Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÈ | ỌMỌ TÍTỌ́

Àwọn Ọmọdé àti Ìkànnì Àjọlò​—Apá 1: Ṣé Ó Yẹ Kí Ọmọ Mi Lo Ìkànnì Àjọlò?

Àwọn Ọmọdé àti Ìkànnì Àjọlò​—Apá 1: Ṣé Ó Yẹ Kí Ọmọ Mi Lo Ìkànnì Àjọlò?

 Ìwádìí kan fi hàn pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn ọ̀dọ́ ló ń lo ìkànnì àjọlò. Ṣé ó ti ń wu ọmọ rẹ láti máa lo ìkànnì àjọlò? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì kó o gbé àwọn kókó yìí yẹ̀ wò.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa

 Bí ọmọ rẹ ṣe ń lo àkókò rẹ̀

 Ìkànnì kan tí wọ́n ń pè HelpGuide sọ pé, “Wọ́n ṣètò ìkànnì àjọlò lọ́nà tá a fi máa lo àkókò tó pọ̀ nídìí ẹ̀, wọ́n fẹ́ ká máa fìgbà gbogbo wà lórí ẹ̀, ká sì tún máa wo àwọn ìsọfúnni tó ń wọlé látìgbàdégbà.

 Lynne tó jẹ́ ọmọ ogún (20ọdún sọ pe: “Kì í rọrùn láti gbé fóònù sílẹ̀ téèyàn bá ti wà lórí ìkànnì àjọlò, nígbà míì mo lè pinnu láti lo ìṣẹ́jú díẹ̀ àmọ́ kí n tó mọ̀, màá ti lo ọ̀pọ̀ wákàtí lórí ẹ̀.”

 Bi ara rẹ pé: Ṣé ọmọ mi kì í lò kọjá àkókò tí mo bá gbà á láyè láti lo lórí ìkànnì àjọlò? Bákan náà, ṣé ọmọ mi lè fúnra ẹ̀ pinnu pé àkókò báyìí lòun á lò lórí ìkànnì àjọlò, kó má sì kọjá àkókò náà?

 Ìlànà Bíbélì: ‘Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé ẹ̀ ń rìn bí ọlọ́gbọ́n, kí ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.’​—Éfésù 5:​15, 16.

Tó o ba gba ọmọ rẹ láyè láti lo ìkànnì àjọlò láìjẹ́ pé o tọ́ ọ sọ́nà, ṣe ló dà bí ìgbà tó o jẹ́ kó máa gun ẹṣin láìkọ́kọ́ jẹ́ kó mọ bí wọ́n ṣe ń gùn ún

 Èrò tí ọmọ rẹ ní nípa yíyan ọ̀rẹ́

 “Ìkànnì àjọlò” lè mú kéèyàn ronú pé òun ní ọ̀rẹ́ tó pọ̀ tóun lè kàn sí nígbàkigbà. Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn ọ̀rẹ́ yìí kì í ṣe ọ̀rẹ́ gidi.

 Patricia tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17sọ pé: “Ohun tí mo kíyè sí ni pé, àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń ronú pé tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá nífẹ̀ẹ́ ohun tí wọ́n gbé sórí ìkànnì àjọlò, tàbí tí wọ́n fẹ́ báwọn ṣọ̀rẹ̀ẹ́ níbẹ̀, á jẹ́ pé àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ àwọn nìyẹn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò mọ àwọn ẹni náà rí.”

 Bi ara rẹ pé: Ṣé ó yé ọmọ mi pé kì í ṣe iye àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ohun tó gbé sórí ìkànnì àjọlò ló fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? Àti pé, ṣé ó rọrùn fún un láti ní ọ̀rẹ́ lójú kojú?

 Ìlànà Bíbélì: “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”​—Òwe 17:17.

 Àkóbá tó lè ṣe fún ọmọ rẹ

 Àwọn tó ń ṣèwádìí ti rí i pé téeyàn bá ń lo àkókò tó pọ̀ gan-an nídìí ìkànnì àjọlò, ó lè fa ìrẹ̀wẹ̀sì, kí ọkàn ẹni má balẹ̀, tàbí kéèyàn máa ronú pé òun dá wà.

