ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Ṣé Ọ̀rẹ́ Lásán Ni Wá àbí Ọ̀rọ̀ Ìfẹ́ Ti Wọ̀ Ọ́?—Apá 2: Báwo Ní Mo Ṣe Ń Ṣe sí Ẹni Yìí?
Gbogbo ìgbà lo máa ń fẹ́ wà lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ ẹ. Àmọ́ o rí i pé lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, ọ̀kan wà nínú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ tọ́rọ̀ yín ti wá wọ̀ gan-an. Ìṣòro ibẹ̀ kàn ni pé, ọ̀rẹ́ ẹ yìí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ. O lè máa rò ó pé ‘Ọ̀rẹ́ lásán ni wá,’ kó o sì máa wò ó pé bó ṣe ń ṣe ẹ́ ló ń ṣe òun náà. Ṣé nǹkan bàbàrà ni?
Ohun tó lè ṣẹlẹ̀
Kò sóhun tó burú nínú kó o lọ́rẹ̀ẹ́ tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ. Àmọ́, kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó o bá ń nífẹ̀ẹ́ àrà ọ̀tọ̀ sí ẹni kan jú àwọn tó kù? Ẹni náà lè máa rò ó pé o fẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kọjá ti ọ̀rẹ́ lásán.
Àmọ́ ṣé ohun tó wà lọ́kàn tìẹ nìyẹn? Jẹ́ ká wo àwọn ọ̀nà tí èyí lè gbà ṣẹlẹ̀ láì fura.
Ẹnì kan ló máa ń fẹ́ bá sọ̀rọ̀ ní gbogbo ìgbà.
“Bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ò lè pinnu bọ́rọ̀ ṣe máa rí lára ẹnì kan, kò ní dáa kó o máa pa kún un. Bí àpẹẹrẹ, o sọ pé ọ̀rẹ́ lásán ni yín, o wá ń pe onítọ̀hún ní gbogbo ìgbà, ẹ jọ máa ń sọ̀rọ̀ ṣáá. Bí ẹni da epo síná ló rí.”—Sierra.
O máa ń gbà kí ẹnì kan máa bá ẹ sọ̀rọ̀.
“Ọmọbìnrin kan sábà máa ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí mi lórí fóònù, òun ló máa ń bẹ̀rẹ̀ ẹ̀, kì í ṣe èmi. Àmọ́ gbogbo ìgbà ni mo máa ń fèsì ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó wá mú kó ṣòro fún mi láti jẹ́ kó mọ̀ pé ọ̀rẹ́ lásán ni wá.”—Richard.
O máa ń fẹ́ kí ẹnì kan máa bá ẹ sọ̀rọ̀.
“Ọ̀pọ̀ ló rò pé kò sóhun tó burú nínú títage. Ṣe ni wọ́n máa ń mú àwọn míì ṣeré, wọn ò ní in lọ́kàn láti fẹ́ wọn. Irú ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ dáadáa, ó sì máa ń pa àwọn ẹlòmíì lára.”—Tamara.
Òótọ́ ibẹ̀: Téèyàn bá ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ ṣáá, tó sì ń pe àfíyèsí àrà ọ̀tọ̀ sẹ́ni náà, ó lè mú kí ẹni náà máa rò pé ẹ kì í ṣe ọ̀rẹ́ lásán.
Ìdí tó fi ṣe pàtàkì
Ó máa ń pa ẹnì kejì lára.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn.” (Òwe 13:12) Kí lo máa wá sí ẹ lọ́kàn tí ẹnì kan bá ń fìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí ẹ?
Ó dà bí ìgbà tó o bá fi ìwọ̀ mú ẹja, àmọ́ o ò mú ẹja náà kúrò lẹ́nu ìwọ̀, bẹ́ẹ̀ lo ò tú u sílẹ̀. Irú ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ láàárín ìwọ àti ẹlòmíì. Tó o bá mọ̀ pé o ò lẹ́nì kan fẹ́, àmọ́ tẹ́ ẹ jọ máa ń sọ̀rọ̀ ṣáá, tó ò yé pè é, ó máa pa dà pa ẹni yẹn lára.”—Jessica .
Ó lè bà ẹ́ lórúkọ jẹ́.
Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4) Irú ẹni wo lo máa ka ẹni tó jẹ́ pé tara ẹ̀ nìkan ló mọ̀ sí? Ojú wo làwọn èèyàn á fi máa wo ẹni náà?
“Mi ò gba ti ọkùnrin tó máa ń bá àwọn obìnrin tage. Tí ẹni tó máa ń bá obìnrin tage bá sì gbéyàwó lọ́jọ́ iwájú, ó ṣeé ṣe kó dalẹ̀ ìyàwó rẹ̀. Tara wọn nìkan ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ mọ̀, torí ṣe ni wọ́n máa ń fi àwọn ẹlòmíì gborúkọ.”—Julia.
Òótọ́ ibẹ̀: Ṣe ni ẹni tó bá ń fìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sẹ́lòmíì láìní in lọ́kàn láti fẹ́ onítọ̀hún ń pa ara rẹ̀ àti ẹlòmíì lára.
Ohun tó o lè ṣe
Bíbélì sọ pé ká máa ṣe “àwọn ọ̀dọ́kùnrin gẹ́gẹ́ bí arákùnrin” àti “àwọn ọ̀dọ́bìnrin gẹ́gẹ́ bí arábìnrin pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.” (1 Tímótì 5:1, 2) Tó o bá ń tẹ̀ lé ìlànà yẹn, kò ní jẹ́ kí ọ̀rẹ́ tó ò ń bá àwọn tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ ṣe dà rú.
“Ká sọ pé mo ti lọ́kọ, mi ò ní máa bá ọkọ ẹlòmíì tage. Mo ti ń fi kọ́ra báyìí tí mi ò tíì lọ ilé ọkọ, mo máa ń ṣọ́ra ṣe pẹ̀lú àwọn ọkùnrin, ó sì dáa bẹ́ẹ̀.”—Leah.
Bíbélì sọ pé: “Nínú ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ kì í ṣàìsí ìrélànàkọjá.” (Òwe 10:19) Kì í ṣe ọ̀rọ̀ sísọ nìkan ni ìlànà yẹn bá wí, ó tún kan fífi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́, títí kan bó o ṣe ń fi ránṣẹ́ tó àti ohun tó ò ń bá ẹni náà sọ.
“Kò sídìí tó fi yẹ kó o máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ọmọbìnrin kan lójoojúmọ́ nígbà tó ò ní in lọ́kan láti fẹ́ ẹ.”—Brian.
Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè a kọ́kọ́ mọ́ níwà.” (Jákọ́bù 3:17) O lè bọ ẹnì kan lọ́wọ́ lọ́nà tí ò ní túmọ̀ sí nǹkan kan, o sì lè ṣe é lọ́nà tí ẹni tó o bọ̀ lọ́wọ́ á fi máa ro nǹkan míì.
“Mo máa ń bá àwọn èèyàn ṣeré, àmọ́ mo máa ń ṣe é níwọ̀n, mi kì í kọjá àyè mi.”—Maria.
Òótọ́ ibẹ̀: Máa ṣọ́ra ṣe pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Jennifer sọ pé, “Kò rọrùn láti rí ọ̀rẹ́ tòótọ́, tó o bá wá jàjà rí, máa ṣọ́ra ṣe pẹ̀lú wọn kó o má bàa lọ mú kí wọ́n máa ro nǹkan míì, torí ìyẹn lè ba ọ̀rẹ́ yín jẹ́.”
Àbá
Má ṣe kó ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì dà nù. Tẹ́nì kan bá bi ẹ́ pé, “Ṣé ìwọ àti lágbájá ń fẹ́ra ni?” ó lè jẹ́ pé ẹ ti sún mọ́ra jù nìyẹn.
Ọwọ́ kan náà ni kó o fi mú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ. Má yan ẹnì kan láàyò, kó o máa wá bá òun nìkan sọ̀rọ̀ ṣáá.
Má ṣe máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ ní gbogbo ìgbà, máa ṣọ́ ohun tó ò ń fi ránṣẹ́, kó o sì máa ṣọ́ ìgbà tí wàá fi ránṣẹ́. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Alyssa sọ pé, “Kò yẹ kó o máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ lóru.”