ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Fífọ̀rọ̀ Ránṣẹ́ Lórí Fóònù?
:-) Téèyàn bá fọgbọ́n lo ọ̀rọ̀ àtẹ̀jíṣẹ́, ó lè jẹ́ kéèyàn mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí fáwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀.
:-( Tó ò bá fọgbọ́n lò ó, ó lè da àárín yín rú, ó sì lè mú kí wọ́n máa fojú àbùkù wò ẹ́.
Àpilẹ̀kọ yìí máa sọ ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa
Ohun tó tún wà nínú àpilẹ̀kọ yìí:
Irú ẹni tó yẹ kó o fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí
Fọ́pọ̀ ọ̀dọ́, fífọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ètò ìbánisọ̀rọ̀. Á jẹ́ kó o lè máa kàn sí gbogbo àwọn tó wà lórí àkọsílẹ̀ rẹ, ìyẹn táwọn òbí ẹ bá gbà fún ẹ.
“Dádì ò máa ń fẹ́ kémi àtàbúrò mi obìnrin báwọn ọmọkùnrin sọ̀rọ̀ lórí fóònù, àfi tó bá máa jẹ́ lórí fóònù àjùmọ̀lò tó wà ní yàrá ìgbàlejò, táwọn míì sì wà níbẹ̀.”—Lenore.
Ohun tó yẹ kó o mọ̀: O lè kóra ẹ sínú ewu tó bá jẹ́ pé ẹnikẹ́ni tó o bá ṣáà ti rí lo máa ń fún ní nọ́ńbà ẹ.
“Tó o bá ń fún gbogbo ẹni tó o bá rí ní nọ́ńbà ẹ, àfàìmọ̀ lo ò ní gba àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí àwòrán tó ò fẹ́.”—Scott.
“Tó o bá ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sẹ́ni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ ní gbogbo ìgbà, ìfẹ́ ẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbà ẹ́ lọ́kàn kíákíá.”—Steven.
Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Tó o bá kíyè sára, o ò ní kó sínú ìbànújẹ́.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sẹ́nì kan: “Èmi àtọmọkùnrin kan jọ ń ṣọ̀rẹ́, a sì máa ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra wa déédéé. Èrò tèmi ni pé kò kúkú ju ọ̀rẹ́ lásán lọ. Mi ò mọ̀ ọ́n lọ́ràn, àfìgbà tó sọ fún mi pé ọkàn òun ti ń fà mọ́ mi. Nígbà tí mo ronú pa dà sẹ́yìn, mo wá rí i pé kò yẹ kí n máa wà pẹ̀lú ẹ̀ kí n sì máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i tó bí mo ṣe ṣe.”—Melinda.
Rò ó wò ná: Báwo lo ṣe rò pé ọ̀rẹ́ àárín Melinda àtọmọkùnrin yẹn ṣe máa rí lẹ́yìn tó sọ fún un póun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀?
Ohun tó yẹ: Kí ló yẹ kí Melinda ti máa ṣe tẹ́lẹ̀ kọ́rọ̀ òun àtọmọkùnrin yẹn má bàa kọjá pé wọ́n kàn ń bára wọn ṣọ̀rẹ́?
Irú ọ̀rọ̀ tó yẹ kó o kọ ránṣẹ́
Fífọ̀rọ̀ ránṣẹ́ ò ṣòro rárá, bí ẹní fàkàrà jẹ̀kọ ni, ó sì máa ń dùn mọ́ ẹni tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí náà, ìyẹn ò wá ní jẹ́ kó o rántí pé ẹni tó o fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí lè ṣi ọ̀rọ̀ tó o kọ lóye.
Ohun tó yẹ kó o mọ̀: Èèyàn lè ṣi ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ lórí fóònù lóye.
“Èèyàn ò lè mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹni tó fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí, kódà tó bá fàwọn àwòrán orí fóònù tó ń fi ìmọ̀lára téèyàn ní hàn sí i. Ẹni tí wọ́n fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí lè ṣì í lóye.”—Briana.
“Mo mọ àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n ti bara wọn lórúkọ jẹ́ táwọn èèyàn sì sọ pé wọ́n máa ń tage torí irú ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sáwọn ọmọkùnrin.”—Laura.
Bíbélì sọ pé: “Àwọn èèyàn rere máa ń ronú kí wọ́n tó fèsì.” (Òwe 15:28, ìtumọ̀ Bíbélì Good News Translation) Kí lẹsẹ Bíbélì yẹn kọ́ wa? Máa tún irú ọ̀rọ̀ tó o kọ kà kó o tó fi ránṣẹ́!
Ìgbà tó yẹ kó o fọ̀rọ̀ ránṣẹ́
Tó o bá lo làákàyè, ìwọ náà lè láwọn òfin tí wàá máa tẹ̀ lé tó o bá ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù.
