ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ
Ohun Tí Ẹ Lè Ṣe Tí Owú Ò Fi Ní Dá Wàhálà Sílẹ̀ Láàárín Yín
Ìgbéyàwó ò lè láyọ̀ tí tọkọtaya bá ń fura síra wọn, tí wọn ò sì fọkàn tán ara wọn. Torí náà, kí lo lè ṣe tó ò fi ní máa jowú láìnídìí?
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Kí ló túmọ̀ sí pé èèyàn ń jowú?
Ọ̀rọ̀ náà “kéèyàn jowú” lè túmọ̀ sí oríṣiríṣi nǹkan. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, kéèyàn máa jowú túmọ̀ sí pé kí ẹnì kan máa ronú, kó sì gbà pé ọkàn ọkọ tàbí aya òun ti ń fà sí ẹlòmíì tàbí pé ọkàn ẹnì kan tí ń fà sí ọkọ tàbí aya òun. A lè wá máa ronú pé ìdílé wa ti ń dàrú lọ nìyẹn. Tá a bá ronú lọ́nà yìí, á jẹ́ pé owú tó tọ́ nìyẹn. Ó ṣe tán, o yẹ kí àárín àwọn méjì tó jẹ́ tọkọtaya gún régé, kí wọ́n sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí ìgbéyàwó wọn má bàa dàrú.
Ìlànà Bíbélì: “Wọn kì í ṣe méjì mọ́, àmọ́ wọ́n jẹ́ ara kan. . . . Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí èèyàn kankan má ṣe yà á.”—Mátíù 19:6.
“Owú tó tọ́ lè jẹ́ kí tọkọtaya mọ̀ pé ìṣòro ti ń rúgbó bọ̀, ìyẹn á sì jẹ́ kí wọ́n tètè bójú tó o.”—Benjamin.
Ìfura òdì àti ìbẹ̀rù ló ń jẹ́ kéèyàn máa jowú láìnídìí. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ ọkọ tàbí aya wa, a ò ní máa jowú láìnídìí. (1 Kọ́ríńtì 13:4, 7) Dókítà kan tó ń jẹ́ Robert L. Leahy sọ pé: “Tí èèyàn bá ń jowú láìnídìí, ohun tó máa ń ti ẹ̀yìn ẹ̀ yọ máa ń burú ju ohun téèyàn rò lọ, ìyẹn sì lè da àárín àwọn tọkọtaya rú.” a
Kí ló lè mú kéèyàn máa jowú láìnídìí?
Tó bá jẹ́ pé ẹnì kan ti dalẹ̀ rẹ rí, ìyẹn lè jẹ́ kó o máa jowú láìnídìí. Tàbí kó jẹ́ pé àwọn òbí rẹ kọ ara wọn sílẹ̀ torí ọ̀kan nínú wọn ṣe ìṣekúṣe, kíyẹn wá jẹ́ kó o máa bẹ̀rù pé kí ohun kan náà má ṣẹlẹ̀ sí ìgbéyàwó rẹ.
“Nígbà tí mo ṣì kéré, bàbá mi bá obìnrin kan ṣe ìṣekúṣe, ìyẹn jẹ́ kó ṣòro fún mi láti fọkàn tán àwọn míì. Ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá mi, ó sì jẹ́ kó ṣòro fún mi láti fọkàn tán ọkọ mi.”—Melissa.
Ohun míì ni pé: Tí ẹ̀rù bá ń bà ẹ́, tí ọkàn rẹ ò sì balẹ̀ pé ẹnì kejì rẹ lè fẹ́ ẹlòmíì, ìyẹn lè mú kó o máa wo àwọn míì bí i pé wọ́n fẹ́ gba ọkọ tàbí aya rẹ mọ́ ẹ lọ́wọ́.
