Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | JÓÒBÙ

Jèhófà Wò Ó Sàn

Jèhófà Wò Ó Sàn

Nígbà tó yá, àwọn ọkùnrin náà ò sọ̀rọ̀ mọ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìró afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ wá láti aṣálẹ̀ ilẹ̀ Arébíà nìkan ló kù tó ń dún. Jóòbù kò mọ ohun tíì bá sọ mọ́, torí awuyewuye náà ti mú kó rẹ̀ ẹ́. Fojú inú wo bó ṣe ń fìbínú wo àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà, ìyẹn Élífásì, Bílídádì àti Sófárì. Bíi pé kí ló tún kù tí wọ́n fẹ́ sọ báyìí? Àmọ́, àwọn náà ò tiẹ̀ fẹ́ wo ojú Jóòbù rárá. Torí ó jọ pé gbogbo “ọ̀rọ̀ líle” tí wọ́n ti sọ sí i ò tu irun kankan lára rẹ̀. (Jóòbù 16:​3, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Tí wọ́n bá sì sọ ohunkóhun, Jóòbù ti múra sílẹ̀ láti gbèjà ara rẹ̀.

Lójú Jóòbù, kò sóhun tó dáa tó kéèyàn pa ìwà títọ́ ẹ̀ mọ́. Lẹ́yìn tó ti pàdánù gbogbo ohun ìní rẹ̀, àìsàn ò jẹ́ kó gbádùn, gbogbo ọmọ ẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá kú mọ́ ọn lójú, ó tún di ẹni ẹ̀tẹ́ lójú ará, ọ̀rẹ́, àtẹbí. Ṣe ni gbogbo ara ẹ̀ dúdú bó ṣe ń sé èépá tí ìdin sì bò ó nítorí àìsàn. Kódà, òórùn tó ń bù jáde lẹ́nu ẹ̀ ò dáa rárá. (Jóòbù 7:5; 19:17; 30:30) Àmọ́ ṣe ni ọ̀rọ̀ burúkú táwọn ọkùnrin mẹ́ta náà sọ túbọ̀ ń múnú bí i. Ó fẹ́ kí wọ́n gbà lóòótọ́ pé òun ò kì í ṣe ẹni burúkú tí wọ́n sọ pé òun jẹ́. Lẹ́yìn tí Jóòbù sì ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ṣe ni wọ́n dákẹ́ wẹ́lo. Kò sí ọ̀rọ̀ burúkú míì tí wọ́n tún fẹ́ sọ sí i mọ́. Àmọ́ ìrora tó bá Jóòbù ò tíì lọ. Ó ṣì nílò ìtùnú lójú méjèèjì.

A mọ̀ lóòótọ́ pé Jóòbù ò mọ ibi tíṣòro rẹ̀ ti wá. Síbẹ̀, ó ṣì nílò kẹ́nì kan tọ́ ọ sọ́nà. Ó tún nílò ẹni tó máa fún un níṣìírí táá sì fọkàn ẹ̀ balẹ̀, ohun tó sì yẹ káwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti ṣe tẹ́lẹ̀ nìyẹn. Ṣé ìgbà kan wà tó o kojú ìṣòro tó le, tó o sì retí pé káwọn èèyàn tù ẹ́ nínú kó o lè fara dà á? Ṣé àwọn tó o mú lọ́rẹ̀ẹ́ ti já ẹ kulẹ̀ rí? Ọkàn ẹ máa balẹ̀ wàá sì gbà pé ìrètí ṣì wà, tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ látinú bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe ran ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ń jẹ́ Jóòbù lọ́wọ́ àti bí Jóòbù ṣe mọyì ìrànlọ́wọ́ náà.