Ohun tó yẹ kó o mọ̀: Tó ò bá kíyè sára nípa bó o ṣe ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́, àwọn èèyàn lè máa wò ẹ́ bí ẹni tí kì í ṣọmọlúwàbí, o sì lè máa lé àwọn ọ̀rẹ́ ẹ sá dípò kí wọ́n máa fà mọ́ ẹ.
“Èèyàn kì í pẹ́ gbàgbé ìlànà tó bá ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́. Lọ́jọ́ kan, bí mo ṣe ń bẹ́nì kan tá a jọ ń jẹun sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni mo tún ń tẹ ọ̀rọ̀ àtẹ̀jíṣẹ́ sẹ́lòmíì.”—Allison.
“Ó léwu téèyàn bá ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ nígbà tó ń wakọ̀. Téèyàn ò bá wo ibi tó ń lọ, jàǹbá ọkọ̀ lè ṣẹlẹ̀.”—Anne.
Bíbélì sọ pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, . . . ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀.” (Oníwàásù 3:1, 7) Ọ̀rọ̀ tá à ń sọ lẹ́nu nìkan kọ́ ni ìlànà yìí kàn, ó kan ọ̀rọ̀ tá à ń kọ ránṣẹ́ náà.
Béèyàn ṣe ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́
Irú ẹni tó yẹ kó o fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí
;-)Máa tẹ̀ lé ìlànà táwọn òbí ẹ fún ẹ.—Kólósè 3:20.
;-)Mọ irú àwọn tí wàá máa fún ní nọ́ńbà ẹ. Tó o bá fohùn pẹ̀lẹ́ sọ fẹ́nì kan pó ò ní jẹ́ kó mọ ohun kan nípa ọ̀rọ̀ ayé ẹ, títí kan nọ́ńbà fóònù ẹ, ìlànà tí wàá máa tẹ̀ lé tó o bá dàgbà lo fi ń kọ́ra yẹn.
;-)Má máa fọ̀rọ̀ àtẹ̀jíṣẹ́ báàyàn tage kọ́rọ̀ àárín yín má lọ kọjá ibi tó yẹ. Tí ìfẹ́ ẹ bá lọ gbà á lọ́kàn, ìbànújẹ́ àti ìjákulẹ̀ ló máa fà fún un.
“Àwọn òbí mi mọ̀ mí sẹ́ni tí kì í lo fóònù lọ́nà tí ò dáa, torí náà, wọ́n jẹ́ kí n máa fọgbọ́n pinnu fúnra mi, àwọn tí màá fi nọ́ńbà wọn sórí fóònù mi.”—Briana.
Irú ọ̀rọ̀ tó yẹ kó o kọ ránṣẹ́
;-)Kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ fi ránṣẹ́, bi ara ẹ pé, ‘Ṣé ọ̀rọ̀ àtẹ̀jíṣẹ́ ló yẹ kí n fi sọ irú ọ̀rọ̀ yìí?’ Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ lórí fóònù ló máa dáa jù tàbí kẹ́ ẹ jọ ríra sọ̀rọ̀.
;-)Má ṣe fọ̀rọ̀ tó ò lè báàyàn sọ ránṣẹ́ sí i. Sarah ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23] sọ pé: “Tó ò bá ti lè bónítọ̀hún sọ ọ́, má ṣe fi ránṣẹ́ sí i.”
“Tẹ́nì kan bá fi àwòrán tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ sí ẹ, sọ fáwọn òbí ẹ. Ìyẹn máa dáàbò bò ẹ́, ó sì máa jẹ́ káwọn òbí ẹ fọkàn tán ẹ.”—Sirvan.
Ìgbà tó yẹ kó o fọ̀rọ̀ ránṣẹ́
;-)Pinnu ìgbà tó o máa pa fóònù ẹ tì tó ò ní lò ó. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Olivia sọ pé: “Mi ò máa ń jẹ́ kí fóònù mi wà lọ́dọ̀ mi tá a bá ń jẹun tàbí tí mo bá ń kẹ́kọ̀ọ́.” “Ṣe ni mo máa ń pa á tá a bá wà nípàdé kó máa bàa máa ṣe mí bíi kí n yẹ̀ ẹ́ wò.”
;-)Máa fọ̀rọ̀ rora ẹ wò. (Fílípì 2:4) Má máa kọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù tó o bá ń bẹ́nì kan sọ̀rọ̀ lọ́wọ́.
“Mo ti ṣòfin fúnra mi, ìkan lára ẹ̀ ni pé mi ò ní kọ̀rọ̀ ránṣẹ́ tí mo bá wà láààrín àwọn ọ̀rẹ́ mi, àfi tó bá pọn dandan. Mi ò sì máa ń fáwọn tí mi ò tíì mọ̀ dáadáa ní nọ́ńbà mi.”—Janelly.