“Nígbà tí ọ̀rẹ́ ọkọ mi kan fẹ́ ṣègbéyàwó, ó sọ pé kí ọkọ mi wà lára àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ, ó sì gba pé kí ọkọ mi bá obìnrin míì jó. Ìyẹn ò bá mi lára mu rárá. Torí náà, mi ò jẹ́ kí ọkọ mi ṣe é.”—Naomi.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àṣà ìgbéyàwó yàtọ̀ láti ibì kan sí ibòmíì, ó yẹ kí àwọn Kristẹni máa tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì. Ṣé a lè sọ pé ohun tí Naomi ṣe yẹn bọ́gbọ́n mu? Lẹ́yìn tó ronú lórí ọ̀rọ̀ náà, ó wá rí i pé ṣe ni òun ń jowú láìnídìí. Ó sọ pé, “Nígbà yẹn, ṣe lẹ̀rù ń bà mí, tọ́kàn mi ò sì balẹ̀. Mo rò pé ọkọ mi ń fi mí wé àwọn obìnrin míì, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bí mo ṣe rò.”
Ohun yòówù kó mú kéèyàn máa jowú láìnídìí, ó lè mú kéèyàn máa ronú pé ọkọ tàbí aya òun tí dalẹ̀ òun, téèyàn ò bá sì ṣọ́ra, ó lè fẹ̀sùn ìṣekúṣe kan ọkọ tàbí aya rẹ̀. Èrò tí ò tọ́ yìí lè ba àárín ìwọ àti ẹnì kejì rẹ jẹ́, kó sì tún ṣàkóbá fún ìlera rẹ.
Ìlànà Bíbélì: “Owú dà bí àìsàn tó ń mú kí egungun jẹrà.”—Òwe 14:30.
Kí lo lè ṣe tó ò fi ní máa jowú láìnídìí?
Túbọ̀ máa fọkàn tán ẹnì kejì rẹ. Dípò kó o máa wá àwọn nǹkan tó fi hàn pé ẹnì kejì rẹ ò ṣeé fọkàn tán, máa ronú lórí àwọn nǹkan tí ọkọ tàbí aya rẹ ti ṣe tó fi hàn pé o ṣeé fọkàn tán.
“Mo máa ń ronú lórí àwọn ìwà tó dáa tí ọkọ mi ní. Tó bá fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, kì í ṣe torí pé ó ní èrò tí kò tọ́, àmọ́ ó ṣe é torí pé ó bìkítà fún wọn. Mo máa ń rán ara mi létí pé tórí pé ìgbéyàwó àwọn òbí mi tú ká kò túmọ̀ sí pé ti tèmi náà máa rí bẹ́ẹ̀.”—Melissa.
Ìlànà Bíbélì: “Ìfẹ́ . . . máa ń gba ohun gbogbo gbọ́.”—1 Kọ́ríńtì 13:4, 7.
Má ṣe máa fura sí ẹnì kejì rẹ. Dókítà Leahy, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lókè sọ pé: “A sábà máa ń ronú pé gbogbo èrò wa ló tọ́. Tá a bá ti rò pé òótọ́ ni nǹkan kan, a máa ń gbà pé òótọ́ ni. Àmọ́ ti pé a ronú pé nǹkan kan jẹ́ òótọ́ ò túmọ̀ sí pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí.” b
“Tá a bá ń fura òdì sí ẹnì kejì wa, tá a sì ń méfò lórí nǹkan tí ò ṣẹlẹ̀, ìyẹn lè dá wàhálà ńlá sílẹ̀ nínú ìdílé.”—Nadine.
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.”—Fílípì 4:5.
Ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Ó yẹ kí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa ohun yòówù tó mú kó o máa jowú, ẹ jọ sọ ohun tó bọ́gbọ́n mu tí ẹ lè máa ṣe tí ẹnì kejì ò fi ní máa jowú.
“Bí ẹ ṣe jọ ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, fi sọ́kàn pé kì í ṣe pé ọkọ tàbí aya rẹ fẹ́ múnú bí ẹ, àmọ́ ńṣe ló ń wá bí ẹ ṣe máa yanjú ìṣòro náà. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé èrò tó tọ́ ni ẹnì kejì ẹ ní. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe lọ̀rọ̀ yẹn ká ẹ lára ju bó ṣe yẹ lọ. Tàbí kó o máa ronú pé ọkọ tàbí aya rẹ kò rí tìẹ rò.”—Ciara.
Ìlànà Bíbélì: “Kí kálukú máa wá ire ti ẹlòmíì, kì í ṣe ti ara rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 10:24.