Agbaninímọ̀ràn Tó Gbọ́n, Tó Sì Ń Gba Tẹni Rò

Ohun míì tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn Jóòbù yani lẹ́nu. Ọ̀dọ́kùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Élíhù wà nítòsí ibi tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ náà. Àtìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn ló ti wà níbẹ̀, tó dákẹ́ tó ń gbọ́ gbogbo ohun táwọn àgbàlagbà náà ń sọ. Inú ẹ̀ ò sì dùn rárá sóhun tó ń gbọ́ lẹ́nu wọn.

Inú Élíhù ò dùn sí Jóòbù. Ó dun Élíhù pé Jóòbù tó jẹ́ olóòótọ́ gbà káwọn ọkùnrin mẹ́ta náà ti òun, débi tó fi ń “gbìyànjú láti fi hàn pé òun jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run lọ.” Síbẹ̀, Élíhù káàánú Jóòbù, ó mọ bí ìṣòro náà ṣe rí lára Jóòbù, ó mọ̀ pé olóòótọ́ ni, ó sì gbà pé ó nílò ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú. Ìdí nìyẹn tí ara Élíhù ò fi gbà á mọ́. Bó ṣe ń gbọ́ táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ń sọ̀rọ̀ burúkú sí i, tí wọ́n ń fojú kéré ìgbàgbọ́ àti ìwà títọ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń dójú tì í. Èyí tó tún wá burú jù ni bí wọ́n ṣe ń dọ́gbọ́n sọ pé ìkà ni Ọlọ́run. Torí náà, ṣe ni inú ń bí Élíhù, ó sì rí i pé ó yẹ kí òun dá sí ọ̀rọ̀ náà.​—Jóòbù 32:2-4, 18.

Élíhù sọ pé: “Ọmọdé ni mí, àgbàlagbà sì ni ẹ̀yin. Ìdí nìyẹn tí mi ò fi sọ̀rọ̀ torí mo bọ̀wọ̀ fún yín, mi ò sì jẹ́ sọ ohun tí mo mọ̀ fún yín.” Àmọ́ torí pé kò lè pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ra mọ́. Ó sọ pé: “Ọjọ́ orí nìkan kọ́ ló ń sọ èèyàn di ọlọ́gbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe àwọn àgbà nìkan ló mọ ohun tó tọ́.” (Jóòbù 32:6, 9) Àwọn ohun tó sọ lẹ́yìn náà sì fi hàn pé òótọ́ gbáà lọ̀rọ̀ yìí. Ọ̀rọ̀ tiẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ti Élífásì, Bílídádì àti Sófárì. Élíhù mú kó dá Jóòbù lójú pé òun ò ní kàn án lábùkù, òun ò sì ní dá kún ìṣòro rẹ̀. Ó tún buyì kún Jóòbù bó ṣe ń dárúkọ rẹ̀, ó sì jẹ́ kó hàn nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ò bọ̀wọ̀ fún un rárá. * Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni Élíhù fi sọ pé: “Ní báyìí, Jóòbù, jọ̀ọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.”​—Jóòbù 33:1, 7; 34:7.

Élíhù buyì kún Jóòbù bó ṣe ń dárúkọ rẹ̀, ó gba ti Jóòbù rò, kò sì kàn án lábùkù

Élíhù ba Jóòbù wí láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Ó sọ fún un pe: ‘O sọ ọ́ létí mi pé, ‘Mo mọ́, mi ò ní ẹ̀ṣẹ̀ lọ́rùn; Mo mọ́, mi ò ní àṣìṣe. Àmọ́ Ọlọ́run rí ìdí tó fi yẹ kó ta kò mí.’ Élíhù wá sọ ohun tó jẹ́ ìṣòrò Jóòbù gan-an, ó bi í pé: “Ṣé ó dá ọ lójú pé o jàre tí wàá fi sọ pé, ‘Òdodo mi ju ti Ọlọ́run lọ’?” Ọ̀dọ́kùnrin náà wá tún èrò Jóòbù ṣe. Ó sọ pé: “Ohun tí o sọ yìí ò tọ́.” (Jóòbù 33:​8-12; 35:2) Élíhù mọ̀ pé bí Jóòbù ṣe pàdánù ọ̀pọ̀ nǹkan kó ìdààmú tó kọjá àfẹnusọ bá a, àwọn ọ̀rẹ́ tó sì tún yẹ kó tù ú nínú tún dá kún ìṣòro rẹ̀. Àmọ́ Élíhù ní kí Jóòbù ṣe pẹ̀lẹ́, ó sọ fún un pé: “Rí i pé ìbínú ò sún ọ ṣe ìkà.”​—Jóòbù 36:18.

