ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Kí Ni Mo Lè Ṣe Nípa Àwọn Àṣìṣe Mi?
Kí ni wàá ṣe?
Kà nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Karina, kó o sì wò ó bíi pé ìwọ ló ń ṣẹlẹ̀ sí. Kí ni wàá ṣe tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Karina?
Karina: “Lọ́jọ́ kan tí mò ń wa ọkọ̀ lọ síléèwé, ṣe ni mò ń fi ọkọ̀ náà sáré, ni ọlọ́pàá kan bá dá mi dúró ó sì já ìwé ìtanràn pé mo ti sáré jù fún mi.” Ìdààmú bá mi. Mo ṣàlàyé fún Mọ́mì mi, wọ́n sì sọ pé mo ní láti sọ fún Dádì, àmọ́ mi ò fẹ́ sọ.
Kí ni wàá ṣe?
Àbá Àkọ́kọ́: Kí n má sọ nǹkan kan, kí n sì rò pé àṣírí ò ní tú sọ́wọ́ Dádì.
Àbá Kejì: Kí n sọ gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ fún Dádì.
Ó lè ṣe ẹ́ bíi pé kó o yan Àbá Àkọ́kọ́. Ó kúkú ṣe tán, Mọ́mì lè má mọ̀ pé o ò tí ì lọ sọ fún Dádì. Àmọ́ àwọn ìdí pàtàkì wà tó fi yẹ kó o jẹ́wọ́ àṣìṣe ẹ—yálà lórí ọ̀rọ̀ ìwé ìtanràn tí wọ́n já fún ẹ tàbí nǹkan míì.
Ìdí mẹ́ta tó fi yẹ kó o gba àṣìṣe rẹ
1. Ìdí ni pé ohun tó yẹ kó o ṣe nìyẹn. Bíbélì sọ ìlànà kan táwa Kristẹni ń tẹ̀ lé, ó ní: “a . . . dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”—Hébérù 13:18.
“Mo sa gbogbo ipá mi kí n lè jẹ́ ẹni tí kì í ṣàbòsí, kí n máa gba ẹ̀bi mi lẹ́bi, kí n sì máa gba àṣìṣe mi lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”—Alexis.
2. Ìdí ni pé ó máa ń rọrùn fáwọn èèyàn láti dárí ji ẹni tó bá gbà pé òun ṣàṣìṣe. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò kẹ́sẹ járí, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ni a ó fi àánú hàn sí.”—Òwe 28:13.
“Ó gba pé kó o pa ìtìjú tì kó o lè gbà pé o ṣàṣìṣe, àmọ́ ìyẹn ló máa jẹ́ káwọn ẹlòmíì fọkàn tán ẹ. Wọ́n á rí i pé olóòótọ́ èèyàn ni ẹ́. Àṣìṣe tó o ṣe yẹn á wá di ohun tó mú káwọn èèyàn mọ̀ pé o kì í ṣe alábòsí.”—Richard.
3. Ìdí kẹta tó ṣe pàtàkì jù ni pé, ó ń múnú Jèhófà dùn. Bíbélì sọ pé: “Oníbékebèke jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ Rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn adúróṣánṣán.”—Òwe 3:32.
“Lẹ́yìn tí mo ṣàṣìṣe ńlá kan, mo rí i pé mo ní láti lọ jẹ́wọ́ ara mi. Jèhófà ò ní ṣe ojúure sí mi tí mi ò bá ṣe nǹkan lọ́nà tó fẹ́.”—Rachel.
Torí náà, kí ni ọ̀dọ́bìnrin Karina ṣe nípa àṣìṣe rẹ̀? Ńṣe ló tọ́jú ìwé ìtanràn yẹn síbì kan kí Dádì ẹ̀ má bàa rí i. Àmọ́ bí irọ́ bá lọ lógún ọdún, ọjọ kan ni òtítọ́ á bá a. Karina sọ pé: “Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, Dádì ń ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ ètò ìbánigbófò wa, wọ́n wá rí àkọsílẹ̀ tíkẹ́ẹ̀tì yẹn lábẹ́ orúkọ mi. Mo wọ wàhálà gan-an lọ́dọ̀ Dádì, mọ́mì pàápàá bínú pé mi ò tíì sọ fún Dádì!”
Ẹ̀kọ́ tó rí kọ́: Karina sọ pé: “Téèyàn bá bo àṣìṣe rẹ̀ mọ́lẹ̀, ṣe lo tún ń dá kún ọ̀rọ̀ náà. Bópẹ́ bóyá, ó máa jìyà ẹ̀!”
Bó o ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe ẹ
Kò sẹ́ni tí kì í ṣàṣìṣe. (Róòmù 3:23; 1 Jòhánù 1:8) Ohun tá a sì ti ń gbé yẹ̀ wò fi hàn pé tó o bá gba àṣìṣe ẹ, pàápàá tó bá jẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé o ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ o sì dàgbà dénú.
Ohun tó kàn ni pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe ẹ. Ó ṣeni láàánú pé àwọn ọ̀dọ́ kan ò kìí ṣe bẹ́ẹ̀! Ó lè máa ṣe wọ́n bíi ti ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Priscilla, tó sọ pé: “Nígbà kan rí, mo máa ń rẹ̀wẹ̀sì gan-an nítorí àwọn àṣìṣe mi. Mò máa ń wo ara mi bí aláìjámọ́ nǹkan kan, àwọn àṣìṣe mi wá dà bí ẹrù ńlá tó ń wọ̀ mí lọ́rùn. Ó máa ń tojú sú mi pátápátá, á wá dà bíi pé ọ̀rọ̀ mi ti kọjá àtúnṣe.”
Ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀ nígbà míì? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, rántí pé: Téèyàn bá gbé àṣìṣe rẹ̀ sọ́kàn, ńṣe ló dà bí ìgbà tí awakọ̀ kan gbájú mọ́ àwọn ọkọ̀ tó wà lẹ́yìn nínú dígí. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe lá mú kó máa ṣe ẹ́ bíi pé o ò já mọ́ nǹkan kan, o ò sì ní lókun láti kojú àwọn ìpèníjà ọjọ́ iwájú.
Kàkà kó o ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ṣe fojú tó yẹ wo ọ̀rọ̀ náà?
“Tó o bá rántí àwọn àṣìṣe ẹ, ṣe ni kó o kẹ́kọ̀ọ́ látinú wọn kó o máa bàa ṣe é mọ́. Kò yẹ kó o gbé e sọ́kàn débi tí wàá fì di aláìjámọ́ nǹkan kan lójú ara ẹ.”—Elliot.
“Mo máa ń wo àṣìṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, torí náà, tí àṣìṣe bá ti wáyé, ẹ̀kọ́ inú ẹ̀ ni mo máa ń gbájú mọ́, èyí tó máa jẹ́ kí n dẹni tó dáa sí i kí n má sì ṣe àṣìṣe yẹn nígbà míì. Nǹkan tó yẹ kéèyàn máa ṣe nìyẹn, torí á jẹ́ kéèyàn máa dáa sí i.”—Vera.