ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Àkóbá Wo Ni Ìkànnì Àjọlò Lè Ṣe fún Mi?
Ṣé àwọn òbí rẹ fún ẹ láǹfààní láti lo ìkànnì àjọlò? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà mẹ́ta tó ṣe pàtàkì ní ìgbésí ayé rẹ.
Ní apá yìí
Ṣé mi kì í fi àkókò ṣòfò lórí ìkànnì àjọlò?
Ṣe ni ìkànnì àjọlò dà bí ìgbà tèèyàn gun ẹṣin tí kò ní ìjánu, ṣé wà á gbà kó gbé ẹ ṣubú, àbí wà á fi ìjánu dá a dúró.
“Nígbà tí mo bá fẹ́ lo ìkànnì àjọlò fún ìṣẹ́jú díẹ̀, kí n tó mọ̀ wákàtí mélòó kan ti lọ! Mo wá rí i pé ìkànnì àjọlò lè di bárakú ó sì ń fi àkókò ẹni ṣòfò.”—Joanna.
Ǹjẹ́ o mọ̀? Àwọn tó ṣe ìkànnì àjọlò mọ̀ pé bí àwọn tó ń lò ó bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni owó tí wọ́n máa rí á ṣe pọ̀ torí àwọn tó ń polówó ọjà. Èyí ló mú kí ìkànnì àjọlò di bárakú.
Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé kì í ṣe pé mo kàn ń fi àkókò mi ṣòfò bí mo ṣe ń lọ sórí ìkànnì àjọlò láìnídìí? Ṣé mo lè lo lára àkókò náà láti fi ṣe àwọn nǹkan míì tó nítumọ̀?’
Ohun tó o lè ṣe. Pinnu iye àkókò tó o máa lò lórí ìkànnì àjọlò, kó o sì dúró lórí ìpinnu rẹ.
“Mo ṣe ètò kan sórí fóònù mi tó fi jẹ́ pé tí iye àkókò tí mo pinnu láti lò lórí ìkànnì àjọlò bá ti pé, ó máa kú fúnra ẹ̀. Ohun tí mo ṣe yìí ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an láti mọ bí màá ṣe lo ìkànnì àjọlò, kí n má sì fi àkókò ṣòfò.”—Tina.
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.”—Éfésù 5:16.
Ṣé ìkànnì àjọlò máa ń dí oorun mi lọ́wọ́?
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ pé ó kéré tán, ó yẹ káwọn ọ̀dọ́ máa sun oorun wákàtí mẹ́jọ lálẹ́, àmọ́ ọ̀pọ̀ wọn ni kì í sùn tó bẹ́ẹ̀. Ìkànnì àjọlò sì wà lára ohun tó máa ń fà á.
“Mo máa ń tẹ fóònù kí n tó lọ sùn. Kí n tó mọ̀, mo ti lo ọ̀pọ̀ wákàtí níbi tí mo ti ń wo ohun táwọn èèyàn gbé sórí ìkànnì àjọlò. Mo mọ̀ pé ìwà tí ò dáa ni, ó sì yẹ kí n jáwọ́ níbẹ̀.”—Maria.
Ǹjẹ́ o mọ̀? Téèyàn ò bá sùn dáadáa, ìyẹn lè mú kéèyàn máa ṣàníyàn, kó sì máa rẹ̀wẹ̀sì. Ọ̀jọ̀gbọ́n Jean Twenge tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìrònú ẹ̀dá sọ pé, téèyàn ò bá sùn dáadáa, ara ẹ̀ ò ní yá gágá, inú ẹ̀ ò sì ní dùn. Ó fi kún un pé, “tó bá ń bá a lọ bẹ́ẹ̀,” ìrònú ẹni náà lè má já geere mọ́, kó sì yọrí sí “àìsàn ọpọlọ tó burú.” a
Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń sùn tó bó ṣe yẹ?’ ‘Àbí ṣe ni mo máa ń wo ìkànnì àjọlò lásìkò tó yẹ kí n lọ sùn?’
Ohun tó o lè ṣe. Tó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí fóònù rẹ jìnnà sí ẹ tó o bá fẹ́ lọ sùn. Tó bá tiẹ̀ ṣeé ṣe, wákàtí méjì kó o tó lọ sùn ni kó o ti gbé fóònù ẹ̀ sílẹ̀. Tó o bá fẹ́ kí àláàmù jí ẹ láàárọ̀, o lè lo èyí tí kò sí lórí fóònù tàbí tablet rẹ.
