Ṣé Ẹ Rò Pé Ẹ̀yin Nìkan Ló Máa Rí Ìgbàlà?
Rárá o. Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó gbé láyé láwọn ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa rí ìgbàlà. Bíbélì ṣàlàyé pé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó wà láàyè lónìí bẹ̀rẹ̀ sí í sin Ọlọ́run, kí àwọn pẹ̀lú sì rí ìgbàlà. Èyí ó wù kó jẹ́, iṣẹ́ wa kọ́ ni láti pinnu àwọn tó máa rí ìgbàlà àti àwọn tí kò ní rí i. Iṣẹ́ Jésù ni.—Jòhánù 5:22, 27.