Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Fífi Ohun Tó Ń Mọ́kàn Fà sí Ìṣekúṣe Ránṣẹ́ Lórí Fóònù?

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Fífi Ohun Tó Ń Mọ́kàn Fà sí Ìṣekúṣe Ránṣẹ́ Lórí Fóònù?

Kí ló ní nínú?

  Àwọn èèyàn máa ń fi ohun tó ń mọ́kàn fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ sáwọn míì látorí fóònù wọn. Lára ohun tí wọ́n máa ń fi ránṣẹ́ ni àtẹ̀jíṣẹ́, fọ́tò tàbí fídíò tó dá lórí ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe. Ọkùnrin kan sọ pé, “Ohun tó lòde báyìí nìyẹn. Tíwọ àti ẹnì kan bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra yín, ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ẹ̀ẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fi oríṣiríṣi fọ́tò táá máa mọ́kàn yín fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ síra yín.”

 Kí ló máa ń mú káwọn èèyàn ṣe bẹ́ẹ̀? Ọ̀gá àgbà kan lẹ́nu iṣẹ́ agbẹjọ́rò sọ nínú ìwé ìròyìn The New York Times pé: “Tó o bá ti lè ní fọ́tò ìhòòhò ẹni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra yín sórí fóònù ẹ, ṣe lò ń fìyẹn sọ fáwọn èèyàn pé o ò kẹ̀rẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀. Téèyàn bá ń firú ẹ̀ ránṣẹ́ sẹ́nì kan, bí ẹni ní ìbálòpọ̀ láìfara kanra ló rí.” Ohun tó sì máa ń mú káwọn ọ̀dọ́ kan fi ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí fóònù nìyẹn. Ọ̀dọ́bìnrin kan tiẹ̀ sọ pé ó jẹ́ “ọ̀nà téèyàn ń gbà ní ìbálòpọ̀ láìfi ẹ̀mí ara ẹ̀ wewu.” Ó ní, “téèyàn bá ń ṣe irú ẹ̀, kò kúkú lè tibẹ̀ lóyún, kò sì lè kó àrùn táwọn èèyàn máa ń tibi ìbálòpọ̀ kó.”

 Àwọn ohun míì tó máa ń mú káwọn ọ̀dọ́ fi ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí fóònù rèé:

  •   Kí wọ́n lè máa bá ẹni tó wù wọ́n kí wọ́n jọ máa fẹ́ra tage.

  •   Torí pé ẹnì kan ti fi fọ́tò tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ sí wọn, àwọn náà wá wò ó pé àfi káwọn náà firú ẹ̀ ránṣẹ́ sí onítọ̀hún.’

Kí ló lè tẹ̀yìn ẹ̀ yọ téèyàn bá ṣe bẹ́ẹ̀?

  Tó o bá ti lè fi fọ́tò kan ránṣẹ́ lórí fóònù, ó ti kúrò ní tìẹ nìkan, torí tó bá ti tẹ àwọn míì lọ́wọ́, ohun tó bá wù wọ́n ni wọ́n lè fi ṣe. Wọ́n tiẹ̀ lè fi bà ẹ́ lórúkọ jẹ́. Amanda Lenhart, tó jẹ́ olùṣèwádìí àgbà, sọ̀rọ̀ lórí fífi ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí fóònù, iléeṣẹ́ Pew Research Center wá gbé jáde ohun tó sọ jáde. Ó ní: “Ó ti wá rọrùn gan-an báyìí kí gbogbo ayé rí ohun tí kò tọ́ téèyàn fi ránṣẹ́ látorí fóònù, ì báà jẹ́ pé ṣe lonítọ̀hún ṣèèṣì ṣe nǹkan ọ̀hún.”

 Nígbà míì

  •    Tí ọmọbìnrin kan bá fi fọ́tò ìhòòhò ẹ̀ ránṣẹ́ sí ọkùnrin kan, ṣe lọkùnrin náà á fi ránṣẹ́ sáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ míì káwọn náà lè wò ó, kí wọ́n máa fi gbádùn ara wọn.

  •    Tí ọmọbìnrin kan bá sọ fún ẹni tó ń fẹ́ pé òun ò ṣe mọ́, ṣe lọkùnrin yẹn máa fi àwọn fọ́tò ìhòòhò ọmọbìnrin náà tó ti ní lórí fóònù ẹ̀ ránṣẹ́ sáwọn míì, kó lè fìyẹn gbẹ̀san.

