Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Òòlẹ̀ Ara Ìṣáwùrú Tó Ń Yọ̀

Òòlẹ̀ Ara Ìṣáwùrú Tó Ń Yọ̀

 Tipẹ́ tipẹ́ làwọn dókítà tó ń ṣiṣẹ́ abẹ ti gbà pé àwọn nílò òòlẹ̀ tó dáa tí wọ́n lè máa lò láti ṣiṣẹ́ abẹ, kí egbò àtàwọn iṣan ara lè tètè jinná. Ọ̀pọ̀ àwọn òòlẹ̀ tí wọ́n ń lò báyìí, ni kò ṣeé lò nínú ara èèyàn. Wọ́n lè ṣàkóbá fún ara, wọ́n máa ń lè gbagidi tí wọ́n bá gbẹ tán, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò lè lẹ àwọn iṣan ara tó bá ṣì tutù. Nígbà táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣe ìwádìí nípa ohun kan tó rí bí itọ́ lára ìṣáwùrú, a wọ́n rí ojútùú sáwọn ìṣòro yìí.

 Rò ó wò ná: Nígbà tí ìṣáwùrú bá fura pé jàǹbá fẹ́ ṣẹlẹ̀ sóun, ohun tó rí bí itọ́ náà á jáde lára ẹ̀, ìyẹn á sì mú kó ṣeé ṣe fún un láti lẹ̀ mọ́ ara ewé tó tutù. Ọgbọ́n tí ìṣáwùrú ń dá yìí máa ń dáàbò bò ó, ó ṣì máa ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti fà díẹ̀díẹ̀ nírú àsìkò bẹ́ẹ̀.

 Lẹ́yìn táwọn tó ń ṣèwádìí ṣe àyẹ̀wò ìṣáwùrú, wọ́n rí ohun tó mú kí nǹkan tó dà bí itọ́ náà jẹ́ òòlẹ̀ tó wúlò gan-an. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n rí i pé ohun tó rí bí itọ́ náà ní èròjà tó máa ń jẹ́ kó lẹ nǹkan pọ̀ àti èròjà tó máa ń mú kí nǹkan fà mọ́ra kíákíá. Ó máa ń wọ ojú ibi tí ìṣáwùrú bá lẹ̀ mọ́, ó sì máa ń ràn nígbà tí nǹkan kan bá fẹ́ fà á kúrò níbi tó wà. Ní báyìí táwọn olùṣèwádìí ti ṣe òòlẹ̀ kan tó dà bí itọ́ ìṣáwùrú, àwọn oníṣègùn ti ní òòlẹ̀ tó lágbára gan-an ju èyí tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀ lọ, tó sì lè lẹ̀ mọ́ àwọn ẹ̀yà ara èyíkèyìí. Wọ́n tiẹ̀ sọ pé ó lè lẹ̀ mọ́ àwọn ẹ̀yà ara dáadáa bí kèrékèré ṣe máa ń lẹ̀ mọ́ egungun.

 Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n gbà pé tó bá yá, òòlẹ̀ yìí máa di ọ̀kan pàtàkì lára irinṣẹ́ tí gbogbo àwọn dókítà tó ń ṣiṣẹ́ abẹ á máa lò, torí kò ní sí pé wọ́n ń rán ẹ̀yà ara mọ́. Wọ́n lè lò ó láti tún kèrékèré inú ara ṣe tàbí kí wọ́n fi lẹ àwọn ohun èlò ìtọ́jú ìṣègùn mọ́ ojú ibi tí wọ́n ti nílò rẹ̀ gan-an nínú ara. Wọ́n ti lo òòlẹ̀ yìí láti fi lẹ ihò tó wà nínú ọkàn ẹlẹ́dẹ̀ kan àtàwọn ihò tó wà nínú ẹ̀dọ̀ eku kan, ẹ̀rí sì fi hàn pé òòlẹ̀ náà wúlò gan-an.

 Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ máa ń kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá kí wọ́n lè rí ojútùú tó gbéṣẹ́ gan-an sáwọn ìṣòro táwọn èèyàn sábà máa ń ní. Ọ̀gbẹ́ni Donald Ingber tó jẹ́ olùdarí àjọ tó ń ṣèwádìí lórí bí wọ́n ṣe ń ṣe òòlẹ̀ sọ pé: “Ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn mọ ibi tó ti lè ri ohun tó ń wá, kó sì dá èyí tó máa wúlò mọ̀ tó bá ti rí i.”

 Kí lèrò rẹ? Ṣé òòlẹ̀ ara ìṣáwùrú tó ń yọ̀ kàn ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló ṣe iṣẹ́ àrà náà?

a Orúkọ táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fún un ni Arion subfuscus.