Élíhù Tẹnu Mọ́ Ọn Pé Aláàánú Ni Jèhófà

Pàtàkì ibẹ̀ ni pé, Élíhù jẹ́ kó ṣe kedere pé gbogbo ohun tí Jèhófà bá ṣe ló máa ń tọ̀nà. Ó fi ọ̀rọ̀ tó ṣe ṣàkó yìí ṣàkópọ̀ òótọ́ tí kò ṣeé já ní koro yẹn nígbà tó sọ pé: “Ó dájú pé Ọlọ́run tòótọ́ kò ní hùwà burúkú, pé Olódùmarè kò ní ṣe ohun tí kò dáa! . . . Olódùmarè kì í sì í yí ìdájọ́ po.” (Jóòbù 34:​10, 12) Élíhù rán Jóòbù létí pé Jèhófà jẹ́ aláàánú àti pé kì í ṣe ojúsàájú, ó sì jẹ́ kí Jóòbù mọ̀ pé torí pé tara ẹ̀ nìkan ló ń rò, ó ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ aláìnírònú àtàwọn ọ̀rọ̀ tí kò buyì kún Ọlọ́run tó yẹ kí Ọlọ́run torí ẹ̀ fìyà jẹ ẹ́, àmọ́ Jèhófà ò ṣe bẹ́ẹ̀. (Jóòbù 35:​13-15) Dípò tí Élíhù á fi ṣe bí ẹni tó mọ gbogbo nǹkan tán, ó fìrẹ̀lẹ̀ sọ pé: “Ọlọ́run tóbi ju bí a ṣe lè mọ̀.”​—Jóòbù 36:26.

Òótọ́ ọ̀rọ̀ pọ́ńbélé ni Élíhù sọ, síbẹ̀ kò sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà sí Jóòbù. Ó sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tó ní pé Jèhófà ṣì máa mú Jóòbù lára dá. Ọlọ́run máa sọ nípa ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ yìí pé: “Kí ara rẹ̀ jọ̀lọ̀ ju ti ìgbà ọ̀dọ́; kó pa dà sí àwọn ọjọ́ tó lókun nígbà ọ̀dọ́.” Ohun míì tí Élíhù ṣe tó fi hàn pé ó ní ìgbatẹnirò ni pé, ó ní kí Jóòbù sọ̀rọ̀ dípò kó kàn máa sọ àwọn ohun tó yẹ kí Jóòbù ṣe. Ó sọ pé: “Sọ̀rọ̀, torí mo fẹ́ fi hàn pé o jàre. (Jóòbù 33:​25, 32) Àmọ́, Jóòbù ò sọ nǹkan kan bó ti wù kó kéré mọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jóòbù ò fẹ́ sọ nǹkan kan kó má bàa dà bíi pé ó ń wá àwíjàre fún ara rẹ̀ níwájú Élíhù, ẹni tó gba tiẹ̀ rò tó sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ ẹ́ lógún. Ó ṣeé ṣe kí Jóòbù bú sẹ́kún nígbà tó rí i pé Élíhù bìkítà fún un.

A rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ lára àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí. Àpẹẹrẹ Élíhù kọ́ wa nípa bá a ṣe lè gba àwọn tó wà nínú ìṣòro nímọ̀ràn ká sì tù wọ́n nínú. Tó o bá ṣe àṣìṣe, ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa jẹ́ kó o mọ ibi tó o kù sí tàbí kó kìlọ̀ fún ẹ kó o má bàa ṣe àṣìṣe tó burú jáì, kódà tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún un láti sọ fún ẹ. (Òwe 27:6) Irú ọ̀rẹ́ táwa náà fẹ́ jẹ́ nìyẹn, ká jẹ́ ẹni tó ń gba tẹni rò, ká sì fún àwọn tó wà nínú ìṣòro níṣìírí kódà tí wọ́n bá tiẹ̀ sọ̀rọ̀ tí kò dáa, tàbí láìronújinlẹ̀ torí ohun tó ń bá wọn fínra. Tó bá sì jẹ́ pé àwa la wà nínú ìṣòro, àpẹẹrẹ Jóòbù kọ́ wa pé ó yẹ ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ká fara balẹ̀ tẹ́tí sí ìmọ̀ràn táwọn míì bá fún wa dípò ká kó ọ̀rọ̀ wọn dànù. Kò sẹ́ni tó dàgbà ju ìbáwí àti ìmọ̀ràn lọ. Tá a bá sì gbà á, ó lè gba ẹ̀mí wa là.​—Òwe 4:13.

“Látinú ìjì”

Bí Élíhù ṣe ń sọ̀rọ̀, ó sábà ń mẹ́nu kan ìjì, àwọsánmà, ààrá àti mànàmáná. Ó sọ nípa Jèhófà pé: “Ẹ fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohùn rẹ̀ tó ń kù rìrì.” Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn ni Élíhù sọ̀rọ̀ nípa “ìjì.” (Jóòbù 37:​2, 9) Ó jọ pé ńṣe ni ìjì bẹ̀rẹ̀ sí í jà bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, kò sì pẹ́ tí ìjì tó ń jà díẹ̀díẹ̀ yìí fi wá di ńlá. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, ohun àràmàǹdà kan ṣẹlẹ̀. Jèhófà sọ̀rọ̀ látọ̀run!​—Jóòbù 38:1.

Ẹ wo bó ṣe máa rí lára yín ká sọ pé ẹ wà níbẹ̀ nígbà tí Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run ń dá yín lẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun tó dá!

Kò sígbà téèyàn ka ìwé Jóòbù tí inú rẹ̀ kò ní dùn tó bá dé àwọn orí tí Jèhófà ti bá Jóòbù sọ̀rọ̀. Ṣe ló dà bí ìgbà tí ìjì òtítọ́ ń gbá àwọn òfìfo ọ̀rọ̀, àwọn ọ̀rọ̀ èké tí Élífásì, Bílídádì àti Sófárì sọ dànù. Jèhófà ò tiẹ̀ bá àwọn ọkùnrin yìí sọ̀rọ̀ níbẹ̀rẹ̀ rárá àfìgbà tó yá. Jóòbù nìkan ló ń bá sọ̀rọ̀; ó sì bá ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ yìí wí tìfẹ́tìfẹ́ bí ìgbà tí bàbá kan ń bá ọmọ rẹ̀ wí.

Jèhófà mọ bí ìṣòro náà ṣe rí lára Jóòbù. Àánú Jóòbù ṣe Jèhófà, bó sì ṣe máa ń rí lára rẹ̀ nìyẹn tí àwọn ọmọ rẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́ bá ń jìyà. (Àìsáyà 63:9; Sekaráyà 2:8) Ó sì tún mọ̀ pé Jóòbù “ń sọ̀rọ̀ láìní ìmọ̀,” èyí tó mú kí ìṣòro rẹ̀ túbọ̀ burú jáì. Ni Jèhófà bá bá Jóòbù wí, ó bi í láwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kó ronú jinlẹ̀. Jèhófà béèrè pé: “Ibo lo wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Sọ fún mi, tí o bá rò pé o mọ̀ ọ́n.” Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ̀dá àwọn nǹkan, “àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀,” ìyẹn àwọn ańgẹ́lì tó jẹ́ ara ìdílé Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í hó yèè nígbà tí wọ́n rí àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà ṣẹ̀dá. (Jóòbù 38:​2, 4, 7) Jóòbù ò lè sọ ohunkóhun torí kó mọ nǹkan kan nípa rẹ̀.

