Àwọn Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Wo Ló Ń Mú Káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Já Fáfá Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa?
Lóòrèkóòrè làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó máa ń ràn wá lọ́wọ́ ní gbogbo apá ìgbésí ayé wa títí kan iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí ni iṣẹ́ tí Jésù pàṣẹ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ máa ṣe, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láwọn ìpàdé tá a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, láwọn àpéjọ agbègbè tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún àti láwọn àpéjọ àyíká wa. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń bójú tó àwọn iṣẹ́ kan nínú ìjọ tàbí nínú ètò Ọlọ́run máa ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó tún ṣàrà ọ̀tọ̀ láwọn ilé ẹ̀kọ́ tá a dá sílẹ̀.
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gbà?
Àwọn ìpàdé ìjọ. A máa ń ṣe ìpàdé méjì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láwọn ibi tá a ti máa ń jọ́sìn Ọlọ́run. A máa ń ṣe ìpàdé kan láàárín ọ̀sẹ̀, á sì máa ń ṣe ìkejì lópin ọ̀sẹ̀. A kì í gbé igbá ọrẹ láwọn ìpàdé wa, gbogbo èèyàn ló sì lè wá.
Ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀. A máa ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí bá a ṣe lè kàwé lọ́nà tó dáa, bá a ṣe lè fetí sáwọn èèyàn ká sì báwọn sọ̀rọ̀, bá a ṣe lè sọ̀rọ̀ dáadáa níwájú ọ̀pọ̀ èèyàn, bá a ṣe lè wàásù àti bá a ṣe lè kọ́ àwọn èèyàn. Lára àwọn nǹkan tó wà nínú ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ni àsọyé, ìjíròrò, àṣefihàn, àti fídíò. Ó máa ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè wàásù lọ́nà táá fi wọ àwọn èèyàn lọ́kàn àti bá a ṣe lè kọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Gbogbo àwọn tó bá wá sípàdé ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí máa ń ṣe láǹfààní. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, ó máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run túbọ̀ lágbára, ó sì máa ń jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àtàwọn ará wa túbọ̀ jinlẹ̀.
Ìpàdé òpin ọ̀sẹ̀. Apá méjì ni ìpàdé yìí pín sí. Apá àkọ́kọ́ ni àsọyé Bíbélì tó wà fún gbogbo èèyàn títí kan àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nínú apá kejì, a máa ń jíròrò àpilẹ̀kọ kan nínú Ilé Ìṣọ́ a ẹ̀dà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa ń jíròrò yìí máa ń ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì àtàwọn ìlànà tó lè ràn wá lọ́wọ́ nínú ìgbésí ayé wa àti lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
Àwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè. Àwọn ìpàdé ńlá mẹ́ta la máa ń ṣe lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ ìjọ ló sì máa ń pàdé pọ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àpéjọ yìí. Àwọn àpéjọ amóríyá yìí máa ń dá lé àkòrí kan látinú Bíbélì. Lára àwọn nǹkan tá a sì máa ń gbádùn níbẹ̀ ni àsọyé, àṣefihàn, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àti fídíò. Bíi ti àwọn ìpàdé ìjọ tá a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ àgbègbè máa ń jẹ́ ká túbọ̀ ní ìmọ̀ Bíbélì, ká sì túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bákan náà, a kì í gbé igbá ọrẹ láwọn ìpàdé ńlá yìí, gbogbo èèyàn ló sì lè wá.
Àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó dá lórí Bíbélì táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lọ
Àwọn kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lọ sáwọn ilé ẹ̀kọ́ Bíbélì kí wọ́n lè gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Kí lorúkọ àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí? Kí nìdí tá a fi dá àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí sílẹ̀, báwo sì ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ṣe máa ń gùn tó? Àwọn wo ló lè lọ sáwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí?
Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà
Ohun tó wà fún: Ó máa ń ran àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tá à ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà b lọ́wọ́ láti túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. Lára ohun tí wọ́n máa ń gbádùn ní ilé ẹ̀kọ́ yìí ní ìjíròrò, àṣefihàn, àsọyé, àti ìdánrawò.
