn pé àwọn tó moore lára àwọn ọ̀dọ́ náà ò fi bẹ́ẹ̀ jíwèé wò nígbà ìdánwò, wọn ò mutí, wọn ò lo oògùn olóró, wọn ò sì hùwà tí kò tọ́.
Ẹní bá ń rò pé òun lẹ́tọ̀ọ́ sí gbogbo nǹkan kì í moore. Ọ̀pọ̀ ọmọdé máa ń rò pé ẹ̀tọ́ àwọn ni gbogbo ohun rere tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn. Ẹni bá ń ronú pé ṣe làwọn tó ń ṣe òun lóore jẹ òun ní gbèsè irú oore bẹ́ẹ̀, máa ń ya abaramóorejẹ.
Irú èrò bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ lóde òní. Ìyá kan tó ń jẹ́ Katherine sọ pé: “Ohun tí ayé yìí fi ń kọ́ni ni pé gbogbo nǹkan lèèyàn lẹ́tọ̀ọ́ sí. Ìwé ìròyìn, tẹlifíṣọ̀n àti Íńtánẹ́ẹ̀tì ń fi ọ̀pọ̀ nǹkan tó yẹ ká gbà pé a lẹ́tọ̀ọ́ sì hàn wá, ó sì ń sọ fún wa pé àwa ló yẹ ká kọ́kọ́ ní wọn.”
Ọmọdé lè kọ́ béèyàn ṣe ń moore láti kékeré. Ìyá kan tó ń jẹ́ Kaye sọ pé: “Àwọn ọmọdé dùn ún kọ́. Wọ́n kúkú sọ pé àtikékeré la ti ń pẹ̀ka ìrókò, torí náà àtikékeré ló yẹ ká ti fi ìwà rere kọ́ wọn àwọn ọmọdé.”
Bí òbí ṣe lè kọ́ ọmọ láti máa moore
Kọ́ wọn ni ohun tí wọ́n á sọ. Àwọn ọmọdé pàápàá lè kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ káwọn máa dúpẹ́ bí ẹnì kan bá fún wọn lẹ́bùn tàbí tó ṣe wọ́n lóore. Bí wọ́n bá ṣe ń dàgbà tí wọ́n sì ń gbọ́n sí i, wọ́n á túbọ̀ máa mọrírì ohun táwọn míì bá ṣe fún wọn.
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa dúpẹ́.”—Kólósè 3:15.
“Ọmọ-ọmọ wa tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta máa ń tètè sọ pé ‘ẹ ṣeun,’ tó bá sì fẹ́ béèrè fún nǹkan á kọ́kọ́ sọ pé ‘ẹ jọ̀wọ́.’ Ohun táwọn òbí rẹ̀ fi kọ́ ọ nìyẹn. Ìwà tí wọ́n ń hù àti bó ṣe gbọ́ tí wọ́n máa ń dúpẹ́ ló sọ òun náà di ẹni tó mọpẹ́ẹ́dá.”—Jeffrey.
Kọ́ wọn ní òun tí wọ́n á ṣe. O ò ṣe ní káwọn ọmọ rẹ kọ̀wé ìdúpẹ́ nígbà míì tí ẹnì kan bá fún wọn ní ẹ̀bùn kan? Tó o bá tún ń fún àwọn ọmọ rẹ̀ níṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ṣe nínú ilé, wàá jẹ́ kí wọ́n mọrírì bó ṣe gba ìsapá tó láti mú kí nǹkan máa lọ geerege nínú ìdílé.
Ìlànà Bíbélì: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
“Àwọn ọmọ wa méjèèjì tí ò tíì pé ogún ọdún máa ń ṣe ipa tiwọn nínú ilé. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń se oúnjẹ, wọ́n sì máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́ẹ̀ẹ̀pẹ́. Ìyẹn jẹ́ kí wọ́n mọrírì ìsapá àwa òbí wọn, wọ́n sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wa.”—Beverly.
Kọ́ wọn ní ìwà tí wọ́n á hù. Bí ilẹ̀ tó dáa ṣe máa ń mú kí irúgbìn hù dáadáa, bẹ́ẹ̀ ni ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ṣe máa ń mú kéèyàn mọpẹ́ẹ́dá. Àwọn onírẹ̀lẹ̀ máa ń gbà pé àwọn nílò ìrànlọ́wọ́ ẹlòmíì káwọn tó lè ṣe ohunkóhun láṣeyọrí, ìyẹn sì máa ń mú kí wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó bá ràn wọ́n lọ́wọ́.
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ, bí ẹ ṣe ń wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.”—Fílípì 2:3, 4.
“Nígbà míì tá a bá ń jẹ́un, a máa ń ṣeré tó ń rán wa létí pé ká máa dúpẹ́. Olúkúlùkù wa máa ń sọ ohun tó dúpẹ́ fún. Eré náà máa ń jẹ́ kí gbogbo wa ní èrò tó dáa, èrò tó fẹ́mì ìmoore hàn dípò ká máa ro èròkerò, tàbí ká mọ tara wa nìkan.”—Tamara.
Ìmọ̀ràn kan rèé: Fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Ó máa rọrún fáwọn ọmọ láti máa dúpẹ́ tí wọ́n bá gbọ́ tó ò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn míì, tó o sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn náà.
a Látinú ìwé Thanks! How Practicing Gratitude Can Make You Happier.