“Nígbà míì, mo máa ń pẹ́ lọ sùn torí pé mò ń tẹ fóònù, àmọ́ mo ti ń ṣiṣẹ́ lé e lórí. Ó yẹ kí n bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà àgbà káwọn èèyàn lè fọkàn tán mi. Mo gbọ́dọ̀ tètè máa sùn kára mi lè yá gágá lọ́jọ́ kejì.”—Jeremy.
Ìlànà Bíbélì: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:10.
Ṣé ìkànnì àjọlò lè ṣàkóbá fún bí nǹkan ṣe ń rí lára mi?
Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe, ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì àwọn ọmọbìnrin tó wà nílé ẹ̀kọ́ ló sọ pé, “ọ̀pọ̀ ìgbà ni inú àwọn kì í dùn, ó sì máa ń ṣe àwọn bíi pé ó ti tán fáwọn.” Ó ṣeé ṣe kí ìkànnì àjọlò wà lára ohun tó fà á. Dókítà Leonard Sax sọ pé: “Bó o bá ṣe ń lo àkókò sí i lórí ìkànnì àjọlò, tó ò ń fi ara ẹ wé àwọn míì, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa rẹ̀wẹ̀sì.” b
“Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń fi ara wọn wé àwọn míì, ìkànnì àjọlò sì máa ń mú kó rọrùn fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Tó o bá ń wo ohun táwọn èèyàn gbé sórí ìkànnì àjọlò, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ìgbésí ayé wọn sàn ju tìẹ lọ. Tó o bá sì ń wo ohun táwọn ọ̀rẹ́ ẹ gbé síbẹ̀, níbi tí wọ́n ti ń ṣe fàájì tàbí tí wọ́n ti ń jayé, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé wọ́n ń gbádùn jù ẹ́ lọ.”—Phoebe.
Ǹjẹ́ o mọ̀? Òótọ́ ni pé ìkànnì àjọlò lè mú kíwọ àti ọ̀rẹ́ ẹ máa kàn sí ara yín, àmọ́ kò lè dà bíi pé kẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ lójúkojú. Dókítà Nicholas Kardaras sọ pé: “Bínú wa ṣe máa ń dùn tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ yàtọ̀ sí bínú wa ṣe máa ń dùn tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú. Kódà àwọn èèyàn máa ń sọ pé ojú lọ̀rọ̀ wà.” c
Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ó máa ń ṣe mí bíi pé mo dá wà tí mo bá ń wo ohun táwọn ọ̀rẹ́ mi ń ṣe?’ ‘Ṣé ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò gbádùn ayé mi tí mo bá ń rí oríṣiríṣi nǹkan táwọn ọ̀rẹ́ mi ń gbé sórí ìkànnì àjọlò tó mú kó dà bíi pé wọ́n ń gbádùn ayé wọn?’ ‘Ṣé mi ò kì í rẹ̀wẹ̀sì tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló tẹ àmì pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí mo gbé sórí ìkànnì àjọlò?’
Ohun tó o lè ṣe. O lè pinnu pé o ò ní lo ìkànnì àjọlò fún ọjọ́ mélòó kan, ọ̀sẹ̀ kan tàbí oṣù kan pàápàá. Kó o wá túbọ̀ máa lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ lójúkojú tàbí kó o máa pè wọ́n lórí fóònù. Ó ṣeé ṣe kó o rí i pé ara á tù ẹ́, wàá sì túbọ̀ láyọ̀ ní gbogbo ìgbà tí o kò bá lo ìkànnì àjọlò.
“Mo kíyè sí i pé tí mo bá ń lo ìkànnì àjọlò, ohun táwọn míì ń ṣe ló máa ń gbà mí lọ́kàn. Mo wá pinnu pé mi ò ní lo ìkànnì àjọlò mọ́, mo sì yọ ọ́ kúrò lórí fóònù mi. Lẹ́yìn tí mo ṣe bẹ́ẹ̀, ara tù mí, ọkàn mi sì balẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ kí n túbọ̀ ráyè fáwọn nǹkan pàtàkì míì.”—Briana.
Ìlànà Bíbélì: “Kí kálukú máa yẹ ohun tó ń ṣe wò, nígbà náà, yóò láyọ̀ nítorí ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣe, kì í ṣe torí pé ó fi ara rẹ̀ wé ẹlòmíì.”—Gálátíà 6:4.