ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jẹ́ Káwọn Òbí Mi Fọkàn Tán Mi?
Ohun tó yẹ kó o mọ̀
Irú ẹni tó o bá fi han àwọn òbí ẹ pé o jẹ́ ló máa pinnu bí wọ́n á ṣe fọkàn tán ẹ tó. Tó o bá ń ṣe ohun táwọn òbí ẹ ní kó o ṣe, ṣe ló dà bí ìgbà tó o san gbèsè tó o jẹ ní báǹkì. Tó o bá ṣe ń san owó tó o yá ní báǹkì ni àwọn òṣìṣẹ́ báǹkì á máa fọkàn tán ẹ, wọ́n á sì tún lè yá ẹ lówó sí i. Lọ́nà kan náà, ó yẹ kó o máa gbọ́ tàwọn òbí ẹ, bó o bá sì ṣe ń gbọ́ tiwọn ni wọ́n á túbọ̀ máa fọkàn tán ẹ, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ kó o túbọ̀ lómìnira. Àmọ́ tó o bá ti ń ṣe ohun tí ò ní jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán ẹ, má jẹ́ kó yà ẹ lẹ́nu pé wọ́n lè dín òmìnira tó o ní kù.
Ó máa gba àkókò kí wọ́n tó lè fọkàn tán ẹ. Kí àwọn òbí ẹ tó lè túbọ̀ fún ẹ lómìnira, ó yẹ kí wọ́n mọ̀ ẹ́ mọ ìwà ọmọlúàbí.
OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ SÍ ẸNÌ KAN: “Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, mo mọ ohun táwọn òbí mi máa ń fẹ́ kí n ṣe gan-an, màá wá máa díbọ́n pé mò ń ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, bẹ́ẹ̀ ojú ayé ni mò ń ṣe, mò ń yọ́ tinú mi ṣe ní kọ̀rọ̀. Ìyẹn jẹ́ kó ṣòro fáwọn òbí mi láti fọkàn tán mi. Nígbà tó yá, mo rí i pé kò sí àbùjá lọ́rùn ọ̀pẹ. Tó o bá fẹ́ káwọn òbí ẹ fún ẹ lómìnira sí i, àfi kó o máa ṣe ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ fọkàn tán ẹ. Kò sọ́gbọ́n míì tó o lè dá.”—Craig.
Ohun tó o lè ṣe
Máa sòótọ́, kódà bí ohun tó o ṣe bá tiẹ̀ dùn ẹ́. Kò sẹ́ni tí kì í ṣàṣìṣe, àmọ́ tó o bá ń bo irọ́ mọ́lẹ̀ (tàbí tó ò ń fi àwọn òótọ́ kan pa mọ́), ṣe ló máa ba ìgbẹ́kẹ̀lé táwọn òbí ẹ ní nínú ẹ jẹ́. Ṣùgbọ́n tó o bá máa ń sòótọ́, táwọn òbí ẹ sì ti mọ̀ ẹ́ mọ́ ọn, wọ́n máa rí i pé o ti gbọ́n tó láti máa gba ẹ̀bi ẹ lẹ́bi. Irú ẹni tó sì ṣeé fọkàn tán nìyẹn.
“Ti pé ò ń ṣe àṣìṣe ò ní kí wọ́n má fọkàn tán ẹ mọ́, ohun tí ò ní jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán ẹ mọ́ ni tó o bá ń bo àṣìṣe ẹ mọ́lẹ̀.”—Anna.
Bíbélì sọ pé: “A . . . dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”—Hébérù 13:18.
Rò ó wò ná: Táwọn òbí ẹ bá bi ẹ́ léèrè ibi tó ò ń lọ àtohun tó o fẹ́ lọ ṣe, ṣé o máa ń sòótọ́ fún wọn délẹ̀délẹ̀? Àbí táwọn òbí ẹ bá bi ẹ́ léèrè ibi tó o lọ àtohun tó o lọ ṣe, ṣé o máa ń bomi la àlàyé tó yẹ kó o ṣe fún wọn?
Máa hùwà ọmọlúàbí. Gbogbo òfin tí wọ́n bá ṣe nínú ilé ni kó o máa tẹ̀ lé. Tètè máa ṣiṣẹ́ tí wọ́n bá ní kó o ṣe. Tí ìwọ àti ẹnì kan bá ní àdéhùn, má máa pẹ́ débẹ̀. Fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ iléèwé rẹ. Aago tí wọ́n bá ní kó o wọlé náà ni kó o máa wọlé.
“Táwọn òbí ẹ bá gbà kí ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ ṣeré jáde, àmọ́ tí wọ́n sọ fún ẹ pé aago mẹ́sàn-án alẹ́ ò gbọ́dọ̀ lù bá ẹ níta, tó o bá lọ délé ní aago mẹ́wàá ààbọ̀, má retí pé wọ́n á jẹ́ kó o bá àwọn ọ̀rẹ́ ẹ ṣeré jáde lọ́jọ́ míì!”—Ryan.
Bíbélì sọ pé: “Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.”—Gálátíà 6:5.
Rò ó wò ná: Kí làwọn òbí ẹ mọ̀ ẹ́ mọ́ tó bá dọ̀rọ̀ pípẹ́ lẹ́yìn, ṣíṣe iṣẹ́ ilé àti títẹ̀lé òfin tí wọ́n ṣe nínú ilé, ì báà tiẹ̀ jẹ́ òfin tó ò gba tiẹ̀?
Máa ní sùúrù. Tó o bá ti ṣohun tí ò jẹ́ káwọn òbí ẹ fọkàn tán ẹ mọ́, ó máa gba àkókò kí wọ́n tó tún lè pa dà fọkàn tán ẹ. Àfi kó o ṣe sùúrù.
“Nígbà tí mo dàgbà sí i, inú máa ń bí mi pé àwọn òbí mi kì í jẹ́ kí n ṣe àwọn nǹkan kan. Mi ò tètè mọ̀ pé àgbà ò kan ọgbọ́n, èèyàn lè dàgbà kó má danú. Mo wá ní káwọn òbí mi fún mi láǹfààní kí n lè jẹ́ kí wọ́n rí i pé wọ́n lè fọkàn tán mi. Ó gba àkókò díẹ̀ o, àmọ́ ó ṣiṣẹ́. Mo wá rí i pé ti pé èèyàn dàgbà kọ́ ló ń jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán an, ohun tó bá ń ṣe ló máa jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán an.”—Rachel.
Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.”—2 Kọ́ríńtì 13:5.
Rò ó wò ná: Tó o bá fẹ́ káwọn òbí ẹ fọkàn tán ẹ, kí làwọn ohun tó o lè ṣe láti fi irú ẹni tó o “jẹ́” hàn?
ÀBÁ: Fi ṣe àfojúsùn ẹ pé o ò fẹ́ máa pẹ́ lẹ́yìn, tàbí pé o fẹ́ tètè máa parí iṣẹ́ ilé tàbí pé o ò fẹ́ máa kọjá aago táwọn òbí ẹ bá ni kó o wọlé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Jẹ́ káwọn òbí ẹ mọ ohun tó o ti pinnu lọ́kàn ẹ, kó o sì bi wọ́n ní ohun tí wọ́n retí kó o máa ṣe kí wọ́n lè fọkàn tán ẹ. Kó o wá sapá láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì pé: “Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé.” (Éfésù 4:22) Bó pẹ́ bó yá, àwọn òbí ẹ máa rí pé nǹkan ti yàtọ̀!