 Serena tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19sọ pé: “Tó o bá ń wo fọ́tò táwọn ọ̀rẹ́ ẹ yà níbi tí wọ́n ti ń gbádùn ara wọn nígbà tó ò sí níbẹ̀, ìyẹn lè mú kínú ẹ bà jẹ́.”

 Bi ara rẹ pé: Tí ọmọ mi bá rí ohun táwọn míì gbé sórí ìkànnì àjọlò, ṣé ìyẹn ò ní mú kó máa bá àwọn míì díje tàbí kó máa wá bó ṣe máa ṣe ohun táá mú káwọn míì gba tiẹ̀ tàbí kó máa pàfiyèsí sí ara ẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ?

 Ìlànà Bíbélì: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di agbéraga, kí a má ṣe máa bá ara wa díje, kí a má sì máa jowú ara wa.”​—Gálátíà 5:26.

 Ohun táá máa ṣe lórí ìkànnì àjọlò

 Téèyàn ò bá ṣọ́ra, ìkànnì àjọlò lè mú kéèyàn máa fi ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe ránṣẹ́, kó máa wo àwòrán ìṣekúṣe tàbí káwọn èèyankéèyàn máa halẹ̀ mọ́ ọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọ rẹ lè má lọ́wọ́ sírú àwọn ìwà yìí, síbẹ̀ ó lè bá àwọn tó ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ pàdé tó bá ń lo ìkànnì àjọlò.

 Linda tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún (23sọ pé: “Ohun tí mo kíyè sí ni pé, àwọn ohun tó wà lórí ìkànnì àjọlò lè kọ́kọ́ dà bí ohun tí ò burú, àmọ́ ká tó ṣẹ́jú pẹ́ àá ti rí i pé àwọn ohun tí ò yẹ ọmọlúàbí ló ń gbé lárugẹ. Àpẹẹrẹ kan ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ò bójú mu àtàwọn orinkórin.”

 Bi ara rẹ pé: Ṣé ọmọ mi máa lè fọgbọ́n lo ìkànnì àjọlò? Ṣé ó máa lè kó ara ẹ̀ níjàánu tó bá rí àwọn nǹkan tí ò bójú mu lórí ẹ̀?

 Ìlànà Bíbélì: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan ìṣekúṣe àti ìwà àìmọ́ èyíkéyìí tàbí ojúkòkòrò láàárín yín, . . . bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà àìnítìjú tàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ẹ̀fẹ̀ rírùn.”​—Éfésù 5:​3, 4.

 Ṣé ó tiẹ̀ pọn dandan kéèyàn lo ìkànnì àjọlò?

 Kò pọn dandan kéèyàn lo ìkànnì àjọlò kò tó lè láyọ̀ kí ìgbésí ayé sì nítumọ̀. Àwọn ọ̀dọ́ kan pinnu pé àwọn ò ní lo ìkànnì àjọlò, bọ́rọ̀ sì ṣe rí nìyẹn fáwọn kan tó ti lò ó rí àmọ́ tí wọ́n pinnu pé àwọn ò ní lò ó mọ́.

 Nathan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17sọ pé: “Nígbà tí mo rí àkóbá tí ìkànnì àjọlò ṣe fún ẹ̀gbọ́n mí, mo pinnu pe mi ò ní lò ó mọ́. Látìgbà yẹn, ọkàn mi balẹ̀, mo sì ń gbádùn ayé mi.”

 Kókó pàtàkì: Kó o tó gba ọmọ rẹ láyè láti lo ìkànnì àjọlò, rí i dájú pé ó ti lè pinnu àkókò tó fẹ́ lò, kó sì dúró lórí ìpinnu tó ṣe. Bákan náà, ó lè yan àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa, kó má sì wo àwọn ohun tí kò bójú mu.

 Ìlànà Bíbélì: “Aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.”​—Òwe 14:15.