ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Kí Ni Mo Lè Ṣe Káwọn Òbí Mi Má Bàa Máa Tojú Bọ Ọ̀rọ̀ Mi Jù?
Kí ló lè mú káwọn òbí ẹ máa yọjú sọ́rọ̀ ẹ?
Ire ẹ làwọn òbí ẹ rò pé àwọn ń wá. Àmọ́ lójú tìẹ, ṣe ni wọ́n ń tojú bọ ọ̀rọ̀ ẹ. Bí àpẹẹrẹ:
Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Erin sọ pé: “Dádì mi á mú fóònù mi, wọ́n á ní kí n ṣí i, wọ́n á wá máa wo gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo fi ránṣẹ́ sáwọn èèyàn àtàwọn tí wọ́n fi ráńṣẹ́ sí mi. Tí mi ò bá jẹ́ kí wọ́n ṣe é, wọ́n á máa rò pé nǹkan kan wà tí mò ń fi pa mọ́.”
Denise, tó ti lé lọ́mọ ogún [20] ọdún báyìí, rántí bí mọ́mì ẹ̀ ṣe máa ń yẹ àwọn tó fi fóònù ẹ̀ pè wò. Ó ní, “Wọ́n á máa wo àwọn nọ́ńbà tí mo pè níkọ̀ọ̀kan, wọ́n á béèrè ẹni tó ni ín, wọ́n á sì máa bi mí lóhun tí mo bá wọn sọ.”
Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Kayla sọ pé mọ́mì òun lọ ka ìwé kan tóun máa ń kọ ọ̀rọ̀ ara òun sí. Ó ní, “Gbogbo nǹkan tó bá ń ṣe mí ni mo máa ń kọ síbẹ̀, kódà, mo kọ àwọn nǹkan nípa mọ́mì fúnra wọn sínú ìwé yẹn! Àtìgbà yẹn ni mi ò ti kọ ọ̀rọ̀ ara mi sínú ìwé kankan mọ́.”
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Ojúṣe àwọn òbí ẹ ni láti bójú tó ẹ, ìwọ kọ́ lo sì máa kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe ṣe é. Ó lè fẹ́ dà bíi pé wọ́n ń tojú bọ ọ̀rọ̀ ẹ nígbà míì. Àmọ́ fọkàn balẹ̀, àwọn ohun kan wà tó o lè ṣe kó má bàa máa ṣe ẹ́ bí i pé wọ́n ń tojú bọ ọ̀rọ̀ ẹ.
Ohun tó o lè ṣe
Má fi nǹkan kan pa mọ́. Bíbélì rọ̀ wá pé ká “máa jẹ́ olódodo nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18, Bíbélì Mímọ́) Gbìyànjú láti máa sọ òótọ́ fáwọn òbí ẹ. Tó o bá ń sọ òótọ́, tó ò sì fi ohunkóhun pa mọ́ fún wọn, ó ṣeé ṣe kí wọ́n má yọjú sọ́rọ̀ ẹ mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀.
Rò ó wò ná: Ṣé àwọn òbí ẹ fọkàn tán ẹ? Tí wọ́n bá ní aago báyìí ni kó o délé, ṣé ìgbà yẹn náà lo máa ń délé? Ṣé o kì í fi àwọn ọ̀rẹ́ tó o ní pa mọ́? Ṣé o kì í fi àwọn ohun tó ò ń ṣe pa mọ́?
“Àfi kí n gba ohun táwọn òbí mi bá sọ. Mi ò kí ń fọ̀rọ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí mi pa mọ́ fún wọn. Ohunkóhun tí wọ́n bá bi mí ni mo máa ń sọ fún wọn, ìyẹn ti wá mú kí wọ́n fọkàn tán mi, wọn kì í sì í wá kúlẹ̀kúlẹ̀ gbogbo ohun tí mò ń ṣe mọ́.”—Delia.
Ní sùúrù. Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.” (2 Kọ́ríńtì 13:5) Ó lè pẹ́ díẹ̀ kí àwọn òbí ẹ tó lè fọkàn tán ẹ, àmọ́ ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Rò ó wò ná: Àwọn òbí ẹ ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí. Kí lo rò pé ìyẹn ní ín ṣe pẹ̀lú bí ọ̀rọ̀ ẹ ṣe máa ń jẹ wọ́n lógún?
“Ó dà bíi pé àwọn òbí máa ń rántí àwọn àṣìṣe tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ọ́, wọn kì í sì í fẹ́ káwọn ọmọ wọn tún ṣe irú ẹ̀.”—Daniel.
Máa fọ̀rọ̀ ro ara ẹ wò. Máa fira ẹ sí ipò àwọn òbí ẹ. Bíbélì sọ pé ìyàwó tó dáńgájíá máa ń “ṣọ́ àwọn ohun tí ń lọ nínú agbo ilé rẹ̀”, bàbá rere sì máa ń fi “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà” tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀. (Òwe 31:27; Éfésù 6:4) Torí náà, kò sí ọgbọ́n tó o fẹ́ dá sí i táwọn òbí ẹ ò fi ní máa dá sí ọ̀rọ̀ ayé ẹ.
Rò ó wò ná: Ká sọ pé òbí ni ẹ́, tó o sì ti mọ bẹ́yin ọ̀dọ́ ṣe máa ń ṣe, ṣé o kàn máa fi ọmọ ẹ sílẹ̀, kó máa ṣe nǹkan tó wù ú láìbi í ní ohunkóhun?
“Téèyàn bá wà lọ́dọ̀ọ́, ó lè fẹ́ dà bíi pé àwọn òbí ń ‘tojú bọ’ ọ̀rọ̀ èèyàn. Àmọ́ ní báyìí tí mo ti dàgbà, ó ti wá yé mi ìdí tó fi yẹ káwọn òbí ṣe bẹ́ẹ̀. Torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa ni.”—James.