Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

Tí Ẹnì Kan Nínú Ìdílé Bá Ń Mutí Lámujù

Tí Ẹnì Kan Nínú Ìdílé Bá Ń Mutí Lámujù

 Ṣé ìyàwó ẹ ti sọ fún ẹ rí pé inú òun ò dùn sí bó o ṣe ń mutí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á dáa kó o ronú lórí àwọn kókó mélòó kan.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

 Àmujù ọtí máa ń dá wàhálà sílẹ̀ láàárín lọ́kọláya

 Àmujù ọtí lè sọni di aláìsàn, kódà ó lè kọ́lé àrùn síni lára. Bí àpẹẹrẹ, ọtí àmujù lè mú kéèyàn ní àrùn ọkàn; ó ń mú kí ẹ̀dọ̀ sún kì, ó sì máa ń fa àrùn jẹjẹrẹ. Yàtọ̀ sí ìṣòro àìsàn, àmujù ọtí tún lè fa ìṣòro nínú ìdílé. Ó lè mú kí tọkọtaya máa bára wọn jà, kí ọ̀kan máa lu èkejì bí ẹni lu bàrà, tàbí káwọn òbí máa lu ọmọ nílùkulù. Bákan náà, kì í jẹ́ kéèyàn ní àkójọ, ó lè mú kí ọkọ tàbí ìyàwó lójú síta, kódà ó lè mú kí wọ́n kọra wọn sílẹ̀.

 Bíbélì sọ pé téèyàn bá ń mu ọtí lámujù, ó máa ń “buni ṣán bí ejò, á sì tu oró jáde bíi paramọ́lẹ̀.” (Òwe 23:32) Kí lá jẹ́ kó o mọ̀ bóyá ò ń mutí lámujù tàbí pé o ò lè ṣe kó o má mutí?

 Ṣé o ò lè ṣe kó o má mutí?

 Àwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá o ti ń ṣàṣejù tó bá dọ̀rọ̀ ọtí mímu:

  •   Ṣé o mọ̀wọ̀n ara ẹ tó bá dọ̀rọ̀ ọtí mímu?

  •   Ṣé o máa ń ronú ìgbà tí wàá tún ráyè mutí?

  •   Ṣó nira fún ẹ láti ṣíwọ́ ọtí mímu, bó o tiẹ̀ mọ̀ pé ó ń ṣàkóbá fún ẹ, tó sì tún ń dá wàhálà sílẹ̀ láàárín ìwọ àtìyàwó ẹ?

  •   Ṣó máa ń ṣe ẹ́ bíi kó o rí ọtí mu bó tiẹ̀ jẹ́ pé ò ń gbìyànjú láti jáwọ́?

  •   Ṣé ọ̀rọ̀ ọtí kì í dájà sílẹ̀ láàárín ìwọ àti ìyàwó ẹ?

  •   Ṣé bó o ṣe ń mutí tàbí ìwọ̀n ọtí tó ò ń mu ti pọ̀ ju tàtẹ̀yìnwá lọ?

  •   Ṣé o máa ń yọ́ kẹ́lẹ́ lọ mutí, àbí o máa ń ṣojú fúrú káwọn ará ilé tàbí àwọn ará ibi iṣẹ́ ẹ má bàa mọ̀ pé ò ń mutí?

 Tí ìdáhùn ẹ bá jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ ni” sí ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ìbéèrè yìí, a jẹ́ pé ọtí ti di bárakú fún ẹ nìyẹn o. Kódà, ó ṣeé ṣe kó o ti di ọ̀mùtí.

 Má tan ara ẹ jẹ tó bá dọ̀rọ̀ ọtí mímu

 Ṣé ìyàwó ẹ ti kọminú sí bó o ṣe ń mutí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o ti wá nǹkan sọ láti fi hàn pé o ò níṣòro. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó o di ẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà ru ìyàwó ẹ tàbí àwọn míì, kó o wá máa sọ pé:

  •   “Ká sọ pé ò ń pọ́n mi lé dáadáa ni, mi ò ní máa mutí.”

  •   “Tó o bá mọ ohun tójú mi ń rí níbi iṣẹ́ ni, o ò ní máa ṣàròyé pé mò ń mutí.”

  •   “Tó o bá ráwọn tó mọ ọtí mu, wàá gbà pé kékeré ni tèmi lẹ́gbẹ̀ẹ́ tiwọn.”

 Ṣé a lè sọ pé ẹni tó ń sọ irú ọ̀rọ̀ yìí lẹ́nu mọyì ìgbéyàwó ẹ̀, ṣé ó sì gbà pé ìdílé òun ṣe pàtàkì ju ọtí lọ? Ṣé irú èrò yìí lè mú kí inú tọkọtaya dùn síra wọn?

