ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Mi?
Èwo nínú àwọn nǹkan yìí lo lè fi ẹ̀rí ọkàn ẹ wé?
kọ́ńpáàsì
dígí
ọ̀rẹ́
adájọ́
Ìdáhùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ló tọ̀nà. A máa ṣàlàyé ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí.
Kí ni ẹ̀rí ọkàn?
Ẹ̀rí ọkàn ẹ ni ọlọ́pàá inú tó máa jẹ́ kó o lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Bíbélì sọ pé, ‘ó dà bí òfin tá a kọ sínú ọkàn èèyàn.’ (Róòmù 2:15, Contemporary English Version) Tó o bá ní ẹ̀rí ọkàn tó dáa, á jẹ́ kó o ronú dáadáa lórí ohun tó o fẹ́ ṣe tàbí ohun tó o ti ṣe.
Ẹ̀rí ọkàn ẹ dà bíi kọ́ńpáàsì. Ó máa tọ́ ẹ sọ́nà tó tọ́ kó o má bàa kó sí ìṣòro.
Ẹ̀rí ọkàn ẹ dà bíi dígí. Á jẹ́ kó o mọ bí ìwà ẹ ṣe rí àti irú ẹni tó o jẹ́ gan-an.
Ẹ̀rí ọkàn ẹ dà bí ọ̀rẹ́ gidi. Tó o bá fetí sí i, ó lè fún ẹ nímọ̀ràn tó dáa táá sì jẹ́ kó o ṣàṣeyọrí.
Ẹ̀rí ọkàn ẹ dà bí adájọ́. Ó máa dá ẹ lẹ́bi tó o bá ṣe ohun tí kò dáa.
Kókó ibẹ̀: Ẹ̀rí ọkàn ẹ lè jẹ́ kó o (1) ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, ó sì (2) lè jẹ́ kó o ronú lórí àṣìṣe tó o ṣe kó o sì ṣàtúnṣe.
Kí nìdí tó fi yẹ kó o kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ?
Bíbélì sọ pé ká “ní ẹ̀rí ọkàn rere.” (1 Pétérù 3:16) Àmọ́, ó máa ṣòro láti ní ẹ̀rí ọkàn rere tá ò bá kọ́ ọ.
“Mo máa ń parọ́ fáwọn òbí mi nípa ibi tí mo lọ, mo sì máa ń ṣe é láṣìírí. Níbẹ̀rẹ̀, ẹ̀rí ọkàn mi máa ń dà mí láàmú, àmọ́ nígbà tó yá, kò jọ mí lójú mọ́.”—Jennifer.
Nígbà tó yá, ẹ̀rí ọkàn Jennifer bẹ̀rẹ̀ sí í dà á láàmú, ó wá sọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ fún àwọn òbí ẹ̀, kò sì parọ́ fún wọn mọ́.
Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ìgbà wo ló yẹ kí ẹ̀rí ọkàn Jennifer ti kọ́kọ́ kìlọ̀ fún un?
“Ọkàn ẹni tó ń ṣojú ayé kì í balẹ̀, nǹkan sì máa ń nira fún un. Tí ẹ̀rí ọkàn ẹ bá ti gbà ẹ́ láyè láti ṣe ohun kan tí kò dáa, kó o tó mọ̀, á mọ́ ẹ lára.”—Matthew.
Àwọn kan kì í fetí sí ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn bá sọ fún wọn rárá. Bíbélì sọ pé wọ́n ti “kọjá gbogbo òye ìwà rere.” (Éfésù 4:19) Ohun tí Bíbélì Mímọ́ túmọ̀ rẹ̀ sí ni pé: “Ọkàn wọn le ré kọjá.”
Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Kí lo lè sọ nípa àwọn tí kì í dá ara wọn lẹ́bi bí wọ́n tiẹ̀ ṣe ohun tí kò dáa, ṣé ìgbésí ayé wọn máa ń sàn jù? Àwọn ìṣòro wo ni wọ́n sábà máa ń ní?
Kókó ibẹ̀: Kó o tó lè ní ẹ̀rí ọkàn tó dáa, ó yẹ kó o ‘kọ́ agbára ìfòyemọ̀ rẹ nípa bó o ṣe ń lò ó láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.’—Hébérù 5:14.
Báwo lo ṣe lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ?
