Ṣé Kristẹni Ni Yín?
Bẹ́ẹ̀ ni. Kristẹni ni wá, àwọn ohun tá a fẹ́ sọ yìí ló fi hàn bẹ́ẹ̀:
A ń sapá láti tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ Jésù Kristi àti ìwà rẹ̀.—1 Pétérù 2:21.
A gbà gbọ́ pé ipasẹ̀ Jésù lèèyàn fi lè rí ìgbàlà, pé “kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run tí a ti fi fúnni láàárín àwọn ènìyàn nípasẹ̀ èyí tí a ó fi gbà wá là.”—Ìṣe 4:12.
Bí àwọn èèyàn bá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a máa ń ṣèrìbọmi fún wọn lórúkọ Jésù.—Mátíù 28:18, 19.
A máa ń gbàdúrà lórúkọ Jésù.—Jòhánù 15:16.
A gbà gbọ́ pé Jésù ni Orí, tàbí ẹni tí Ọlọ́run yàn láti jẹ́ aláṣẹ lórí gbogbo ọkùnrin.—1 Kọ́ríńtì 11:3.
Àmọ́ ṣá o, ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà, a yàtọ̀ sí àwọn ẹlẹ́sìn míì tí wọ́n ń pè ní Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, a gbà gbọ́ pé Bíbélì kọ́ni pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù, kì í ṣe ara Mẹ́talọ́kan. (Máàkù 12:29) A ò gbà pé ẹ̀mí èèyàn kì í kú, a ò gbà pé ibì kankan wà nínú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé Ọlọ́run máa ń dá àwọn èèyàn lóró títí láé nínú ọ̀run àpáàdì, tàbí pé àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọsìn gbọ́dọ̀ máa ní orúkọ òye tó gbé wọn ga ju àwọn yòókù lọ.—Oníwàásù 9:5; Ìsíkíẹ́lì 18:4; Mátíù 23:8-10.