Jèhófà sọ̀rọ̀ látinú ìjì, ó sì fìfẹ́ tọ́ Jóòbù sọ́nà

Jèhófà wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ṣẹ̀dá. Lọ́nà kan ṣáá, a lè sọ pé Jèhófà ṣàlàyé ìwọ̀nba nípa àwọn ohun tá à ń pé ní ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lónìí fún Jóòbù. Àwọn ẹ̀kọ́ bí, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà, ẹ̀kọ́ nípa ohun alààyè, ẹ̀kọ́ nípa ìtàn ìpele ilẹ̀, òkúta àti àwọn ẹ̀dá tó ń gbé láyé àti ẹ̀kọ́ físíìsì. Ní pàtàkì, Jèhófà ṣàlàyé nípa onírúurú àwọn ẹranko tó wà lágbègbè ibi tí Jóòbù wà, ìyẹn kìnnìún, ẹyẹ ìwò, ewúrẹ́ orí òkè, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó, akọ màlúù igbó, ògòǹgò, ẹṣin, àṣáǹwéwé, ẹyẹ idì, Béhémótì, (ohun náà là ń pè ní erinmi), àtèyí tó kẹ́yìn, Léfíátánì (ó ṣeé ṣe kó jẹ́ òun la mọ̀ sí ọ̀nì). Ẹ wo bó ṣe máa rí lára yín ká sọ pé ẹ wà níbẹ̀ nígbà tí Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run ń dá yín lẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun tó dá! *

Jèhófà Kọ́ Ọ Láti Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ àti Onífẹ̀ẹ́

Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣe gbogbo ohun tó ṣe yìí? Torí pé Jèhófà fẹ́ kí Jóòbù túbọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ni. Bí Jóòbù ṣe ń ṣàròyé pé Jèhófà ó ṣe dáadáa sí òun, ńṣe ló ń ba àjọṣe tó ní pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́ díẹ̀díẹ̀, ìyẹn sì tún dá kún ìṣòro ni. Torí náà, Jèhófà béèrè lọ́wọ́ Jóòbù léraléra pé ibo ló wà nígbà tí òun ṣẹ̀dá àwọn ohun àgbàyanu tó wà láyé àtọ̀run. Jèhófà tún bi í bóyá ó lè bọ́ àwọn ohun tó ṣẹ̀dá tàbí kó darí wọn bó ṣe wù ú. Tí Jóòbù ò bá lè darí àwọn ìṣẹ̀dá tó kéré jù, báwo ló ṣe wá rò pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ ohun tó yẹ kí Ẹlẹ́dàá ṣe? Ǹjẹ́ àwọn ọ̀nà Jèhófà àtàwọn èrò rẹ̀ ò kọjá òye Jóòbù lọ́nà tó pọ̀ fíìfíì?

Jóòbù kò jiyàn, kò bẹ̀rẹ̀ sí í máa wá àwáwí bẹ́ẹ̀ sì ni kò wá àwíjàre fúnra rẹ̀

Ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá Jóòbù sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé Jèhófà ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí i. Ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń sọ fún Jóòbù pé: ‘Ọmọ mi, ṣebí èmi ni mo dá gbogbo nǹkan yìí tí mò sì ń bójú tó wọn, àbí? Ṣé o wá rò pé mi ò ní lè bójú tó ẹ ni? Ṣé o rò pé mo lè pa ọ́ tì ni, àbí máa wá pa àwọn ọmọ ẹ? Ṣé èmi ni màá wá fi àìsàn ṣe ẹ́ ni àbí o rò pé mo lè gba gbogbo nǹkan tó máa jẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la rẹ dùn kó sì lóyin? Ta lo rò pé ó lè dá gbogbo nǹkan tó o ti pàdánù pa dà fún ọ, tó sì máa wò ẹ́ sàn bí kò ṣe èmi?’