 ṢÓ O MỌ̀ PÉ lọ́pọ̀ ìgbà, tẹ́nì kan bá fi àwọn fọ́tò ìhòòhò ẹlòmíì ránṣẹ́ sáwọn èèyàn lórí fóònù, wọ́n lè fẹ̀sùn kàn án pé ó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe àbí pé ó ń pín àwòrán ìhòòhò ọmọdé, èyí tó ta ko òfin? Kódà, ọwọ́ òfin ti tẹ àwọn ọ̀dọ́ kan tó fi ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí fóònù.

Kí ni Bíbélì sọ?

  Bíbélì ò ta ko kéèyàn ní ìbálòpọ̀ tó bá ti ṣègbéyàwó. (Òwe 5:​18) Àmọ́ ó sọ ohun tó ṣe kedere nípa ohun tí kò yẹ kó wáyé láàárín àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó. Wo àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí:

  •   “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín, . . . bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà tí ń tini lójú tàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn.”​—Éfésù 5:​3, 4.

  •   “Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò.”​—Kólósè 3:5.

 Kì í ṣe “àgbèrè” (ìyẹn, ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó) nìkan ni àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn dẹ́bi fún, àmọ́ ó tún dẹ́bi fún àwọn nǹkan bí “ìwà àìmọ́” (ìyẹn, ọ̀rọ̀ tó kó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìṣekúṣe pọ̀) àti “ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo” (kì í ṣe láàárín àwọn tọkọtaya, àmọ́ ó jẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó lè mú kẹ́nì kan lọ ṣe ohun tí kò tọ́).

 Bi ara ẹ pé:

  •   Kí nìdí tá a fi lè sọ pé “ìwà àìmọ́” ni kéèyàn máa fi fọ́tò oníhòòhò ránṣẹ́ lórí fóònù?

  •   Báwo ló ṣe lè jẹ́ kéèyàn máa ní “ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo”?

  •   Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ó máa ṣèpalára fún ẹnì kan tó bá ń wù ú kó máa wo àwọn fọ́tò oníhòòhò tàbí tó ń wù ú kó fi ránṣẹ́ sẹ́lòmíì?

 Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó tẹ̀ lé e yìí tiẹ̀ tún jẹ́ ká rí ìdí tó fi pọn dandan kéèyàn má ṣe fi ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ sáwọn míì.

  •   “Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú.”​—2 Tímótì 2:​15.

  •    “Irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run!”​—2 Pétérù 3:​11.

 Àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn jẹ́ ká rí ohun rere tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ yọ tá a bá jẹ́ oníwà mímọ́. Tó o bá ń hùwà tó tọ́, kò sídìí fún ẹ láti máa bẹ̀rù pé o lè kábàámọ̀ àwọn ohun tó o ṣe, o ò ṣáà ṣohun tí kò dáa.​—Gálátíà 6:7.

 Bi ara ẹ pé:

  •    Irú èèyàn wo ni mo jẹ́?

  •    Ṣé mo máa ń ro ipa tí ohun tí mo bá ṣe máa ní lórí orúkọ rere àwọn ẹlòmíì?

  •    Ṣé ohun tó máa dun àwọn míì lèmi á fẹ́ fi ṣayọ̀?

  •    Tí mo bá ń fi ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ sáwọn míì, ipa wo ló lè ní lórí orúkọ rere tí mo ní?

  •    Ṣé ó máa jẹ́ káwọn òbí mi tún lè fọkàn tán mi?

 OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ SÍ ẸNÌ KAN “Mo ní ọ̀rẹ́ kan tó ń fẹ́ ọmọkùnrin kan, àmọ́ kò jẹ́ káwọn òbí ẹ̀ mọ̀. Lọ́jọ́ kan, ó fi fọ́tò ìhòòhò ara ẹ̀ ránṣẹ́ sí ọmọkùnrin yẹn lórí fóònù, ni ọmọkùnrin náà bá fi fọ́tò ìhòòhò ara tiẹ̀ náà ránṣẹ́ pa dà sí i. Kò tíì tó ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà tí dádì ọ̀rẹ́ mi yìí ní káwọn wo àwọn ohun tó wà lórí fóònù ẹ̀. Ni wọ́n bá rí ohun tí wọ́n fi ránṣẹ́ síra wọn. Inú wọn bà jẹ́ gan-an nígbà tí wọ́n rí i. Wọ́n lọ bá ọmọ wọn, wọ́n béèrè bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́, òun náà sì ṣàlàyé gbogbo ẹ̀, ó gbà póun ṣe ohun tí kò dáa. Mo mọ̀ pé ohun tó ṣe yẹn dun òun fúnra ẹ̀, àmọ́ ó ya àwọn òbí ẹ̀ lẹ́nu gan-an pé ó lè ṣe irú ẹ̀, inú wọn ò sì dùn rárá! Kódà, wọn ò mọ̀ bóyá àwọn á lè fọkàn tán an mọ́.”

