ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?—Apá Kejì: Jẹ́ Kí Bíbélì Gbádùn Mọ́ Ẹ
“Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Will sọ pé: “Tí eèèyàn ò bá mọ ọ̀nà tó tọ́ láti ka Bíbélì, kò ní pẹ́ sú èèyàn.”
Ṣé wà á fẹ́ mọ àwọn ohun tó o lè ṣe kí Bíbélì kíkà lè gbádùn mọ́ ẹ? Àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Fojú inú yàwóràn ohun tó ò ń kà
Ṣe bí i pé o wà nínú ìtàn tó ò ń kà. O lè ṣe báyìí:
Yan ìtàn Bíbélì kan tó o máa fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. Ó lè jẹ́ ìtàn kan nínú Bíbélì bóyá nínú ìwé Ìhìn Rere, ó sì lè jẹ́ ìtàn kan látinú àwọn eré Bíbélì tó wà lórí ìkànnì jw.org.
Ka ìtàn náà. O lè ka ìtàn náà fúnra rẹ, tàbí kó o kà á sókè pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàbí àwọn ẹbí rẹ. Ẹnì kan lè máa ka ìtàn yẹn kí àwọn tó kù sì máa ka ọ̀rọ̀ tí àwọn èèyàn tó wà nínú ìtàn yẹn sọ.
Gbìyànjú ọ̀kan lára àwọn àbá yìí:
Ya àwọn àwòrán láti ṣàpèjúwe bí ìtàn náà ṣe ṣẹlẹ̀. O sì lè ya oríṣiríṣi àwòrán nípa bí ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú Bíbélì ṣe tò tẹ̀léra sínú ìwé kan. Kọ ọ̀rọ̀ síbẹ̀, kó o sì ṣàlàyé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn kọ̀ọ̀kan.
Ya àwọn àtẹ. Fún àpẹẹrẹ, bó o ṣé ń ka nípa ìtàn olóòótọ́ kan, so àwọn ànímọ́ àti àwọn ìṣe ẹni yẹn mọ́ àwọn ìbùkún tẹ́ni náà ti rí gbà.
Sọ bí ìtàn náà ṣe ṣẹlẹ̀ fún ẹnì kan. Ṣàlàyé onírúurú ọ̀nà tí ìtàn náà gbà ṣẹlẹ̀. Ṣe bí ẹni pé ò ń fi ọ̀rọ̀ wá ẹni tí ìtàn yẹn dálé lórí lẹ́nu wò àtàwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ṣojú wọn.
Ká sọ pé ìkan nínú àwọn tó wà nínú ìtàn náà ṣe ìpinnu tí kò tọ́, ronú nípa ohun tó yẹ kó ṣe. Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa bí Pétérù ṣe sẹ́ Jésù. (Máàkù 14:66-72) Ònà wo ló dáa jù tó yẹ kó gbà borí àdánwò náà?
Tí ó bá wù ẹ́ láti kọ ìtàn nípa nǹkan tí ò ń kà, o ò ṣe kọ àwòkẹ́kọ̀ọ́ kan tó dá lórí Bíbélì, àtàwọn ẹ̀kọ́ tá a lè kọ́ látinú ẹ̀.—Róòmù 15:4.
Ṣe ìwádìí!
Tó o bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìtàn kan dáadáa, wà á rí àwọn ìṣura tó fara pamọ́ nínú Bíbélì. Nígbà míì ó lè gba pé ká fi ẹsẹ Bíbélì kan tàbí méjì wéra.
Fún àpẹẹrẹ, fi Mátíù 28:7 wé Máàkù 16:7.
Kí nìdí tí Máàkù fi sọ nínú ìwé tiẹ̀ pé Jésù máa tó fara han àwọn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ “àti Pétérù”?
Àbá: Ó dájú pé Pétérù ló sọ ohun tó ṣelẹ̀ yẹn fún Máàkù, torí ko ṣojú ẹ̀.
Ìṣura tó fara pamọ́: Kí nìdí tọ́kàn Pétérù fi balẹ̀ nígbà tó gbọ́ pé Jésù tún fẹ́ rí òun? (Máàkù 14:66-72) Báwo ni Jésù ṣe fihàn pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ ló jẹ́ sí Pétérù? Báwo lo ṣe lè fara wé Jésù ní jíjẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́ sí àwọn míì?
Tó o bá ń ka Bíbélì bíi pé o wà níbẹ̀, tó o sì ń ṣèwáàdí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀, wàá ríi pé Bíbélì kíkà á túbọ̀ máa gbádùn mọ́ ẹ!