Àkókò: Ọjọ́ mẹ́fà.
Àwọn tó lè lọ: Ó kéré tán, ẹni náà ti gbọ́dọ̀ lo ọdún kan lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. A tún máa ń pe àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ yìí, tó sì jẹ́ pé ó ti tó ọdún márùn-ún tí wọ́n lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà kẹ́yìn.
Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run
Ohun tó wà fún: Wọ́n máa ń fún àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tó ní ìrírí ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ yìí. Wọ́n tún máa ń kọ́ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà bí wọ́n ṣe lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni, wọ́n sì máa ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ni wọ́n máa ń rán lọ sáwọn ibi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i.
Àkókò: Oṣù méjì.
Àwọn tó lè lọ: Àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó bá dójú ìlà ohun tá à ń béèrè, tí wọ́n sì lè lọ síbikíbi tí wọ́n bá rán wọn lọ, lè kọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù tó wà fún ilé ẹ̀kọ́ yìí.
Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Ìjọ
Ohun tó wà fún: Ó máa ń jẹ́ káwọn alàgbà c mọ bí wọ́n ṣe lè ṣe àwọn iṣẹ́ wọn nínú ìjọ dáadáa, irú bíi kíkọ́ni àti ṣíṣe àbójútó àwọn ará, ó sì tún máa ń jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run àtàwọn ará wọn túbọ̀ jinlẹ̀.—1 Pétérù 5:2, 3.
Àkókò: Ọjọ́ márùn-ún.
Àwọn tó lè lọ: Wọ́n máa ń pe àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di alàgbà àtàwọn alàgbà tó ní ìrírí tó sì jẹ́ pé ó ti tó ọdún márùn-ún tí wọ́n lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà kẹ́yìn.
Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alábòójútó Àyíká Àtàwọn Ìyàwó Wọn
Ohun tó wà fún: Ó máa ń ran àwọn òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò tá à ń pé ní alábòójútó àyíká d lọ́wọ́, kí wọ́n lè bójú tó àwọn iṣẹ́ wọn lọ́nà tó dáa. (1 Tímótì 5:17) Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí tún máa ń ran àwọn arákùnrin tó jẹ́ alàgbà yìí àtàwọn ìyàwó wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ lóye Ìwé Mímọ́.
Àkókò: Oṣù kan.
Àwọn tó lè lọ: Wọ́n máa ń pe àwọn arákùnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di alábòójútó àyíká àtàwọn ìyàwó wọn wá sí ilé ẹ̀kọ́ yìí lẹ́yìn tí wọ́n bá ti lo ọdún kan lẹ́nu iṣẹ́ náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n á máa pè wọ́n wá sí ilé ẹ̀kọ́ yìí lọ́dún márùn-ún márùn-ún.
Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́
Ohun tó wà fún: Ó máa ń ran àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ e lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ wọn nínú ìjọ bí ipò nǹkan ṣe ń yí pa dà. (2 Tímótì 3:1) Ilé ẹ̀kọ́ yìí máa ń wáyé lọ́dún mélòó kan síra.
Àkókò: Ó máa ń yí pa dà, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà ó máa ń jẹ́ ọjọ́ kan.
Àwọn tó lè lọ: Àwọn alábòójútó àyíká, àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.
Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Tó Ń Sìn ní Bẹ́tẹ́lì
Ohun tó wà fún: Ó máa ń ran àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì f lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ wọn dáadáa, kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run àtàwọn ará sì túbọ̀ jinlẹ̀ sí i.
Àkókò: Ọjọ́ márùn-ún àtààbọ̀.
Àwọn tó lè lọ: A máa ń pe àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì wá sí ilé ẹ̀kọ́ náà. A tún lè pe àwọn tó ti pẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó bá jẹ́ pé ó ti tó ọdún márùn-ún tí wọ́n lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà kẹ́yìn.
Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì
Ohun tó wà fún: Ó máa ń jẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà túbọ̀ mọyì Bíbélì, ó sì tún máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò. (1 Tẹsalóníkà 2:13) Ilé ẹ̀kọ́ yìí tún máa ń jẹ́ káwọn arákùnrin àti arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn túbọ̀ wúlò fún ètò Jèhófà àti fún iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé. Àwọn tó bá kẹ́kọ̀ọ́ yege máa ń di míṣọ́nárì tàbí ká rán wọn lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà lórílẹ̀-èdè wọn tàbí lórílẹ̀-èdè míì.
Àkókò: Oṣù márùn-ún.
Àwọn tó lè lọ: Àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì máa ń fi fọ́ọ̀mù tó wà fún ilé ẹ̀kọ́ yìí ránṣẹ́ sáwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan. A máa ń ṣe ilé ẹ̀kọ́ yìí lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Watchtower tó wà ní Patterson, nílùú New York.
Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Àtàwọn Ìyàwó Wọn
Ohun tó wà fún: Láti dá àwọn tó wà ní Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka g lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa bójú tó iṣẹ́ tó ń lọ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àti àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn láwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn ń bójú tó.
Àkókò: Oṣù méjì.
Àwọn tó lè lọ: Orílé-Iṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló máa ń yan àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka àti ìyàwó wọn tí wọ́n máa pè. A máa ń ṣe ilé ẹ̀kọ́ yìí ní Ilé Ẹ̀kọ́ Watchtower tó wà ní Patterson, nílùú New York.
Kí làwọn ẹ̀kọ́ tí a máa ń gbà láwọn ilé ẹ̀kọ́ náà dá lé?
Orí Bíbélì ni ẹ̀kọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gbà láwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí dá lé. A gbà pé Ọlọ́run ló mí sí Bíbélì àti pé inú ẹ̀ la ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó dáa jù nípa báwa Kristẹni ṣe lè gbé ìgbésí ayé wa.—2 Tímótì 3:16, 17.
Ṣé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sanwó fáwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí?
Rárá. Ọ̀fẹ́ làwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí. Ọrẹ táwọn èèyàn ń ṣe tinútinú la fi ń ti iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn.—2 Kọ́ríńtì 9:7.
a Bíbélì àtàwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì títí kan àwọn fídíò wà lórí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org.
b Aṣáájú-ọ̀nà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti ṣèrìbọmi tó sì jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, tí wọ́n ti pinnu láti máa fi iye wákàtí kan wàásù lóṣooṣù. Àwọn ọkùnrin àti obìnrin ló lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà.
c Alàgbà làwọn ọkùnrin tó jẹ́ Kristẹni tí òtítọ́ sì jinlẹ̀ lọ́kàn wọn. Wọ́n máa ń fi Ìwé Mímọ́ kọ́ni, wọ́n sì máa ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn Ọlọ́run. Bákan náà, wọ́n máa ń ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́, wọ́n sì máa ń gbà wọ́n níyànjú. Wọn kì í sanwó iṣẹ́ fáwọn ọkùnrin yìí.
d Alábòójútó àyíká ni alàgbà tó máa ń bẹ àwọn ìjọ tó wà ní àyíká ẹ̀ wò, á sì lo ọ̀sẹ̀ kan ní ìjọ kọ̀ọ̀kan. Ó máa ń sọ àwọn àsọyé tó dá lé Bíbélì, á sì bá àwọn tó wà ní ìjọ náà lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù kó lè fún wọn lókun.
e Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń bójú tó àwọn iṣẹ́ kan kí wọ́n lè ran àwọn ará nínú ìjọ lọ́wọ́. Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí máa ń jẹ́ káwọn alàgbà túbọ̀ ráyè ṣe iṣẹ́ kíkọ́ni, kí wọ́n sì bójú tó àwọn ará.
f Bẹ́tẹ́lì la máa ń pe àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Iṣẹ́ táwọn tó ń sìn níbẹ̀ ń ṣe máa ń ran àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní agbègbè tí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì náà wà lọ́wọ́, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ní àwọn nǹkan tí wọ́n nílò fún iṣẹ́ ìwàásù.
g Àwọn arákùnrin mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n kúnjú ìwọ̀n tí wọ́n sì dàgbà nípa tẹ̀mí ló máa ń wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka.