Báwo Lẹ́ Ṣe Ṣètò Àwọn Ìjọ Yín?
Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ló ń bójú tó ìjọ kọ̀ọ̀kan. Nǹkan bí ìjọ ogún ló máa ń para pọ di àyíká kan, nǹkan bí àyíká mẹ́wàá sì máa ń para pọ̀ di àgbègbè. Lóòrèkóòrè, àwọn ìjọ máa ń gba ìbẹ̀wò alàgbà tó ń rìnrìn àjò, a máa ń pè wọ́n ní alábòójútó àyíká àti alábòójútó àgbègbè. Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó jẹ́ àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí tó ti ń sìn látọjọ́ pípẹ́ máa ń pèsè àwọn ìtọ́ni àti ìtọ́sọ́nà, ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Brooklyn ní ìpínlẹ̀ New York nílẹ̀ Amẹ́ríkà ni ìgbìmọ̀ náà ti ń ṣiṣẹ́.—Ìṣe 15:23-29; 1 Tímótì 3:1-7.