Jóòbù ronú lórí àwọn ìbéèrè tí Jèhófà bi í, kò sì ju ẹ̀ẹ̀mejì péré lọ tó sọ̀rọ̀ láti fi dáhùn. Kò jiyàn, kò wá bẹ̀rẹ̀ sí í máa wá àwáwí bẹ́ẹ̀ sì ni kó wá àwíjàre fúnra rẹ̀. Ó fi ìrẹ̀lẹ̀ gbà pé bíńtín ni àwọn nǹkan tí òun mọ̀, ó sì kábàámọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ aláìnírònú tó sọ. (Jóòbù 40:​4, 5; 42:1-6) Àpẹẹrẹ àtàtà ni ìgbàgbọ́ Jóòbù jẹ́. Láìka gbogbo ohun tí ojú rẹ̀ rí, ó ṣì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà. Ó gbá ìbáwí tí Jèhófà fún un, ó sì ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. Ó yẹ kí àwa náà bi ara wa pé, ‘Ṣé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ mi pọ̀ débi tí máa fi gba ìbáwí àti ìmọ̀ràn táwọn míì bá fún mi?’ Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, gbogbo wa nílò irú ìbáwí àti ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Tá a bá sì fi tọkàntọkàn gbà á, a jẹ́ pé à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jóòbù nìyẹn.

“Ẹ Ò Sọ Òtítọ́ Nípa Mi”

Jèhófà mọ̀ pé ìyà ń jẹ Jóòbù, ó sì ṣe àwọn nǹkan tó máa tù ú nínú. Jèhófà wá yíjú sí Élífásì, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ló dàgbà jù nínú àwọn olùtùnú èké mẹ́ta yẹn, ó sọ pé: “Inú ń bí mi gidigidi sí ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ méjèèjì, torí ẹ ò sọ òtítọ́ nípa mi, bí ìránṣẹ́ mi Jóòbù ṣe sọ òtítọ́.” (Jóòbù 42:7) Ẹ ronú lórí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ yìí. Ṣé ohun tí Jèhófà ń sọ ni pé irọ́ ni gbogbo ohun táwọn ọkùnrin mẹ́ta yẹn sọ àbí pé gbogbo ohun tí Jóòbù sọ ló tọ̀nà? Rara. * Síbẹ̀ náà, ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ló wà láàárín Jóòbù àtàwọn tó fẹ̀sùn kàn án. Ìbànújẹ́ tó bá Jóòbù kọjá àfẹnusọ, ọkàn rẹ̀ gbọgbẹ́, àwọn tó sì tún yẹ kó tù ú nínú tún ń fẹ̀sùn èké kàn án. Torí náà, àwọn ọ̀rọ̀ tí kò mọ́gbọ́n dání lè jáde lẹ́nu ẹ̀ nígbà míì. Àmọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù ò ṣẹlẹ̀ sí Élífásì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ méjèèjì rí. Wọ́n dìídì sọ àwọn ọ̀rọ̀ burúkú yẹn torí pé ìgbéraga ti wọ̀ wọ́n lẹ́wù àti pé ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Ọlọ́run ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára. Kì í ṣe pé wọ́n fẹ̀sùn kan aláìmọwọ́-mẹ́sẹ̀ nìkan ni, àmọ́ wọn ò sọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa Jèhófà, ńṣe ni wọ́n ń dọ́gbọ́n sọ pé aláìláàánú àti ìkà ni Ọlọ́run. Ẹ ò rí i pé ìyẹn burú jáì!

