ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Mo Bá Ń Sorí Kọ́?
Àwọn ohun kan wà tó o lè ṣe kó o lè bọ́ nínú ẹ̀!
Kí lo máa ṣe?
Wo àwọn àpẹẹrẹ yìí:
Inú ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Jennifer kì í dùn mọ́ rárá. Ṣe ló máa ń wa ẹkún mu lójoojúmọ́, láìsí ohun kan pàtó tó ṣe é. Ó máa ń yẹra fáwọn èèyàn, agbára káká ló sì fi ń jẹun. Kì í tún tètè rí oorun sùn, kì í sì í lè pọkàn pọ̀. Jennifer wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé: ‘Kí ló ń ṣe mí ná? Kì í ṣe bí mo ṣe rí tẹ́lẹ̀ nìyí. Ṣé bí màá ṣe wá máa bá a lọ rè é?’
Ọmọ iléèwé ni Mark, àpẹẹrẹ rere ló sì jẹ́ níléèwé. Àmọ́ nǹkan ti yí pa dà báyìí, iléèwé ò wù ú mọ́, kò sì ṣe dáadáa mọ́ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀. Agbára Mark ò tún gbé eré ìdárayá tó máa ń ṣe dáadáa tẹ́lẹ̀ mọ́. Ọ̀rọ̀ náà ò wá yé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mọ́, ọkàn àwọn òbí rẹ̀ ò sì balẹ̀. Ṣé ó kàn rí bẹ́ẹ̀ lákòókò yẹn ni, àbí ọ̀rọ̀ ọ̀hún jù bẹ́ẹ̀ lọ?
Ṣé ó má ń ṣe ẹ́ bíi ti Jennifer àti Mark? Tó bá máa ń ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe? Ohun méjì lo lè ṣe:
Máa bá a yí fúnra ẹ
Bá àgbàlagbà kan tó o fọkàn tán sọ̀rọ̀
Ó lè jẹ́ ohun àkọ́kọ́ ló máa wù ẹ́, pàápàá tí kò bá ṣe ẹ́ bíi kó o bá ẹnì kankan sọ̀rọ̀. Àmọ́ ṣé ohun tó dáa kó o ṣe nìyẹn? Bíbélì sọ pé: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan . . . nítorí, bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde. Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe rí fún ẹnì kan ṣoṣo tí ó ṣubú nígbà tí kò sí ẹlòmíràn láti gbé e dìde?”—Oníwàásù 4:9, 10.
Bí àpẹẹrẹ: Ká sọ pé o há sí àdúgbò kan tí ìwà ọ̀daràn ti gbòde. Ilẹ̀ ti ṣú, àwọn ojú tó ṣàjèjì sí ẹ̀ sì pọ̀ káàkiri ní gbogbo kọ̀rọ̀ àdúgbò náà. Kí lo máa ṣe? O lè wá ọ̀nà àbáyọ fúnra ẹ. Àmọ́ ṣé kò ní bọ́gbọ́n mu kó o ní kẹ́nì kan tó o fọkàn tán ràn ẹ́ lọ́wọ́?
Ìsoríkọ́ lè dà bí àdúgbò tó léwu yẹn. Lóòótọ́, tó o bá sorí kọ́ fúngbà díẹ̀, tó bá yá, ó lè má ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀ mọ́. Àmọ́ tí ìsoríkọ́ ò bá tètè lọ, á dáa kó o wá ìrànlọ́wọ́.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ . . . gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.”—Òwe 18:1.
Tó o bá ṣe ohun kejì, tó o bá òbí ẹ tàbí àgbàlagbà míì tó o fọkàn tán sọ̀rọ̀, àǹfààní tó máa ṣe ẹ́ ni pé wàá rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára onítọ̀hún, torí irú ẹ̀ lè ti ṣe òun náà rí.
O lè máa rò ó pé: ‘Àwọn òbí mi ò lè mọ bó ṣe máa ń rí jàre!’ Àmọ́ ṣé ó dá ẹ lójú pé wọn ò mọ̀ ọ́n? Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí wọ́n kojú nígbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ọ́ yàtọ̀ sí èyí tíwọ ń kojú, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí nǹkan ṣe rí lára ẹ nísìnyí ló rí lára tiwọn náà nígbà yẹn. Wọ́n sì lè mọ ohun tó o lè ṣe sí i!