 Ìlànà Bíbélì: “Ọkùnrin tó gbéyàwó máa ń ṣàníyàn nípa . . . bó ṣe máa rí ìtẹ́wọ́gbà aya rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 7:33.

Tó o bá ń mutí lámujù, tó o sì ń sọ pé o ò níṣòro, ṣe ló dà bí ìgbà tó o fi ògiri pààlà sáàárín ìwọ àti ìyàwó ẹ. Àmọ́, tó o bá gbà sí ìyàwó ẹ lẹ́nu, tó o sì ṣàtúnṣe ńṣe ló máa dà bíi pé o fi wíńdò rọ́pò ògiri tó wà láàárín yín

 Ohun tó o lè ṣe

  •   Má fojú alásọjù wo ẹnì kejì ẹ. Tó bá tiẹ̀ jọ pé ìyàwó ẹ ti ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ yìí jù, o ò ṣe gbìyànjú láti ṣàtúnṣe. Tó bá nira fún ẹ láti ṣàtúnṣe, tó o wá ń fojú alásọjù wo ìyàwó ẹ, àmì nìyẹn jẹ́ pé ọtí mímu tí ń di bárakú fún ẹ.

     Ìlànà Bíbélì: “Kí kálukú máa wá ire ti ẹlòmíì, kì í ṣe ti ara rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 10:24.

  •   Ṣèwádìí nípa ìṣòro yìí. Tọ́mọ ogun kan bá máa borí lójú ogun, ó gbọ́dọ̀ mọ irú ọwọ́ tí ọ̀tá ń gbé bọ̀. Bọ́rọ̀ ẹ náà ṣe rí nìyẹn. Ó ṣe pàtàkì pé kó o mọ ewu tó wà nínú kéèyàn máa mutí lámujù àti bó ṣe rọrùn tó láti di ẹrú ọtí. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún yẹ kó o mọ bó o ṣe lè kó ara ẹ níjàánu, kó o má bàa pa dà dẹrú ọtí.

     Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa sá fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tó ń bá yín jà.”—1 Pétérù 2:11.

  •   Jẹ́ káwọn míì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Onírúurú ètò làwọn elétò ìlera ti gbé kalẹ̀ láti ran àwọn tó ń mutí lámujù lọ́wọ́. Lára ẹ̀ ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó lè mú kí ọ̀mùtí jáwọ́, wọ́n ṣètò ìtọ́jú fún ẹni tí ọtí sọ dìdàkudà, wọ́n sì láwọn ilé ìwòsàn tírú ẹni bẹ́ẹ̀ ti lè gba ìtọ́jú. Yàtọ̀ sáwọn ètò táwọn elétò ìlera ṣe yìí, o tún lè jẹ́ kẹ́ni tó sún mọ́ ẹ, tó o fọkàn tán, ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ẹni náà lè jẹ́ kó o mọ ohun tó fà á tó o fi ń mutí lámujù. Torí náà, o lè pe ẹni yìí nígbàkigbà tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o tún pa dà sídìí ọtí.

    O lè lọ sọ́dọ̀ àwọn dókítà pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́

     Ìlànà Bíbélì: “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”—Òwe 17:17.

 Ìṣòro ńlá lọ̀rọ̀ kéèyàn máa mutí lámujù. Ká sòótọ́, kéèyàn tó lè borí ẹ̀, ó kọjá kéèyàn kàn kàwé nípa ìṣòro ọtí mímu tàbí kéèyàn gbàmọ̀ràn nípa ẹ̀. Bákan náà, kì í ṣe ọ̀rọ̀ kéèyàn kàn sọ pé, “Wẹ́rẹ́ báyìí ni máa borí ìṣòro yìí tí mo bá ti dín ìwọ̀n ọtí tí mò ń mu kù.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gba pé kéèyàn ní èrò tó tọ́ nípa ìṣòro náà, kó sì fojú tó tọ́ wò ó. Ó ṣe tán, wàhálà tí àmujù ọtí ń fà kọjá ọ̀rọ̀ ìlera, àní sẹ́, ó ń da àárín lọ́kọláya rú, ó sì ń fọ́ ìdílé.

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i: Ka àwọn àpilẹ̀kọ tá a tò sísàlẹ̀ yìí kó o lè mọ ohun táwọn kan ṣe tí wọn ò fi mutí lámujù mọ́.

 Mi Ò Kì Í Ṣe Òǹrorò Èèyàn Mọ́

 Ojú Kì í Tì Mí Mọ́

 Mo Di Ọmọọ̀ta

 O tún lè wo fídíò náà, Ọ̀rọ̀ Ara Mi Sú Mi