Kó o tó lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ, o gbọ́dọ̀ ní ìlànà tàbí àpẹẹrẹ tó dáa tí wàá máa tẹ̀ lé. Ìlànà yẹn ló máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá ohun tó o ṣe dáa àbí kò dáa. Ohun táwọn kan ń jẹ́ kó máa darí wọn ni:
ìdílé àti àṣà ìbílẹ̀ wọn
àwọn ojúgbà wọn
àwọn òṣèré tó lókìkí
Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ nípa bó ṣe yẹ ká gbé ìgbésí ayé wa yàtọ̀ pátápátá sáwọn tó wà lókè yìí, ìlànà Bíbélì kò sì láfiwé. Kò sì yà wá lẹ́nu torí pé Ọlọ́run tó dá wa ló “mí sí” Bíbélì, ó sì mọ ohun tó dáa jù lọ fún wa.—2 Tímótì 3:16.
Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan.
ÌLÀNÀ: Ó “wù wá láti jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.”—Hébérù 13:18.
Báwo lo ṣe lè fi ìlànà yìí kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o jí ìwé wò nígbà ìdánwò, tó ṣe ẹ́ bíi pé kó o parọ́ fáwọn òbí ẹ tàbí kó o jalè?
Tí ẹ̀rí ọkàn ẹ bá ń mú kó o jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo, báwo nìyẹn ṣe máa ṣe ẹ́ láǹfààní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú?
ÌLÀNÀ: “Ẹ máa sá fún ìṣekúṣe.”—1 Kọ́ríńtì 6:18.
Báwo lo ṣe lè fi ìlànà yìí kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o wo àwòrán ìṣekúṣe tàbí kó o ṣe ìṣekúṣe?
Tí ẹ̀rí ọkàn ẹ bá mú kó o sá fún ìṣekúṣe, báwo nìyẹn ṣe máa ṣe ẹ́ láǹfààní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú?
ÌLÀNÀ: “Ẹ jẹ́ onínúure sí ara yín, kí ẹ máa ṣàánú, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà.”—Éfésù 4:32.
Báwo ni ìlànà yìí ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín ìwọ àti mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ rẹ kan?
Tí ẹ̀rí ọkàn ẹ bá mú kó o dárí ji ẹni náà, kó o sì ṣàánú ẹ̀, báwo nìyẹn ṣe máa ṣe ẹ́ láǹfààní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú?
ÌLÀNÀ: “[Jèhófà] kórìíra ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 11:5.
Báwo lo ṣe lè fi ìlànà yìí sílò tó o bá fẹ́ yan fíìmù tàbí ètò tẹlifíṣọ̀n tó o máa wò tàbí géèmù tó o máa gbá?
Tí ẹ̀rí ọkàn ẹ bá mú kó o yẹra fún àwọn eré ìnàjú tó ní ìwà ipá nínú, báwo nìyẹn ṣe máa ṣe ẹ́ láǹfààní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú?
OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ SÍ ẸNÌ KAN: “Mo láwọn ọ̀rẹ́ tó máa ń gbá géèmù oníwà ipá, èmi náà sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Dádì mi sọ fún mi pé mi ò gbọ́dọ̀ gbá géèmù náà mọ́. Àmọ́, ohun tí wọ́n sọ yẹn ò tẹ́ mi lọ́rùn, torí náà mo máa ń gbá a tí mo bá lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi. Tí mo bá wá délé, mi ò ní sọ fún ẹnikẹ́ni pé mo ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀. Dádì mi máa ń béèrè pé kí ló ṣe mí, mo sì máa ń sọ pé kò sí nǹkan kan. Lọ́jọ́ kan, mo ka Sáàmù 11:5, nígbà tí mo kà á tán, mo kábàámọ̀ ohun tí mò ń ṣe. Mo wá rí i pé kò yẹ kí n máa gbá àwọn géèmù náà mọ́. Lọ́tẹ̀ yìí, mo jáwọ́. Kódà, nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi tá a jọ máa ń gbá géèmù náà tẹ́lẹ̀ rí i pé mi ò gbá a mọ́, ṣe lòun náà jáwọ́ ńbẹ̀.”—Jeremy.
Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ìgbà wo ni ẹ̀rí ọkàn Jeremy bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́, ìgbà wo ló sì bẹ̀rẹ̀ sí í fetí sí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀? Kí lo rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jeremy?
Kókó ibẹ̀: Ẹ̀rí ọkàn ẹ ló máa fi irú ẹni tó o jẹ́ hàn, ó sì máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tó o kà sí pàtàkì. Kí ni ẹ̀rí ọkàn ẹ sọ nípa irú ẹni tó o jẹ́?