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ọgbọ́n kò ha wà láàárín àwọn àgbàlagbà àti òye nínú gígùn àwọn ọjọ́?”—Jóòbù 12:12.
Fi sọ́kàn pé: Tó o bá fọ̀rọ̀ lọ òbí ẹ tàbí àgbàlagbà kan tó o fọkàn tán, ó ṣeé ṣe kí wọ́n gbà ẹ́ nímọ̀ràn tó máa wúlò.
Tó bá gba pé kó o lọ rí dókítà ńkọ́?
Tó bá jẹ́ ojoojúmọ́ lò ń sorí kọ́, ó lè gba pé kó o lọ rí dókítà, torí àìsàn ni ìsoríkọ́ máa ń jẹ́ nígbà míì.
Ìsoríkọ́ tó máa ń ṣe ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ máa ń kọ́kọ́ dà bí èyí tó máa ń ṣe àwọn ọmọ tó ń bàlágà, àmọ́ kì í tètè lọ, ó sì sábà máa ń le jùyẹn lọ. Torí náà, tí inú ẹ bá ń bà jẹ́ léraléra, tí ìbànújẹ́ ọ̀hún ò sì lọ, á dáa kó o sọ fáwọn òbí ẹ kẹ́ ẹ lè lọ rí dókítà.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Àwọn ẹni tí ó ní ìlera kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀.”—Mátíù 9:12.
Tí dókítà bá sọ pé àìsàn ni ìsoríkọ́ tó ń ṣe ẹ́, máà jẹ́ kójú tì ẹ́. Tìẹ kọ́ ni àkọ́kọ́, ó sábà máa ń ṣe àwọn ọ̀dọ́, ó sì gbóògùn! Àwọn ọ̀rẹ́ ẹ tòótọ́ ò ní tìtorí èyí wá fojú kéré ẹ.
Àbá: Ṣe sùúrù. Ó lè ṣe díẹ̀ kí ìsoríkọ́ tó ń ṣe ẹ́ tó lọ, sì máa fi sọ́kàn pé kó tó lọ tán, ó lè bá ẹ fà á díẹ̀. a
Ohun tó o lè ṣe sí i
Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ó gba pé kó o máa rí dókítà, àwọn nǹkan kan ṣì wà tó o lè ṣe tí inú ẹ bá ń bà jẹ́ ṣáá. Bí àpẹẹrẹ, ó dáa kó o máa ṣe eré ìmárale déédéé, máa jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore, kó o sì máa sùn dáadáa. Àwọn nǹkan yìí máa jẹ́ kí ọkàn ẹ balẹ̀. (Oníwàásù 4:6; 1 Tímótì 4:8, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Ó tún máa ṣe ẹ́ láǹfààní tó o bá ní ìwé kan tó o lè máa kọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ sí, ohun tó o fẹ́ ṣe sí i, àwọn ìpèníjà tó o ti ní lórí ọ̀rọ̀ yìí àtàwọn àṣeyọrí tó o ti ṣe.
Bóyá ṣe lo kàn sorí kọ́ fúngbà díẹ̀ torí ohun kan tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ àbí ìsoríkọ́ tó ń ṣe ẹ́ kò lọ, tó sì gba pé kó o rí dókítà, fi sọ́kàn pé: Tó o bá jẹ́ káwọn míì ràn ẹ́ lọ́wọ́, tíwọ fúnra ẹ náà sì wá nǹkan ṣe sí i, wàá lè borí ìṣòro yìí.
Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́
“Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”—Sáàmù 34:18.
“Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.”—Sáàmù 55:22.
“Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’”—Aísáyà 41:13.
“Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la.”—Mátíù 6:34.
“Ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín.”—Fílípì 4:6, 7.
a Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi kó o pa ara ẹ, ojú ẹsẹ̀ ni kó o lọ sọ fún àgbàlagbà kan tó o fọkàn tán. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ alápá mẹ́rin náà, “Má Ṣe Jẹ́ Káyé Sú Ẹ” nínú ìwé ìròyìn Jí! ti oṣù May—June, ọdún 2014.