Abájọ tí Jèhófà fi ní kí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yẹn rúbọ tó máa ná wọn lówó gan-an. Wọ́n gbọ́dọ̀ fi akọ màlúù méje àti àgbò méje rúbọ, owó kékeré kọ́ ló sì máa ná wọn. Nígbà tó yá, Jèhófà sọ nínú Òfin Mósè pé àlùfáà àgbà ní láti fi akọ màlúù rúbọ tó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó sì jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ yẹn máa mú kí gbogbo èèyàn orílẹ̀-èdè náà jẹ̀bi. (Léfítíkù 4:3) Lábẹ́ Òfin Mósè, àwọn ẹranko tó wọ́n jù tó sì níye lórí jù lọ nìyẹn. Jèhófà tún wá sọ pé kí òun tó lè tẹ́wọ́ gba ẹbọ wọn, Jóòbù ní láti kọ́kọ́ gbàdúrà fún wọn. * (Jóòbù 42:8) Ẹ ò rí i pé ìyẹn máa jẹ́ kí ara tu Jóòbù, pé Ọlọ́run rẹ̀ kà á sí oníwà títọ́ àti pé ìdájọ́ òdodo Jèhófà ló borí!

‘Jóòbù ìránṣẹ́ mi máa gbàdúrà fún yín.’​—Jóòbù 42:8

Ó dá Jèhófà lójú pé Jóòbù máa ṣe nǹkan tí òun ní kó ṣe, ìyẹn sì máa fi hàn pé ó dárí jí àwọn ọkùnrin mẹ́ta tó ṣe ohun tó dùn ún wọnú eegun yẹn lóòótọ́. Jóòbù ò sì já Baba rẹ̀ kulẹ̀. (Jóòbù 42:9) Bí Jóòbù ṣe ṣègbọràn yìí fi hàn pé ìwà títọ́ rẹ̀ ga lọ́lá, ìyẹn sì lágbára ju àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ. Jèhófà sì bù kún un lọ́nà tó gadabú.

“Ìfẹ́ Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́”

Jèhófà ní “ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó sì jẹ́ aláàánú” sí Jóòbù. (Jémíìsì 5:11) Lọ́nà wo? Jèhófà mú Jóòbù lára dá. Ẹ wo bí inú Jóòbù á ṣe dùn tó nígbà tó rí i pé ‘ara òun ti jọ̀lọ̀ ju ti ìgbà ọ̀dọ́’ lọ bí Élíhù ṣe sọ tẹ́lẹ̀! Àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ ti wá dúró tì í gbá-gbá-gbá báyìí, bí àwọn kan ṣe ń káàánú rẹ̀ làwọn míì ń fún lẹ́bùn. Jèhófà dá ohun ìní rẹ̀ pa dà, ó sì fún un ní ìlọ́po méjì gbogbo nǹkan tó ní tẹ́lẹ̀. Kí ni Jèhófà máa ṣe sí ọgbẹ́ tó lè jù lọ tí Jóòbù ní, ìyẹn bí gbogbo ọmọ rẹ̀ ṣe kú mọ́ ọn lójú? Dé ìwọ̀n àyè kan, ìtùnú ló máa jẹ́ fún Jóòbù àti ìyàwó rẹ̀ nígbà tí wọ́n bí ọmọ mẹ́wàá làǹtì-lanti míì! Kò tán síbẹ̀ o, Jèhófà tún fi ẹ̀mí gígùn jíǹkí rẹ̀. Jóòbù gbé láyé fún ogóje [140] ọdún sí i, èyí mú kó rí àwọn ọmọ rẹ̀ títí dé ìran kẹrin. Bíbélì sọ pé; “Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Jóòbù kú. Ó pẹ́ láyé, ayé rẹ̀ sì dáa.” (Jóòbù 42:10-17) Nínú Párádísè, Jóòbù, aya rẹ̀ ọ̀wọ́n àtàwọn ọmọ wọn máa tún wà papọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, tó fi mọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́wàá tí Sátánì pa.​—Jòhánù 5:28, 29.

Kí nìdí tí Jèhófà fi bù kún Jóòbù lọ́nà tó bùáyà tó bẹ́ẹ̀? Bíbélì dáhùn ìbéèrè yẹn, ó sọ pé: “Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù.” (Jémíìsì 5:11) Ìṣòro tí Jóòbù fara dà lé koko ju ohun èyíkéyìí tá a lè rò lọ. Ọ̀rọ̀ náà “ìfaradà” fi hàn pé kì í ṣe pé Jóòbù kàn ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe lójú àdánwò nìkan ni àmọ́ kò fàyè gba ohunkóhun tó lè ba ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tó ní sí Jèhófà jẹ́. Dípò tí ì bá fi jẹ́ kí ìbínú ru bò ó lójú tàbí kó di òkú òǹrorò, ó fi tinútinú dárí jí àwọn tó dìídì múnú bí i. Kò sì ìgbà kan tó sọ̀rètí tó ṣeyebíye tó ní nípa ọjọ́ ọ̀la nù, ó sì ṣìkẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì sí i jù lọ, ìyẹn ìwà títọ́ rẹ̀.​—Jóòbù 27:5.

Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní láti fara dà á. Ó sì dájú pé Sátánì máa fẹ́ ká bọ́hùn bó ṣe ṣe nínú ọ̀ràn Jóòbù. Ṣùgbọ́n tí ìgbàgbọ́ wa bá dúró digbí bá a ṣe ń fara dà á, tá a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tá a ṣe tán láti darí ji àwọn tó bá ṣe ohun tó dùn wá, tá a sì pinnu pé a ò ní jẹ́ kí ìwà títọ́ bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́, a ò ní pàdánù ìrètí ọjọ́ iwájú tó ṣeyebíye yẹn. (Hébérù 10:36) Kò sí ohun tó lè yẹ̀yẹ́ Sátánì tó kọjá pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jóòbù, kò sì sí ohun tó lè múnú Jèhófà tó nífẹ̀ẹ́ wa dénú dùn jùyẹn lọ!

^ ìpínrọ̀ 6 Àwọn ọ̀rọ̀ tí Élífásì, Bílídádì àti Sófárì sọ fún Jóòbù pọ̀ débi pé, ó lè kún orí mẹ́sàn-án nínú Bíbélì, àmọ́ kò síbi kankan tí wọ́n ti dárúkọ rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ wọn láti lè fi í lọ́kàn balẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 14 Nígbà tí Jèhófà ń bá Jóòbù sọ̀rọ̀, ó lo àfiwé tààràtà, nígbà míì sì rèé, ó lo àwọn ọ̀rọ̀ ewì. Jèhófà lo àwọn ọ̀nà yìí lọ́nà tó dáa gan-an débi pé èèyàn ò ní tètè mọ̀ tó bá yí kúrò lórí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan bọ́ sí òmíì. (Bí àpẹẹrẹ, wo, Jóòbù 41:1, 7, 8, 19-21.) Èyí ó wù kí Jèhófà lò nínú ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà fẹ́ kọ́ Jóòbù lẹ́kọ̀ọ́ kó lè túbọ̀ ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ẹlẹ́dàá.

^ ìpínrọ̀ 18 Kódà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ọ̀kan lára ọ̀rọ̀ tí Élífásì sọ, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé kò sí irọ́ nínú ọ̀rọ̀ Élífásì. (Jóòbù 5:13; 1 Kọ́ríńtì 3:19) Òótọ́ pọ́ńbélé ni Élífásì sọ, àmọ́ ọ̀nà tó gbà lò ó nínú ọ̀ràn Jóòbù ni kò dáa.

^ ìpínrọ̀ 19 Kò sí ibì kan nínú Bíbélì tá a ti rí i kà pé Jèhófà ní kí Jóòbù rú irú ẹbọ bẹ́ẹ̀ nítorí ìyàwó rẹ̀.