Ǹjẹ́ Ẹ Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Jésù?
Bẹ́ẹ̀ ni. A ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù, tó sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) A nígbàgbọ́ pé ọ̀run ni Jésù ti wá sáyé àti pé ó fi ìwàláàyè rẹ̀ pípé lélẹ̀ láti fi rà wá pa dà. (Mátíù 20:28) Ikú rẹ̀ àti àjíǹde rẹ̀ mú kó ṣeé ṣe fún àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ láti ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 3:16) A tún gbà gbọ́ pé Jésù ti di Ọba Ìjọba Ọlọ́run tó wà lókè ọ̀run, èyí tó máa mú àlááfíà wá bá gbogbo aráyé láìpẹ́. (Ìṣípayá 11:15) Àmọ́, a fara mọ́ ohun tí Jésù sọ pé: “Baba tóbi jù mí lọ.” (Jòhánù 14:28) Nítorí náà, a kì í jọ́sìn Jésù torí a kò gbà pé òun ni Ọlọ́run Olódùmarè.