 Òótọ́ kan ni pé: Téèyàn bá fi ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ sí ẹlòmíì, àwọn méjèèjì ló máa ń ṣàkóbá fún, ẹ̀tẹ́ ló sì máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀. Ọ̀dọ́bìnrin kan tí ọ̀rẹ́kùnrin ẹ̀ fi dandan mú un pé kó fi fọ́tò ìhòòhò ara ẹ̀ ránṣẹ́ sóun sọ pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ dójú tì mí gan-an, inú mi ò sì dùn síra mi rárá.”

 Ní báyìí tó o ti rí ohun tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ yọ téèyàn bá ń fi ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí fóònù, ìyẹn bó ṣe máa nípa lórí ìwọ àtàwọn míì àti ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tọ́wọ́ òfin bá tẹ̀ ẹ́, á dáa kó o tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì yìí:

  •   “Yẹra fún àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọ̀dọ́.”​—2 Tímótì 2:22, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀.

  •   “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí.”​—Sáàmù 119:37.

lo máa ṣe?

  Wo bí o ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn inú Bíbélì tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Ka ohun tí Janet sọ, kó o wá yan ohun tó o rò pé ó dáa jù kó ṣe.

 “Nígbà kan, èmi àti ọ̀dọ́kùnrin kan pàdé níbì kan, a sì gba nọ́ńbà ara wa. Kò tíì ju ọ̀sẹ̀ kan tá a pàdé tó fi ń sọ fún mi pé, kí n wọ ṣòkòtò péńpé àti aṣọ tí kò lápá, kí n wá ya fọ́tò ara mi ránṣẹ́ sóun.”​—Janet.

 Kí lo rò pé ó yẹ kí Janet ṣe? Tó bá jẹ́ ìwọ ni, kí lo máa ṣe?

  •  ÀKỌ́KỌ́ O lè máa rò ó pé: ‘Kò sóhun tó burú nínú ìyẹn. Àbí, tá a bá kúkú jọ lọ wẹ̀ lódò, mo lè fi irú aṣọ yẹn wẹ̀, á sì rí i lára mi.’

  •  ÌKEJÌ O lè máa rò ó pé: ‘Mi ò mọ ohun tó wà lọ́kàn bọ̀bọ́ yìí. Jẹ́ n fi fọ́tò ibi tí mi ò ti fi bẹ́ẹ̀ ṣí ara sílẹ̀ ránṣẹ́ sí i, kí n wá wo ohun tó máa ṣẹlẹ̀.’

  •  ÌKẸTA O lè máa rò ó pé: ‘Kò sí nǹkan míì tí bọ̀bọ́ yìí ń wá, àfi kó bayé mi jẹ́. Mi ò ní dá a lóhùn, màá sì pa ọ̀rọ̀ tó fi ránṣẹ́ sí mi rẹ́.’

 Ohun kẹta yìí ló dáa jù, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Bíbélì ṣáà sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n rí ibi, ó farapamọ́, ṣùgbọ́n òpè ń bá tirẹ̀ lọ láìbìkítà, ó sì kó sinu ìyọnu.”​—Òwe 22:3, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀.

 Àpẹẹrẹ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé yẹ̀ wò yìí ń jẹ́ ká mọ ohun kan, tó sábà máa ń mú káwọn èèyàn máa fi ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí fóònù tàbí kí wọ́n hu àwọn ìwà míì tí kò tọ́. Nǹkan ọ̀hún ni pé: Ṣé o máa ń fara balẹ̀ yan àwọn tó o máa bá ṣọ̀rẹ́? (Òwe 13:20) Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Sarah sọ pé, “Àwọn tó o mọ̀ pé wọn ò ní gba ìwàkiwà láyè ni kó o máa bá ṣọ̀rẹ́.” Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Delia náà fara mọ́ ọn, ó ní, “Ṣe làwọn kan tó o pè lọ́rẹ̀ẹ́ fẹ́ ba ìwà rere ẹ jẹ́, wọn ò ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa hùwà tó dáa. Tí ìwà táwọn ń hù bá ti ta ko òfin Ọlọ́run, ohun tí wọ́n ń fìyẹn sọ fún ẹ ni pé kó o fi ìwà rere tó ò ń hù sílẹ̀, kó o máa hùwà tí ò dáa. Ká sòótọ́, ṣé wàá fẹ́ ṣerú ẹ̀?”